Iyawo alaga kansu ku ninu ijamba ọkọ l’Oke-Ogun

Spread the love

Laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni iyawo Alaga ijọba ibilẹ Onidagbasoke Asabari kin-in-ni, nipinlẹ Ọyọ, iyẹn Ọnarebu Kareem Adegoke, Abilekọ Sherifat Abimbọla Adegoke, padanu ẹmi rẹ sinu iṣẹlẹ ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lọna ilu Ipapo, nijọba ibilẹ Itẹsiwaju, niluu Iṣẹyin.

Ọkọ Dangote kan to ko simẹnti lo ya lọọ ba ọkọ ayọkẹlẹ Golf to gbe awọn iyawo alaga ijọba ibilẹ mẹta, iyẹn Abilekọ Grace Ọlawuwo, ti i ṣe iyawo alaga ijọba ibilẹ Onidagbasoke Wẹwẹ, Abilekọ Funmi Salau, to jẹ iyawo alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki ati oloogbe naa, lasiko ti wọn lọọ ṣepade pẹlu iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ, Florence Ajimọbi, niluu Ibadan.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ naa ni ọkọ ajagbe Dangote kan ya kuro loju ọna rẹ, to si lọọ fori sọ ọkọ naa, lẹsẹkẹsẹ ni Abilekọ Abimbọla ku, ti awọn meji yooku pẹlu dereba wọn si farapa pupọ. Ileewosan aladaani FADOK, to wa niluu Iṣẹyin, ni wọn gbe awọn to farapa lọ fun itọju.

Bo tilẹ jẹ pe ogunlọgọ awọn eeyan lo ti n lọọ ba Alaga ijọba ibilẹ Asabari, Ọnarebu Kareem Adegoke, kẹdun adanu rẹ, sibẹ, inu ọkunrin naa ko dun rara lasiko ti akọroyin wa ṣabẹwo si i, koda, o kọ lati sọrọ.

Lara awọn to ti ṣabẹwo ibanikẹdun si i ni Ọgbẹni Matthew Ọlawuwo, Alaaji Nasiru Salami, Oloye Oluṣọla Ogundeji, ti i ṣe alaga ijọba ibilẹ Onidagbasoke Atisbo, Ọnarebu Rafiu Adekunle, Ọnarebu Jimoh Adeniyi, ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu gbogbo.

Iṣẹ nọọsi la gbọ pe Sherifat n ṣe ko too fẹyinti. O fi ọpọlọpọ ọmọ silẹ saye lọ. Ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa ni wọn ti sinku rẹ sinu ile ọkọ rẹ to wa laduugbo Ṣangotẹ, niluu Ṣaki.

 

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.