Iyẹn lo sọ Saraki di fẹndọ, lo ba n pariwo ẹnu

Spread the love

Awọn oloṣelu ti ẹ n ri yẹn, ki i ṣe pe wọn jẹ kinni kan ju araalu lọ. Ohun meji ti wọn n lo naa ni tọọgi ati ọlọpaa, bi oloṣelu kan ko ba ti ni meji yii, ofuutufẹẹtẹ, otubantẹ lasan ni, tabi ka sọ pe korofo. Awọn tọọgi ni wọn maa n ko rin, wọn yoo waa fi ọlọpaa kan tabi meji si aarin wọn. Awọn ibi ti wọn ti n wọle ibo ti awọn eeyan yoo maa pariwo pe wọn gbajumọ, awọn tọọgi ati ọlọpaa lo n ba wọn ji apoti ibo, awọn ni wọn n ba wọn le awọn alatako wọn lọ. Njẹ ẹ ti gbọ ariwo ti ọmọ Baba Oloye, iyẹn Bukọla Saraki, n pa kaakiri bayii. O ni ki awọn aye gba oun ni, nitori ọga ọlọpaa pata, Ibrahim Idris, fẹẹ ba toun jẹ. Ṣe ẹ mọ pe ọjọ ija awọn mejeeji ti pẹ diẹ, ṣugbọn ko sẹni to mọ pe kinni naa tun n le si i ni. N lawọn eeyan ba n beere pe bawo ni ọga ọlọpaa ṣe fẹẹ ba ti Saraki jẹ, nigba to jẹ olori ile-igbimọ aṣofin agba loun naa n ṣe, ta lo waa lagbara ju ẹni kan lọ. Saraki ni ọga ọlọpaa yii lo n daabo bo awọn tọọgi Ilọrin ati agbegbe rẹ, pe gbogbo aburu ti awọn tọọgi n ṣe fawọn ọmọ ẹgbẹ oun, iyẹn PDP, niṣe lawọn ọlọpaa n daabo bo wọn, ti wọn ko si mu wọn. Ni Saraki ba ni bi oun ba ku lojiji, kẹnikan ma ṣẹṣẹ maa beere iru iku to pa oun o, Idris, ọga ọlọpaa, lo wa nidii ẹ. Awọn eeyan to ba gbọ bayii yoo maa rẹrin-in ni, nitori bi eeyan ba sọ pe wọn le fi tọọgi halẹ mọ Saraki n’Ilọrin, tọhun yoo ni irọ ni. Tabi ta lolori awọn tọọgi, tọọgi wo ni Saraki fẹẹ lo n’Ilọrin ti ko ni i ri, tabi tọọgi wo ni yoo ni oun ko mọ Saraki ni Kwara. Ṣugbọn nnkan ti yipada, ko si agbara ijọba lọwọ Saraki, awọn tọọgi si yẹra fun un. Awọn tọọgi to wa bayii, ***ọda ni wọn n gba, bẹẹ ni wọn si ni ọlọpaa lọdọ to n daabo bo wọn. Saraki mọ pe bi wọn ba pade oun lojiji, o lewu, nitori bi wọn ba n ṣe kinni kan foun, awọn ọlọpaa yoo sọ pe awọn ko si nitosi ni, bẹẹ ni ki i ṣe tọọgi, awọn oloṣelu ọmọ ẹgbẹ PDP ni. Iyẹn ni Saraki ṣe n pariwo, ṣe apani lawọn oloṣelu, wọn ki i fẹ ki wọn mu ida kọja niwaju awọn. Iyẹn ni pe awọn oloṣelu asiko yii ko jẹ kinni kan bi a ba ti yọwọ agbara ijọba ati tọọgi, iyẹn ni gbogbo wọn ṣe n ṣebajẹ kaakiri. Ẹ sọ fun Saraki ko ma pariwo iranu si ẹnibọdi leti mọ, ọjọ ẹsan lo de, ko yaa fara mọ gbogbo ohun to ba ri ni.

 

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.