Iyẹn ni Bola Tinubu paapaa ṣe gbọdọ ṣọ ara rẹ gidigidi

Spread the love

Ninu gbogbo awọn ti wọn n sọ oko ọrọ si Ọbasanjọ nitori lẹta to kọ si Buhari, o daju pe eyi ti yoo dun baba naa ju ni eyi ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti i ṣe aṣaaju APC sọ si i. Tinubu ni Ọbasanjọ ti dagba, o ti n ṣaran, ati pe ọlọgbọn kan ko gbọdọ ka ọrọ rẹ si, nitori awọn ohun to n jade lẹnu baba naa lasiko yii ọrọ ẹni to n ṣaran ni. O ni boya Ọbasanjọ fẹ, boya o kọ, Buhari ni yoo wọle, koda ko lọọ ko awọn ọga ṣọja ẹgbẹ rẹ to ti fẹyinti jọ. O ni ko si ohun ti Ọbasanjọ le ṣe mọ, nitori ko ni agbara, ko si lero lẹyin, ko wabi kan jokoo si ko lọọ sẹnpẹ. O ni ohun to n ka baba yii lara ni pe gbogbo awọn ohun ti Buhari n ṣe yii, oun ko ṣe bẹẹ, nitori pe Buhari si ṣejọba daadaa ju u lọ lo ṣe n jowu rẹ, nitori baba naa ki i fẹ kẹnikẹni ju oun lọ. Tinubu ni Ọbasanjọ ti tẹ ni Naijiria, ko si jẹ nnkan kan loju ẹnibọdi mọ, bẹẹ ni agbara kankan ko si lọwọ rẹ to le fi halẹ mọ ẹnikẹni, ki baba lọọ wabi jokoo si ṣaa. Bi eeyan ba n ka awọn ọrọ ti Tinubu sọ si Ọbasanjọ, bo ba ri baba yii, yoo fẹrẹ le bẹ ẹ lori, nitori aṣaaju awọn APC naa sọ kobakungbe ọrọ si i. Yoo yaayan lẹnu pe Tinubu yii lo ṣaaju awọn APC ti wọn mu Buhari lọ sọdọ Ọbasanjọ ni 2015, nigba ti wọn fẹ ki wọn dibo fun un, ti wọn si ni awọn wa si ọdọ Ọbasanjọ ko le jẹ aṣaaju awọn lati ba awọn le Jonathan lọ, ki wọn si gbajọba fun Buhari. Pe Ọbasanjọ naa ni yoo waa di igba-ikolẹ bayii niwaju Tinubu fihan pe ọrọ awọn oloṣelu yii, too-too-too ni. Amọ ki Tinubu ṣọra gidi ni, nitori paṣan ti wọn fi na iyaale ni o, o n bẹ loke aja fun iyawo, bo ba di asiko ti iyawo naa, wọn yoo yi ẹgba rẹ si i. Ni ilẹ Yoruba loni-in, tabi ni Naijiria, ko si aṣaaju kan ninu ẹya kan ti awọn olori Hausa fi ọkan tan ju Ọbasanjọ lọ, nitori wọn ti lo o, wọn si mọ pe ko le fi awọn silẹ, wọn fọkan tan an de gongo. Awọn eeyan yii si mọ pe oloṣelu ni Tinubu, wọn mọ pe nitori pe agbara wa lọwọ awọn bayii lo ṣe n ba awọn ṣe, bi agbara ba de ọwọ ẹlomiiran lọla, yoo pada sọdọ wọn. Nitori bẹẹ, wọn ko ni i fọkan tan Tinubu bii Ọbasanjọ. Amọ pataki ibẹ tilẹ ni pe lọjọ kan ti ija ba de, ti ija de laarin Tinubu ati awọn ọrẹ rẹ tuntun yii, ile ta ni Tinubu yoo pada si, ko ni i le gbe ilẹ Hausa, koda ilu Abuja to kọle si ko ni i gba a, yoo fẹ ko jẹ aarin awọn Yoruba loun wa, ohun to ba fẹẹ ṣẹlẹ soun ko ṣoju wọn. Ẹni to ba waa mọ pe oun ko ni ibi ti oun fẹẹ sa lọ tija ba de ju ile baba oun lọ, tọhun ki i ba ile baba rẹ naa jẹ o. Ki Tinubu ro o daadaa ko too sọrọ si Ọbasanjọ, nitori ohun to le lẹyin ni. Ikilọ lasan ni o.

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.