Iyawo jẹwọ ni kootu, o ni ale loun bi akọbi ọmọ oun fun ni Ṣaki

Spread the love

Bii sinima agbelewo lọrọ naa jọ loju awọn oluworan to wa ni ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa laduugbo Sango, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, nigba ti iyawo ile kan, Abibatu Abẹwọn, sọ fun kootu pe ki ile-ẹjọ fopin si igbeyawo to wa laarin oun ati ọkọ oun, Abduljẹlili Abdulrasaq, o ni ko si ifẹ mọ laarin awọn.
Nigba to n sọrọ nile-ẹjọ, Abibatu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, to n gbe lagboole Atilade, ladugbo Ọtun, niluu Ṣaki, ṣalaye pe oun tun fẹẹ gba akọbi ọmọ  awọn sọdọ. Obinrin naa ni idi toun fi fẹẹ gba akọbi awọn sọdọ ni pe ki i ṣe ọkọ oun lo ni ọmọ naa ọdun mejila naa torukọ rẹ n jẹ Abdulyekeen.

Lasiko ti kootu n beere lọwọ Jẹlili boya o faramọ ọrọ ti iyawo rẹ sọ ni kootu, ọkunrin naa ni ki ile-ẹjọ jọwọ ba oun bi iyawo oun leere idi to fi sọ pe ki i ṣe oun loun ni Abdulyekeen. Jẹlili sọ pe ileewe girama niyawo oun wa toun fi fun loyun, toun si fẹ ẹ.

Abibatu, lasiko to n dahun si ibeere yii sọ pe oyun oṣu mẹta, eyi toun fi bi Abdulyekeen, ti wa lara oun koun too fẹ ọkọ oun, ṣugbọn oun ko sọ fun un.

Abibatu sọ pe awọn ọrẹ oun meji pere lo mọ sọrọ oyun naa, oun si ti ṣetan lati ko wọn wa si kootu, ki wọn le waa jẹrii nipa rẹ.

 

Ẹkun ni Ọgbẹni Abduljẹlili Abdulrasaq bu si nile-ẹjọ pẹlu iroyin buruku ti Abibatu fi to ile-ẹjọ naa leti latari pe lọjọ ti wọn ṣekomọ ọmọ naa, aye gbọ, ọrun mọ pẹlu bo ṣe nawo to si tun n tọju ọmọ naa titi to fi pe ọmọ ọdun mejila.
Ọkunrin naa, ẹni to ni ẹni ọdun mejilelogoji loun, to si ni orin Fuji loun n kọ niluu Ibadan, sọ pe Abdulyekeen jẹ ọmọ toun fẹran gidigidi debii pe oun nikan lo n lo sileewe aladaani laarin awọn ọmọ oun.
Adajọ ile-ẹjọ ọhun, Oloye Muritala Ọladipupọ, pẹtu si awọn mejeeji lati gba alaafia laaye, to si rọ ọkunrin naa lati ko awọn ọmọ mejeeji  wa si ile-ẹjọ. Ọsẹ yii ni igbẹjọ naa n tẹsiwaju.

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.