Iya Biọla Risi ni Dele ti daran, mo lọmọ temi kọ

Spread the love

Inawo mi-in ti tun de o. Ọrọ naa tiẹ fẹẹ su mi, ko ṣaa jẹ ojoojumọ leeyan yoo maa nawo, ojumọ kan, inawo kan ni.  O kan jẹ pe mo maa n dupẹ fun Ọlọrun naa ni, nitori awọn inawo ti mo n na ni temi, inawo ayọ ni. Ọlọrun o jẹ ki n nawo ẹjọ, n ko si nawo aisan, owo ayọ lemi n na. Bi mo si ti n na an lo n tẹ mi lọrun, nitori mo mọ pe oore Ọlọrun ni. Eyi to de yii naa ti de, a maa na an naa ni. Ọmọ mi lo waa ba mi, Risi. Oun lo n fẹsẹ palẹ niwaju mi, o loun fẹẹ ri mi. Bo ṣe n ṣe mu ifura dani, iyẹn ni mo ṣe sare pe e pe Abbey, ṣe ko si nnkan o.

Abbey lemi naa n pe e latọjọ ti Dele ti waa ba mi to ni Abbey loun wa wa, ti mo ni ta lo n jẹ bẹẹ, to ti ni Abiọla ni. Lati igba yẹn lo ti jẹ ti emi naa ba fẹẹ fi i ṣe yẹyẹ, ti mi o fẹẹ pe e ni Risi, Abbey ni mo maa pe e, oun naa yoo si ti mọ pe mo n fi oun ṣe yẹyẹ ni, nitori o mọ pe Risi yẹn ni mo fẹran nitori orukọ suna to jẹ, to si jẹ oun naa, ọmọ to n lọ si asalaatu deede ni. Nigba ti mo pe e ni Abbey ti ko rẹrin-in, ti ko si sọrọ, to ṣaa n ṣoju bakan, ni mo ba fa a mọra, mo ni Risikat, ki lo de, waa sọ fun mi.

Lo ba ni nnkan kan ti ṣẹlẹ ni. Aya mi si sare ja, mo ni ki lo ṣẹlẹ, ki lo de, nitori n ko ri i ko ṣe bẹẹ yẹn ri, ohun to si le ṣẹlẹ ti yoo fi waa maa ṣe bii adiẹ ti ojo pa bayii ko ye mi, nitori ki i bẹru niwaju mi lati sọrọ, o mọ pe mo fẹran oun nitori ọmọ daadaa ni. Mo ni ki lo ṣẹlẹ, ko tun sọrọ, ni mo ba tun fa a, o waa sọ fun mi pe “Ṣebi Bọọda Dele naa ni!” Ibi ti ọkan mi lọ ni pe oun ati Dele ti ja ni, o si dun mi lati ọkan mi lọhun-un wa nitori mo mọ pe ọmọ daadaa lawọn mejeeji, yoo si dun mi ninu bi wọn ba ṣe tọkọ-taya. Mo ni, “Kinni Dele ṣe?”

O ni, “Ṣebi awọn ni wọn ti daran yẹn, ti wọn waa lawọn fẹẹ sa lọ! Mo si sọ nigba ti wọn fẹẹ ṣe kinni yẹn pe ọran ni, wọn o gbọ si mi lẹnu!” Ọrọ naa ko ti i ye mi sibẹ, ni mo ba tun bi i pe ọran wo ni Dele da, mo tiẹ ro pe boya nnkan kan ṣẹlẹ nileewe wọn ni. Afi bo ṣe la a mọlẹ fun mi: “Bọọda Dele kọ lo ti lọọ foluwarẹ loyun bayii, ti wọn o si gbọdọ mọ nile wa pe mo loyun!” Nigba naa ni aya mi balẹ wọọ, nitori gbogbo bo ṣe n sọrọ yẹn, ọtọ loun ti mo ṣebi. Niṣe ni mo bu ẹrin sẹẹkẹ ni temi, n ko si wi nnkan kan fungba pipẹ.

Oun naa ko sọrọ mọ, o n wo oju mi ni. Mo waa ni, iru ọran wo niyẹn, ṣe iwọ ti o gbedii ẹ silẹ fun un, ṣe o o mọ pe oyun lo n da ni. Ọmọ yẹn loun o mọ, pe oun o mọ pe ẹẹkan ti eeyan ba ti ṣe e lo n doyun bẹẹ. Ni mo ba tun wo oju ẹ, mo ni ṣe oun ko ṣe e ri lati ọjọ to ti n bọ ni, bo ti ṣe dagba to yii. Lo ba ma ni oun ko ma ṣe e ri, o lọkunrin ko ba oun sun ri, Dele ni ọkunrin akọkọ to ba oun ṣe, oun naa lo si gba ibale oun. Niṣe ni mo na ọwọ mi soke ti mo n ṣe alhamudu lilahi. N ko tilẹ mọ ohun ti mo tun le sọ mọ.

Emi o mọ pe iru awọn ọmọ bẹẹ wa laye ti a wa yii o. Ki ọmọ to gọlọtọgọlọtọ bẹẹ, to si ti lọ sileewe poli, ko ma ti i mọ ọkunrin. Haa, ṣe ẹ ri i pe ẹsin wa yii dara, ka foju awọn ọmọ wa mọ ọn, ko sohun to dara to o. Meloo meloo awọn ti ko to o rara ti wọn ti bimọ, awọn ti wọn si ti ṣẹyun loriṣiiriṣii nkọ. Teeyan ba sọ fun mi pe ọmọ Risi yii ko ti i mọ ọkunrin ni gbogbo igba ti mo fi n ri i ni ṣọọbu yẹn, n o sọ pe irọ ni. Mo kan mọ pe ki i ṣe oniṣekuṣe ọmọ, nitori ko jẹ ṣi ori rẹ silẹ, bi ọkunrin ti ko mọ ri ba si ti n bọ ni yoo fi aṣọ sara daadaa.

Mo tun bi i leere ọrọ, mo ni nigba to ti n ba a bọ lati ọjọ yii, ti ko ṣe kinni naa ri, ki lo waa de to jẹ oun ati Dele ko ti i mọra to oṣu meji to fi gba fun un. Ni ko ba dahun, lo ba n rẹrin-in. Mo ni ki lo n pa a lẹrin-in ninu ọrọ yii, o ni “Ṣebi nitori pe wọn lawọn fẹẹ fẹ mi ni, emi naa si fẹẹ fẹ wọn nitori yin! Mi o fẹẹ kuro lọdọ yin laelae ni, mo fẹ ki n wa lọdọ yin titi, nitori yin ni mo ṣe fẹẹ fẹ wọn!” Ni jẹbẹtẹ ba gbe ọmọ le mi lọwọ. Iyẹn ni pe ki i ṣe Dele lọmọ yii waa fẹ, emi lo waa fẹ. Haa, k’Ọlọrun ma maa fun wa ni daadaa ṣe o. Ọmọ yii si ya mi lẹnu.

Ẹni ba sọ pe awọn ọmọ isinyii ko gbọn, tọhun n tan ara rẹ ni, koda, wọn gbọn ju bi awa ṣe n ro lọ. Ọmọ yii ti wo iwaju, o ti wo ẹyin, o ti mọ ibi to fẹẹ sọ ẹru ẹ ka. Ṣugbọn inu mi dun pupọ pe ọmọ naa fọkan tan mi bayii lati le sọ pe oun fẹẹ wa lọdọ mi titi. Iyẹn lemi naa ṣe mura lati fi gbogbo ara mi ṣe eto to ba yẹ fun un. Mo ni kin ni Dele funra ẹ wi, o lo ni oun maa sa lọ ni, nitori iya oun o ni i gba, inu aa bi mi, oun o si tun lowo toun le fi sare ṣeyawo, wọn o si gbọdọ royun ninu oun nile awọn lai ṣeyawo, baba oun yoo binu rangbọndan ni.

Ni mo ba sọ fun un pe ka tiẹ too mọ eyi ti a fẹẹ ṣe, ko kọkọ lọọ pe ọdaran wa, ọdaran to fọmọ ọlọmọ loyun. Lo ba ni oun n bọ, afi bo ṣe lọ ṣuẹṣuẹ to pada de, to mu jagunlabi de. Aṣe Dele wa nitosi ṣọọbu mi nibẹ, to kako sẹgbẹẹ kan, ṣe ẹ ri i pe awọn ọmọ yii, nnkan ni wọn. Lo ba de lo ba n wolẹ, afi lẹẹkan naa to sare dọbalẹ, oun o mọ ni, oun o mọ pe ko mọ okunrin ri, oun ro pe irọ lo n pa foun ni. Ki n ma binu, oun o ni i ṣe bẹẹ mọ. Mo ni o o si ni i ṣe bẹẹ mọ loootọ, nitori ọran to o da yii, afi ko o tan an. Mo ni ki loun naa ro lọkan, ṣe ko fẹẹ fẹ Risikat ni.

Lo ba ni ni gbogbo aye oun, ko sẹni ti oun tun fẹran ju u lọ, oun si n ṣeleri fun mi, oun n bura fun mi pe oun ko ni i fiya jẹ ẹ laye, ko sẹni to maa gbọ ija awọn, oun fẹran ẹ pẹlu gbogbo ọkan oun ni. Ni mo ba ni ki iyẹn naa kunlẹ, mo kọkọ ṣadura fun wọn nibẹ, mo ni Ọlọrun to so wọn pọ ko ni i da wọn ru, Ọlọrun aa dẹ ṣegbeyawo wọn ni aṣedalẹ, wọn o ni i tuka lojiji. Mo ni ki wọn dide, ki wọn ma sọ fẹnikan pe oyun ti wa ninu Risi o, ki Risi tete lọ sile ko lọọ sọ pe awọn eeyan ọkọ oun fẹẹ waa mọ wọn, mo ni bi a ba ti lọ la oo ni ki wọn fun wa lọjọ igbeyawo kia.

Bi inawo ṣe bẹrẹ niyẹn o. Nigba ti mo sọ bi ọrọ ti jẹ fun Iyaale mi funra ẹ, niṣe lo bu sigbe. Ko tiẹ waa fẹẹ mọ ju ẹkun lọ bayii, ko maa sọ ara ẹ di dende ẹlẹkun sinu ile. Ọrẹ yin naa waa ba mi, mo mu nnkan ẹ fun un, Anti Sikira. Lo ba waa ba mi pe oun fẹẹ ṣe saraa ni Jimọ to n bọ, mo ni saraa kin ni, o ni ti ọkada to kọlu oun. Mo ni ṣe ọkada lo kọlu u abi awọn ọmọ alaṣọ l’Ojuwoye ni wọn da seria fun un nitori aṣọ awin to ra. Niṣe lọrẹ yin ṣi piri, ko le sọrọ, o n lọ lẹlẹẹlẹ ni. Oniranu, boya afọju bii ọkọ ẹ lo n pe mi. Ko ti i da nnkan kan mọ!

 

 

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.