Iyẹn ni pe ọmọ Amẹrika ni MC Oluọmọ, iyẹn naa daa

Spread the love

Baye ṣe ri niyẹn. Nigba ti wọn ni wọn gun MC Oluọmọ ni ọbẹ, ti wọn sọ pe wọn yoo gbe e lọ si oke-okun fun itọju, kia ni ọkan ninu awọn eeyan rẹ ti jade to ni iyẹn ko le jẹ iṣoro, nitori ọmọ Amẹrika ni Oluọmọ, o ni paali wọn lọwọ, ọmọ oniluu ni, igbakigba lo le wọle to le jade. Baye ṣe ri niyẹn. Ta ni yoo ronu pe ọmọ Amẹrika ni MC. Lọdun to kọja lọhun-un ni ọkan ninu awọn ọmọ rẹ jade ni yunifasiti ni Amẹrika, awọn eeyan ti wọn si ri fọto rẹ lori ẹrọ ayelujara n lọgun ni, wọn ni iyẹn ni pe MC ran awọn ọmọ tirẹ ni ileewe nla bayii. Ṣugbọn awọn ọmọ ọlọmọ kan wa ti ọkunrin yii n ko kiri, ọpọ tiwọn ni aye tiwọn ti bajẹ ti ko ni atunṣe, nitori igbo ati awọn oogun oloro mi-in ni wọn ko fun awọn mu, ti wọn si n fun wọn ni ibọn ati ọbẹ pẹlu awọn ohun ija buruku mi-in lati fi ṣe jamba fun gbogbo ẹni to ba tako wọn. Ṣugbọn eeyan ko le ba MC Oluọmọ wi bii awọn ọmọ abiikọ, ati awọn akọọgba, pẹlu awọn obi ti wọn bi ọmọ wọn ti apa wọn ko ka wọn. Bi Oluọmọ ba lọgbọn lori lati ran awọn ọmọ tirẹ niwee ni Amẹrika, ti oun naa fi ẹsẹ ẹyin di ilẹ mu nitori ọjọ ọla, to sọ ara rẹ di ọmọ Amẹrika to le sa lọ nigba yoowu ti wahala ba ṣẹlẹ nibi, awọn ti wọn n tẹle e lati ṣe ijamba ti wọn si n ba aye ara tiwọn jẹ ni were, awọn oponu ti aye n ṣe. Oluọmọ ko le fi ipa mu ẹni ti ko ba fẹẹ ṣe tọọgi, ẹni to ro pe aye toun ko le nilaari boun ko ba ṣe tọọgi ni ka ba wi. Pataki ni pe ki ijọba ati awọn aṣaaju oloṣelu Eko yee lo awọn tọọgi yii, ki wọn yee fun wọn lowo, ki wọn yee daabo bo wọn labẹ ofin. Ti wọn ko ba ti ṣe bẹẹ, awọn naa yoo ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ kia, wọn yoo jẹ ki awọn araalu rimu mi, ọkan Eko yoo balẹ, nnkan wa yoo si dara. Amọ nibi to ba ti jẹ awọn oloṣelu yii funra wọn ni wọn n lo awọn tọọgi yii, bi aburu yoo ti maa ṣẹlẹ naa lo n ṣẹlẹ yii o, yoo si ṣoro ki nnkan wa too niyanju.

 

 

(45)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.