Iyẹn lo ṣe jẹ pe ariwo lasan ni Jonathan n pa

Spread the love

Ohun to gbe wa de ibi ti a wa yii, iwa ibajẹ ni. Iwa ibajẹ ijọba yii, ati ti ijọba to kọja lọ. Nnkan ko kuku ṣe bayii bajẹ laye Ọbasanjọ. Ṣugbọn aye Jonathan ni ibajẹ nidii ọrọ Boko Haram yii naa pọ ju, nitori oun naa ko gba pe awọn kan n jẹ Boko Haram, o ro pe awọn alatako oun, awọn APC, ni wọn ṣeto naa lati fi ba ijọba oun jẹ, o kọ ọrọ naa sinu iwe tuntun to kọ jade paapaa. Iyẹn lo ṣe jẹ pe gbogbo owo ti ijọba rẹ ko jọ, owo ti wọn ya sọtọ, bi owo naa ṣe pọ to lati fi ṣeto ohun eelo ogun, ati lati tọju awọn ṣọja, ọtọ lohun ti wọn fowo naa ṣe. Awọn to fi sidii ẹ n ji owo ko lọ ni, bẹẹ ni Jonathan yi oju rẹ sẹgbẹẹ kan, gbogbo owo ti wọn iba si fi jagun Boko Haram, ori ọrọ ibo ni wọn na an le, ti awọn ole, jaguda, olorikori oloṣelu ti wọn jọ ko ara wọn jọ nigba naa si ko owo naa sapo ara wọn. Awọn were naa wa niluu ti wọn n rin kiri bayii lẹyin ti wọn ti ko owo awọn ṣọja yii jẹ, aye si n wo wọn bii eeyan gidi. Lara ohun ti ko le jẹ ki ọrọ Jonathan ta leti eeyan ree, koda ko maa fi ojoojumọ kọwe alaye, ko si ohun ti yoo sọ ti yoo tun wulo leti ẹnikan mọ. Lara awọn ohun to n pa wa niyẹn, nigba ti eeyan ba bọ sipo kan ti ko ni iriri ni asiko naa, ti ko si kẹkọọ kan nipa ipo naa, ti ko si ni atinuda ati imọwọn-ara-ẹni lati le sọ pe n ko ṣe iṣẹ yii, bo ba gba ipo naa, kaka ko tun aye awọn eeyan ṣe, yoo ba a jẹ si i ni. Orukọ lo ro Jonathan, Goodluck (Oriire), iyẹn ni awọn ipo wọnyi fi de ọwọ rẹ, ṣugbọn ko ni imọ kikun lori iṣẹ ilu, o si fi ọwọ ara rẹ ba anfaani ati oriire to wa lọwọ rẹ jẹ. Ṣebi nigba to fẹẹ gbajọba ilẹ yii lẹyin iku Yaradua, ṣebi gbogbo ọmọ Naijiria ni wọn ni oun ni ipo naa tọ si, ti wọn si fi gbogbo ara dibo fun un, ki lo de ti awọn oloṣelu ko da ọmọ Naijiria duro nigba naa. Ṣugbọn nigba to gbajọba to ṣe e baṣubaṣu, ti iwa ibajẹ ati ole jija si fi inu ijọba rẹ ṣebugbe, ṣebi iyẹn laye ṣe pada lẹyin rẹ. Awọn iwa oriburuku ti wọn n hu nigba naa lo n ja ran-in ran-in nilẹ yii, iwe jakujaku wo lo waa n kọ kiri. Ẹ sọ pe ko jokoo jẹẹ jare.

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.