Iya Sẹlim bimọ tan lo ku l’Abẹokuta, lasiko ti wọn fẹẹ sin in ni wọn ri i pe wọn ti ge imu rẹ lọ

Spread the love

Iba ṣe pe oku n wẹyin, ka ni o ṣee ṣe fawọn tiku wọn ba mu ẹjọ dani lati dide, ki wọn ṣalaye ohun to ṣokunkun sawọn eeyan aye yooku, kedere ni oju aṣebi ko ba maa han lode kia, ṣugbọn ẹni to ku ki i wẹyin, o tun di laelae pọngba. Ọpọ aṣiri ko ni i han laye yii, afi lode ọrun.

Obinrin kan ti wọn n pe ni Iya Sẹlim, ni Ṣajẹ, l’Abẹokuta, ni iku rẹ mu ẹjọ dani. Ọmọ lo bi tan lọjọ Jimọh to kọja lọhun-un, to si gbabẹ jade laye, ṣugbọn ki i ṣe ẹsẹkẹsẹ to bimọ naa lo ku iku ọhun. Njẹ ki wọn sinku ẹ ni wọn ri i pe wọn ti ge ibi kan nibi imu rẹ lọ, bẹẹ ni apa kan ibi apa osi rẹ naa ti di gige, niṣe lo jin fotoro.

Ṣe ole ko ni i ja agba ko ma ṣe e loju firi, ọkọ ti obinrin yii bimọ fun, Isiaka Balogun, to n ṣiṣẹ ọkada gigun lawọn eeyan n fẹsun kan pe o ṣiṣẹ naa. Ohun ti ALAROYE ri gbọ ni pe Saida gan-an lorukọ Iya Sẹlim, ko si ki n ṣe ọmọde mọ, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta(51), ni.

A gbọ pe obinrin yii ti lọkọ meji tẹlẹ, o si bimọ mẹta fawọn ọkọ meji yii, iyẹn ni pe o bi meji fun ọkunrin kan, o si bi ọmọ ẹyọ kan fun ọkọ keji, ṣugbọn ko si eyi to n fẹ mọ ninu awọn mejeeji, kaluku wọn ti ba tiẹ lọ.

Ẹni to fiṣẹlẹ yii to wa leti, to ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri, ṣalaye pe ko sẹni to rokan pe Iya Sẹlim tun le ronu ọkọ fifẹ mọ, nigba to jẹ agbalagba ni, to si tun jẹ pe ile iya rẹ to wa ni Ṣajẹ lo n gbe, ki i ṣe pe o da gbale kankan.
Afi bo ṣe tun di pe ọlọkada ti wọn n pe ni Isiaka yii tun bẹrẹ si i wa mama naa wa, ti wọn jọ n ṣe wọle-wọde.

Ninu ile iya to bi Iya Sẹlim yii naa ni ọkọ tuntun yii wa n fẹ ẹ mọ, ko si pẹ ti oyun fi wọ ọ. Oyun naa lobinrin yii fẹẹ bi ninu oṣu kẹwaa, to pari yii ti wahala fi de.

ALAROYE gbọ pe o tilẹ ti bimọ ọhun sinu ile, awọn iṣoro to maa n rọ mọ bibi ọmọ sile, ati pe obinrin yii ti dagba lo fa wahala, n lawọn araale fi dabaa pe ki wọn kuku maa gbe e lọ si ọsibitu Lantoro, l’Abẹokuta, lati doola ẹmi Iya Sẹlim.

Ọkọ to bimọ fun yii naa la gbọ pe o gbe e de Lantoro, lawọn iyẹn ba ni ko kọkọ lọọ mu ẹgbẹrun lọna ogun Naira wa na, nitori ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun lobinrin to bimọ sile naa wa, o si nilo itọju pajawiri, ṣugbọn owo ni koko.

Ninu ẹgbẹrun lọna ogun ti wọn ni ki Isiaka san, ẹgbẹrun mẹta Naira lo ni lọwọ. Awọn dokita sọ fun un pe ohun to n ṣe iyawo rẹ ki i ṣọrọ owo kekere bẹẹ, ko lọọ wa owo wa. Ai sowo lọwọ baba ikoko yii lo jẹ ko sọ fawọn dokita pe ki wọn jẹ koun maa gbe iyawo oun lọ, ko sibi toun yoo ti ri tuẹnti taosan ti wọn n beere, oun ko ni ju ẹgbẹrun mẹta lọ.

Bayii ni Isiaka Balogun gbe iyawo rẹ ti ẹjẹ n da lara rẹ naa kuro ni Lantoro, lo ba gbe e lọ si ọsibitu alaadani kan ti wọn n pe ni Mọtara, l’Abẹokuta kan naa. Ṣugbọn nigba ti yoo fi gbe obinrin naa debẹ, oku lẹlẹja n ta lọrọ di, awọn dokita ibẹ si sọ fun un lẹsẹkẹsẹ pe oku ni ẹni to gbe wa naa, wọn ni ko maa gbe e lọ.

Oku ọhun ko ṣe e sin lọjọ naa mọ, ile Isiaka to wa ni Labaiwa, l’Abẹokuta, la gbọ pe o gbe e lọ, ṣugbọn o pe awọn eeyan iyawo rẹ naa, wọn si ni ko maa gbe e bọ wa sọdọ awọn lọjọ keji.

Igba ti ọkunrin yii gbe oku debẹ bi a ṣe gbọ, o ti di i laṣọ, o si loun ti wẹ ẹ, ki wọn kan gbe e ju si koto ni, ko tun niidi ki wọn maa tu aṣọ lori oku to jẹ ara tutu lo fi di oloogbe bẹẹ.

Ọkan ninu awọn aburo Iya Sẹlim ni wọn lo taku pe oun fẹẹ ri oju ẹgbọn oun fun igba ikẹyin, obinrin yii lo ni ko si iru iku teeyan ku ti wọn ko waa ni le ṣi aṣọ loju ẹ, n lo ba taku pe oun ṣaa fẹẹ ri oju ẹgbọn oun dandan. Wọn ni Isiaka ni ki wọn ma da iyawo oun laamu, ṣugbọn awọn ẹbi iyawo taku.

Eyi ni wọn fi ṣi aṣọ loju oku naa, nigba naa ni wọn si ri i pe apa kan imu rẹ ti kuro nibẹ, n ni wọn ba tu aṣọ tọkọ rẹ fi we e naa delẹ, nigba naa ni apa kan ibi igunpa rẹ ti wọn ti fọbẹ ge naa tun foju han kedere, nibẹ ni wahala ti bẹrẹ, lawọn eeyan oku naa fi pero le ọkọ ọmọ wọn lori.

Magbọn, lọdọ awọn ọlọpaa FSARS, la gbọ pe wọn gbe Isiaka lọ, nibi ti wọn ti ti i mọle.

Akorọyin wa pe OC SARS, Ọgbẹni Adams Uba, lati fidi isẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn ipe naa ko kẹsẹ jari bi a ṣe gbiyanju to, awọn amugbalẹgbẹẹ rẹ lo ṣalaye fun wa pe ọkunrin naa ko si nitosi, o si ṣee ṣe ki safiisi ma daa nibi to wa naa. Wọn ni ṣugbọn ootọ niṣẹlẹ naa waye, iwadii si n lọ lati fidi ohun to sọ oku Iya Sẹlim di onimu rirejẹ, to tun ge nigun-un-pa mulẹ, yoo si foju han laipẹ.

Ọsibitu FMC, l’Abẹokuta, ni iya to bi Iya Sẹlim wa ni tiẹ, ara mama agbalagba naa ko ya tipẹ, tiẹ lawọn ẹbi naa si n mojuto bayii, nigba ti awọn ọlọpaa ti n gbọ ti ọmọ wọn ti wọn ge ẹya ara ẹ lọ.

(149)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.