Iyẹn la ṣe gbọdọ beere pe ki l’Ọṣinbajo n wa kiri

Spread the love

Ọsẹ ti inira buruku yii ba awọn ara ilu, paapaa awọn eeyan ilẹ Yoruba, ọsẹ yii naa ni Igbakeji Aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo wa sọdọ wa nibi, to ni oun n ṣe kampeeni kiri, kampeeni oṣelu, ariwo, ‘ẹ dibo fun Buhari’ lo si gba gbogbo ilẹ yii kan fun ọjọ meji ti ọkunrin naa fi wa nilẹ wa. Ohun tara agbegbe kan ṣe maa n pariwo pe kawọn ni ẹni tiwọn nijọba ni ki iru ẹni bẹẹ le ja fun wọn, ko si mu idagbasoke ba adugbo wọn. Amọ yoo ṣoro gidi lati le tọka si ohun meremere kan, tabi idagbasoke gidi kan, ti Ọṣinbajo gba wa fun wa. Eleyii ki ṣe ọrọ oṣelu tabi ọrọ eebu, ọrọ iṣẹ ijọba ni. Bi eniyan ba wa ni ipo pataki bayii, awọn ti wọn jọ n ṣejọba gbọdọ maa fi awọn ohun pataki kan silẹ fun un, ki wọn si maa tun adugbo to ti wa ṣe yatọ, nitori ko le ri nnkan tọka si fawọn eeyan rẹ ni. Ṣugbọn ko jọ pe ijọba tawọn Buhari yii ka Ọṣinbajo si to bẹẹ, iyẹn naa ni wọn si ṣe gbe iṣẹ ko maa rin kiri ilu fun un, ko maa ba wọn purọ, ko maa ṣalaye ohun ti wọn ko ṣe ati idi ti wọn ko fi ṣe e, bo tilẹ jẹ pe ileri ti wọn ṣe tẹlẹ ni pe awọn yoo ṣe e. Ọmọ ọlọmọ ni a n ran niṣẹ de toru-toru, ṣugbọn aimọṣẹẹ-kọ ọmọrogun ni i jẹ ko tori bọ omi gbigbona, o yẹ ki Ọṣinbajo funra rẹ niṣẹ ti yoo jẹ fun Buhari, ati ohun ti yoo sọ fawọn eeyan agbegbe ilẹ Yoruba. Koko ibẹ ni pe Buhari ko ṣe oore kan fun wa, a ko gbadun Ọṣinbajo gẹgẹ bii igbakeji aarẹ Naijiria, ko si si a n fi ọwọ bo ara wa lẹnu nibẹ, bi ọrọ ti ri gan-an niyẹn. Wọn ni ki Ọṣinbajo maa rin kiri ilu oriṣiiriṣii bayii lasiko ti awọn jokoo si Abuja ti wọn n yi gbogbo nnkan lori pada, ti wọn n yan awọn eeyan tiwọn siṣẹ, ti wọn n ko owo ati ohun-ini ijọba apapọ fun awọn eeyan tiwọn nikan. Kin ni irin ti Ọṣinbajo n rin kiri yii ja mọ bayii. Wọn lo n ṣe kampeeni, ṣe oun lawọn eeyan fẹẹ dibo fun ni. Ṣebi Buhari lo fẹẹ gbe apoti, ki lo de ti oun Buhari ko le jade. Bi Ọṣinbajo ba pada si Abuja, ko ba Buhari sọrọ, ko sọ fun un pe inu awọn eeyan rẹ ko dun si bi wọn ṣe gba a sẹyin ninu ijọba ti wọn n jọ n ṣe. Amọ bo ba jokoo sidii irọ, to jokoo sidii abosi ti wọn jọ n ṣe yii, orukọ rere to ti ni tẹlẹ ko too gba iṣẹ awọn Buhari yii, orukọ naa yoo bajẹ ti ko ni i ṣee tun ṣe mọ. Asiko to ti Ọṣinbajo gbọdọ sọ fawọn ti wọn jọ n ṣejọba pe eeyan gidi kan loun naa ninu ijọba Buhari.

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.