Iyawo mi n ṣoogun, o tun fẹẹ ṣeku pa mi

Spread the love

Kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Ikarẹ Akoko ti paṣẹ pe ki igbeyawo ọdun mọkanlelogun kan di tituka lori ẹsun oogun ṣiṣe ti Ogunmọla Ọdunayọ Emmanuel, ẹni aadọta ọdun fi kan iyawo rẹ, Taiwo Florence Ogunmọla.

 

Ninu alaye ti olupẹjọ ṣe lasiko to mu ẹsun iyawo rẹ wa si kootu ọhun lo ti juwe iyawo rẹ bii oloogun paraku, o ni gbogbo ọna lobinrin naa n wa lati gbẹmi oun.

 

Baale ile yii ni iyawo oun ti figba kan gbe asejẹ oogun kan waa ka oun mọle, to si sọ pe awọn gbọdọ jọ wẹ papọ ko too di pe awọn jọ jẹ ẹ.

 

Asejẹ ti wọn fi odidi ẹja kan ṣe ọhun lo ni oun jẹ iru rẹ, nigba ti iyawo oun jẹ ori. O ni lẹyin ti awọn jẹ ẹ tan lobinrin naa tun fi dandan le e pe awọn gbọdọ jọ lajọṣepọ, eyi ti oun kọ jalẹ fun un.

 

Esun mi-in to tun fi kan iyawo rẹ ni pe gbogbo igba lo maa n ba oun ja lori ọrọ ti ko to nnkan, ọpọlọpọ awọn nnkan ini oun lo ni o ti bajẹ lasiko ti awọn ba jọ n ja.

 

Igba kan wa to ni iyawo oun da ata le ọkan ninu awọn ọmọ to bi foun lori nitori pe iyẹn ko tete de lati ibi to ran an. Bakan naa lo tun fẹsun irinkurin kan obinrin naa, o ni igba to ba wu u lo maa n jade, to si tun maa n wọle lasiko to ba fẹ, toun ko si gbọdọ sọrọ.

 

O ni ki kootu tete tu awọn ka nitori pe oun mọ pe niṣe lobinrin naa fẹẹ pa oun pẹlu gbogbo igbesẹ to n gbe naa.

 

Ninu alaye tirẹ, Abilekọ Taiwo ṣe kanlẹ lori gbogbo ẹsun ti ọkọ rẹ fi kan an. Olujẹjọ naa jẹwọ pe loootọ loun n gba oogun wale gẹgẹ bi ọkọ oun ṣe sọ. Iyaale ile yii ni nitori ọkọ oun gan-an loun ṣe n ṣe gbogbo aajo naa lati da awọn ikolọ rẹ to ti lọ pada, nitori pe ko si iṣẹ kankan lọwọ rẹ mọ lasiko ti oun fi ṣe ohun toun ṣe naa.

 

Lẹyin ti gbogbo akitiyan ẹbi awọn mejeeji lati ba wọn yanju ede aiyede to wa laarin wọn ko seso rere ni Aarẹ kootu ọhun, Alagba E.O. Adelabu, paṣẹ pe ki ibaṣepọ ọdun mọkanlelogun to wa laarin wọn di tituka.

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.