Iyẹn ni pe bijọba Buhari ṣe n nawo wa ree

Spread the love

Alaaji Lai Muhammed, minisita fun eto ikede ijọba Buhari lo sọrọ kan fawọn oniroyin lọsẹ to kọja. Ko si fẹ kawọn eeyan gbọ ọrọ naa o, nitori ohun to sọ fun wọn ni pe oun fẹẹ yọ ọrọ kan sọ fun wọn ni, ki wọn pa kamẹra ati maṣinni wọn gbogbo, nitori ki i ṣe ọrọ ti oun fẹ ko jade sita. O ni awọn eeyan, paapaa awọn alatako, n pariwo ẹnu kiri pe awọn mu El-Zakzaky, olori ẹlẹsin awọn Shi’ite ni Kaduna, awọn ti i mọle, awọn ko ṣi i silẹ, o ni awọn araalu ko mọ pe loṣu kan pere, miliọnu mẹta ataabọ lawọn fi n bọ ọkunrin naa atawọn ọmọọṣẹ ẹ ti awọn jọ mu. Miliọnu mẹta ataabọ! Bẹẹ ni Lai wi. Oun funra rẹ lo fẹnu ara rẹ sọ ọ. Akọkọ ni pe ibeere ti awọn ọlọgbọn n beere ni pe kin ni ijọba mu El-Zakzaky pamọ sitimọle si nigba ti ile-ẹjọ ti sọ pe ki wọn tu u silẹ tipẹtipẹ. O to ile-ẹjọ mẹta to ti sọ ọ o, ṣugbọn ijọba Buhari taku, wọn mu baba musulumi naa pamọ, wọn lo n fajangbọn ni Kaduna, wọn ko si ṣi i silẹ ki wọn jẹ ko lọ. Aṣoju ilẹ Amẹrika nilẹ yii, Stuart Symington, sọ ni bii ọsẹ meji sẹyin pe bi ijọba kan ba wa ti ko tẹle ofin, iwa tirẹ buru ju ti awọn ti wọn n ji owo ilu ko lọ, nitori iru ijọba bẹẹ yoo ti gbogbo orilẹ-ede naa ṣubu ni. Awọn eeyan Buharui gbọ ọrọ naa nigba naa, wọn binu, ṣugbọn wọn ko le sọrọ sita, nitori wọn mọ pe awọn lọrọ naa n ba wi. Ni ọjọ Aiku to kọja yii, Sannde ijẹta, Emir ilu Gunmi, Lawal Hassan Gunmi, sọ pe iwa ibajẹ to to ki eeyan ma tẹle aṣẹ ile-ẹjọ ko tun si mọ. Bẹẹ lara ohun ti gbogbo aye fẹrẹ mọ ijọba Buhari mọ niyẹn. Ohun yoowu to ba ṣẹlẹ, bi ijọba dẹmokiresi yoo ba dara, aṣẹ ti ile-ẹjọ ba pa, gbogbo awọn ti wọn ba jẹ olori ijọba gbọdọ tẹle e. Idi ni pe bi wọn ko ba tẹle e, awọn opo to gbe orilẹ-ede duro ni wọn n ti ṣubu yii, nigba ti gbogbo opo naa ba si wo lulẹ tan, orilẹ-ede funra rẹ yoo wo, nitori ko ni i yatọ si ile ti ko ni opo to gbe e duro. Bi El-Zakzaky ba ṣẹ sofin, ile-ẹjọ lagbara lati ju u sẹwọn, bi wọn ba si ni ko lọọ jokoo sile ti awọn yoo fi yanju ọrọ rẹ, ijọba ati awọn alagbara inu ijọba naa gbọdọ gba ohun ti ile-ẹjọ sọ. Ṣugbọn lati ọjọ yii, wọn mu El-Zakzaky, wọn si fi i pamọ, gbogbo bi ile-ẹjọ si ti n pariwo, wọn ko da wọn lohun, Lai Muhammed waa sọ nisinyii pe miliọnu mẹta ataabọ lawọn fi n bọ ọ loṣooṣu. Ẹjọ ta waa ni. Ounjẹ kin ni wọn n fun ọkunrin yii ti wọn fi n na iru owo to to bẹẹ! Ṣe Alaaji Lai Muhammed yoo sọ pe oun o mọ pe awọn eeyan kan lo wa nibẹ ti wọn n ko owo ounjẹ yii jẹ ni? Abiru awọn eeyan wo lo n ṣejọba yii paapaa!

(45)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.