Iyẹn ni Bukọla Saraki ṣe tu aṣiri ara tiẹ faye gbọ

Spread the love

Tabi ẹyin naa ko ti i gbọ ọrọ ti Olori Ile-igbimọ Aṣofin ilẹ wa, Alaaji Bukọla Saraki, sọ tawọn eeyan n gbe kiri lori ẹrọ ayelujara. Nibi to ti n ba awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ, PDP, sọrọ lo ti ju awọn ọrọ naa lulẹ, ohun ti oun ko si mọ ni pe awọn ọta rẹ wa ninu ile nibẹ, awọn naa n ka ohun rẹ silẹ, wọn n gbọ ohun to n sọ, ọrọ to sọ naa ni wọn si gbe fun gbogbo aye gbọ. Saraki ni nigba ti awọn n ṣeto idibo fun Buhari ti awọn n kampeeni, ko si ipinlẹ ti oun ko de lorilẹ-ede yii, bi oun si ti n lọ loun n nawo fun wọn, ọpọ ipinlẹ loun si ti na owo to to miliọnu lọna ọgọrun-un mẹrin (N400m) ki Buhari le wọle. O ni ohun ti oun ṣe n nawo naa ni pe bi awọn ba dibo tan, Buhari yoo fi ọpọlọpọ ileeṣẹ ijọba fun oun atawọn eeyan ti wọn jọ ṣe wahala naa, oun yoo si le pin in kari fun gbogbo awọn aṣaaju to duro ti awọn, ṣugbọn o ni nigba ti Buhari wọle, ko foun ni awọn iṣẹ yii ṣe, bẹẹ ni ko yan awọn eeyan oun kankan sipo, ohun ti oun ṣe fibinu kuro ninu APC ti oun pada si PDP niyẹn. Nigba ti ẹ ba gbọ iru awọn ọrọ bayii, ibeere akọkọ ti yoo wa sọkan eeyan ni pe ninu gbogbo ariwo ti ọkunrin oloṣelu Kwara yii pa yii, ewo lo ṣe awọn ara Kwara lanfaani ninu ohun to sọ, ewo lo ṣe Naijiria lanfaani ninu ẹ. Owo to n na kiri nitori pe o fẹẹ gba ipo lọwọ Buhari ni, nigba ti ko si ri ipo gba mọ lo bẹ jade. Owo ẹ to naa nijọsi lasiko ibo naa paapaa, ṣebi o yẹ keeyan beere ibi to ti ri i, iṣẹ to ṣe to to bẹẹ ti owo bẹẹ fi wa lọwọ rẹ. Tabi ileeṣẹ to da silẹ to n mowo wọle fun un. Ṣebi nidii oṣelu yii naa ni, ṣebi owo to tọ si awọn ara Kwara loun n gba, to n ji pupọ nibẹ, nitori wọn wa nipo gomina, ṣebi owo naa lo tun n pada waa na. Itumọ eyi ni pe oṣelu ti awọn n ṣe ki i ṣe oṣelu lati tun ilu ṣe, oṣelu lati jale ni. Ẹyin ara Kwara, ẹyin naa ti feti ara yin gbọ bayii, bi kinni naa si ṣe wa kaakiri ipinlẹ gbogbo niyi, awọn oloṣelu ole lo yi wa ka. Ẹ yẹra fun wọn; igaara ọlọṣa ni wọn, ẹ ma jẹ ki wọn ba yin laye jẹ o.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.