Iyẹn ni pe Ambọde tun le di ọrẹ Sanwo-olu

Spread the love

Nigba ti ibo abẹle ti ẹgbẹ APC Eko di ku ọtunla, ti Gomina Akinwumi Ambọde n bu iya Jide Sanwo-olu, to n fi baba rẹ le e, to n pe e ni ọdaran ati alawoku, ko si ẹni to ro pe wọn yoo tun jọ ṣe ọrẹ mọ laye, ẹni ti ko ba mọ ọrọ oṣelu, yoo ro pe ọta ni wọn yoo ṣe titi ti wọn yoo fi ku ni. Ṣugbọn ni gbara ti wọn kede pe Sanwo-olu lo wọle ibo, loju ẹsẹ naa ni Ambọde ti ki i ku oriire, lo si ti sọ pe oun yoo ṣiṣẹ lati ri i pe oun lo wọle, awọn yoo si jọ ṣe e ti yoo fi di gomina, oun yoo si ṣe atilẹyin fun un lati ri i pe ijọba rẹ yọri si rere. Bi aye awọn oloṣelu ti Naijiria tiwa nibi ti ri niyẹn, nigba ti ibo ba n bọ bayii, wọn yoo bu ara wọn debii oju iku, wọn yoo bu baba ati iya ara wọn, asiri to ti bo lati ọjọ yii ti ko sẹni to gbọ, loju ẹsẹ lawọn oloṣelu yoo tu u sita. Tabi bawo leeyan yoo ṣe mọ pe Sanwo-olu gba itọju lọsibitu ni Gbagada, tabi pe o ti figba kan lufin ijọba ni Amẹrika to n gbe tẹlẹ. Bo ba jẹ wọn ko tete ba awọn ọmọlẹyin Sanwo-olu sọrọ ni, awọn naa ti kede pe awọn yoo bẹrẹ si i yi awọn agba nla nla jade o, awọn aṣiri buruku tẹnikan ko gbọ ri nipa Ambọde, awọn yoo bẹrẹ si i ju u sita o. Ṣugbọn awọn agbaagba tete da si i, lawọn eeyan naa ko ṣe wi kinni kan titi ti wọn fi dibo naa tan. Wọn dibo tan bayii o, awọn mejeeji si ti tun dọrẹ ara wọn. Iyẹn lawọn ti wọn n sare lẹyin awọn oloṣelu ṣe gbọdọ ṣọ ara wọn, wọn gbọdọ lo laakaye wọn bi wọn ba n ja ija oṣelu, nitori awọn ti wọn n tori ẹ ja yii, ọrẹ ni wọn, ọrọ owo ati ipo lo daja wọn silẹ, bo ba si ti pada bọ sọwọ ẹni kan ninu wọn, wọn yoo tun dọrẹ ara wọn naa ni. Ẹni to ba ti ku ni tirẹ gbe, ẹni ti wọn ba ti sọ di alaabọ ara ni yoo maa jiya rẹ, ẹni ti wọn ba si ti ba ile ati ọna rẹ jẹ ni yoo foju wina iya ati iṣẹ to ba ti idi ẹ yọ foun. Oloṣelu yoo tun maa sọrọ ara wọn, koda, wọn yoo purọ mọ ara wọn nitori ki wọn le depo ni, ki i ṣe nitori wọn fẹran araalu, tabi pe awọn eeyan ilu jẹ kinni kan si wọn. Ki awọn depo, ki ọwọ awọn naa debi ti owo wa, ki wọn si le paṣẹ, nitori rẹ ni gbogbo ariwo ti wọn n pa. Ko ju bẹẹ lọ. Tabi ẹyin mọ pe Ambọde yoo tun pada di ọrẹ Sanwo-olu laarin ọjọ mẹta sira wọn! Bi ọrọ awọn oloṣelu ṣe ri niyẹn o.

 

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.