Iyawo Profeso ti won lo fee ba akekoo lo po ni iro ni won pa mo oko oun

Spread the love

Bii igba teeyan dana ẹẹrun lọrọ naa ran kalẹ lale ọjọo Mọnde to kọja lọhun-un, gbogbo eeyan ni wọn si n gba a bii ẹni gba igba ọti. Ṣe ni fọnran kan deede yọju jade latori ẹrọ ayelujara tẹnikẹni ko le sọ pato ẹni to gbe e sibẹ.

Ninu fọnran naa ni ifọrọjomitooro ọrọ ti waye laarin akẹkọbinrin ile ẹkọ giga Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ileefẹ, ati ọjọgbọn kan to jẹ olukọ ni ẹka iṣiro owo nileewe naa, Ọjọgbọn Richard Akindele.

Ninu fọnran naa ni ohun ẹnikan ti wọn pe ni ti Ọjọgbọn Akindele ti n beere fun ibalopọ ẹẹmarun-un ọtọọtọ ko too le fun ọmọ naa ni maaki meje to ku ti yoo fi ṣaseyọri ninu iṣẹ kan lẹka naa.

Bo tilẹ jẹ pe oju ọtọọtọ lawọn araalu fi wo ọrọ naa, bi awọn kan ṣe n sọ pe ko si ohun tuntun labẹ ọrun, ọmọ taye n bi laye n pọn, ati pe ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ lawọn ile ẹkọ giga atawọn ileeṣẹ nla nla, bẹẹ lawọn kan nigbagbọ pe gẹgẹ bii iranṣẹ Ọlọrun ti wọn n pe Ọjọgbọn Akindele, iwa to hu naa ko bojumu.

Bi ọrọ yii ṣe n ja ran-in-ran-in nilẹ lawọn alaṣẹ ileewe naa sọ pe awọn ti gbe igbimọ oluwadii kalẹ lati wadii boya ohun Ọjọgbọn Akindele lawọn eeyan n gbọ ninu fọnran naa tabi bẹẹ kọ, ko too di pe wọn yoo mọ iru igbesẹ ti wọn yoo gbe lori ọrọ naa.

Lọjọ keji ni wọn tun fun Akindele ni iwe waa-wi-tẹnu-ẹ lori iṣẹlẹ to ti tan jale-jako ọhun, ọla ọjọo Wẹsidee si nireti wa pe ọṣẹ kan ti wọn fun awọn igbimọ naa yoo pe.

Gẹgẹ bi alukoro ile-ẹkọ giga naa, Abiọdun Ọlarewaju, ṣe sọ fun Alaroye, o ni awọn alaṣẹ ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa, ṣugbọn wọn nilo ki ọmọbinrin to n sọrọ ninu fọnran naa jade si gbangba nibikibi to ba wa lati waa sọ bi iṣu ṣe ku, ati bi ọbẹ ṣe bẹ ẹ.

Ọlarewaju ni bo tilẹ jẹ pe ọdun to kọja niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, sibẹ, awọn alaṣẹ yoo ri i pe iwadii ododo fidi mulẹ lori ọrọ naa.

Gbogbo igbiyanju wa lati ba Ọjọgbọn Akindele sọrọ lo ja si pabo nitori nọmba ibanisoro rẹ ko lọ, ṣugbọn iwadii Alaroye ninu ọgba OAU fidi rẹ mulẹ pe bii ẹni ṣere ọwọ lawọn ọga kan nibẹ maa n fi ibalopọ fun awọn akẹkọọ ni maaki ṣe.

Gẹgẹ bi akẹkọ kan to pe orukọ ara rẹ ni Taiwo ṣe sọ, ọkẹ aimọye iru ẹ lo n ṣẹlẹ ṣugbọn tawọn akẹkọọbinrin naa ki i le e sọ fẹnikẹni, afi eyi to ba laya bii ti aṣiri to tu yii.

O ni ọpọlọpọ awọn olukọ yii ni wọn buru debii pe wọn ko laaanu awọn akẹkọọbinrin loju, ṣe ni wọn maa n huwa ta ni yoo mu mi to ba ti di ọrọ fifi ibalopọ gba maaki.

Bakan naa ni akẹkọọjade lọgba OAU to forileede Ireland ṣebujoko bayii sọ sori ẹrọ fesibuuku pe Ọlọrun nikan lo ko oun yọ lọwọ Ọjọgbọn Akindele yii kan naa ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin toun jẹ akẹkọọ nigba to yari kanlẹ pe afi dandan koun fẹyin oun balẹ.

Oniruuru nnkan lawọn ọmọ-ijọ Anglican ti Ọjọgbọn Richard, ọmọ bibi ilu Ikire, nijọba ibilẹ Irewọle, nipinlẹ Ọṣun, yii ti jẹ iranṣẹ Ọlọrun n sọ, bi awọn kan ṣe n sọ pe irọ ni wọn pa mọ ọkunrin naa lawọn mi-in n sọ pe ko nilo wahala kankan rara lati mọ pe ohun Ọjọgbọn Akindele lo wa ninu fọnran naa, ṣugbọn o jẹ oniwatutu ju ko ṣe iru ẹsun ti wọn fi kan yii lọ.

Amọ ṣa, abọ igbimọ oluwadii ni yoo sọ boya Ọjọgbọn Richard Akindele jẹbi ẹsun naa tabi ko jẹbi.

(53)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.