Iya Biọla Ninu Anti Sikira at’Alaaji pẹlu Iya Dele, ẹni kan yoo ṣẹni kan leṣe

Spread the love

sẹẹ! Mo lo ma loyun, pe emi naa ri i nigba ti wọn fẹẹ gbe e wọ mọto, bo ṣe n ṣe e ko ma daa. Sẹki ni oun yoo mu ẹni kan waa ba mi ni ṣọọbu lọsan-an, pe nigba ti mo ba gbọ ọrọ lẹnu ẹ, nnkan Mo ṣẹṣẹ gba ọrọ awọn agbalagba ti wọn n sọ pe ile-ẹkọ ni ile aye yii, ati pe ti eeyan yoo fi ku, oluwarẹ yoo maa kọ ẹkọ naa lọ ni. Ti mo ba sọ fun yin pe n ko mọ ohun ti wọn n pe ni ile olorogun daadaa bii ti asiko yii, njẹ ẹ ko ni i sọ pe kin ni iya yii n wi yii. Bẹẹ bo ṣe ri ni mo wi fun yin yẹn. Ẹkọ ti mo ri kọ ni pe nigba ti kinni kan ba n ṣe eeyan, yoo ro pe toun lo pọ ju, afi nigba to ba ri ti ẹlomi-in ni yoo too mọ pe toun ko to nnkan kan. Emi ti mo n ro pe mo ri ija ile olorogun, n ko mọ pe n o ri nnkan kan tẹlẹ, asiko yii ni mo ṣẹṣẹ ri nnkan.

Anti Sikira ko wale fun odidi ọjọ mẹta, ṣe ọjọ mẹta tiẹ ni abi ọjọ mẹrin, ọjọ mẹrin ni! Nitori Jimọ ni wọn gbe e lọ yẹn, ko dẹ too pada de, ọjọ Mọnde ni, nirọlẹ. Amọ iyẹn kọ ni o ya mi lẹnu o. Laarin ọjọ mẹrin yẹn, bi Iya Dele ṣe n ṣe, bii ki obinrin yẹn ma pada wa sile mọ ni, igba naa ni mo mọ pe bo ba ri oogun ti Anti Sikira ko fi ni i wale mọ, o le ṣe e. N o ro pe o le paayan, ṣugbọn bo ba ri oogun ti obinrin yẹn yoo fi fi ọkọ wa silẹ, yoo ṣe e daadaa. Ohun ti mo si n beere lọwọ ara mi ni pe, ṣe o le to bẹẹ yẹn ni!

Laarin ọjọ mẹrin ti mo n wi yii, niṣe lo n se, to n sọ, gbogbo owo ẹ pata ni yoo ti fi se ounjẹ fun Alaaji tan ti yoo si ti fi ra sitaotu fun un. Iyẹn naa to jẹ ***ajẹru ni, ọdọ Iya Dele lo ku to n jokoo si, to jẹ ẹẹkọọkan ni wọn n lọọ wo ẹni ti ara rẹ ko ya, niṣe lo si da bii pe o tun fẹran Iya Dele ju ti tẹlẹ lọ. Ẹru n ba mi paapaa bi mo ṣe n sọrọ yii, nitori bi Iya Dele ba ri ọna ti obinrin yẹn yoo fi tun pada si ọsibitu, yoo ṣe e fun un. Ati igba to ti pada de ni ko ti tun si aaye rẹpẹtẹ fun Iya Dele lọdọ Alaaji, mo si mọ pe ọrọ naa yoo maa jo o lara gidi ni.

Ohun to jẹ ki n mọ pe gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ, Alaaji funra ẹ lo da a silẹ niyẹn. Oun gangan ni eku ẹda, oun lo n daja silẹ laarin awọn iyawo ẹ. Ọran kọ leeyan fi n fẹyawo meji, iwọ to o fẹyawo meji, iyawo mẹrin niwọ nikan ti fẹ bayii, iyẹn ti a o ba ka awọn ti wọn ti lọ mọ ọn. O waa fẹ awọn iyawo naa tan niyẹn, o o mo iwa a hu laarin wọn, ẹni to o ba ti n gba owo lọwọ ẹ lo mọ, tabi to ba ti le gbe kinni silẹ fun ẹ ko o maa ṣe e ni tọsan toru. Niṣe lo maa pa awọn to ku ti bii pe ko mọ wọn mọ, ṣe iru iyẹn daa.

O da mi loju pe bi ko ba jẹ owo to n ri gba lọwọ emi naa, ati pe emi o fẹran kinni ọhun, bi iba ṣe pa emi naa ti niyẹn, to maa ni oluwarẹ o lowo, tabi pe ko mọ ere e ṣe. Ẹkọ ti mo ṣẹṣẹ ko niyẹn, pe bi ọkunrin ba ṣe ṣe ile olorogun lo maa n ri, ati pe ija orogun ki i ṣe kekere, ohun to si n fa ija wọn pe oriṣiiriṣii. Bi Iya Dele ba ri ọna ti yoo fi ṣe Anti Sikira yẹn leṣe, yoo ti ṣe e leṣe ki gbogbo wa too mọ, yoo si ni o n di oun lọwọ ni, tabi ko ni Alaaji funra ẹ lo fa a. Iyẹn ti aṣiri ba tu ni o, bi aṣiri ko ba tu, yoo ṣe ohun to fẹẹ ṣe laṣegbe ni.

Iyẹn kọ lo tiẹ ba mi. Ara ohun ti a si n wi naa niyi. Bi emi ba fẹẹ le e lọ, ọwọ kan ni n oo le e lọ bayii. Ṣe ẹ mọ pe mo sọ fun yin pe ara fu mi, owo ti mo ko silẹ yẹn ko dun mi bii ẹtan ti wọn tan mi, nigba ti inu si bi mi ti mo pe Anti Sikira funra ẹ, n ba sọ fun Alaaji gan-an, ṣugbọn mo tun ro o wo ni. Akọkọ, Anti Sikira ti bẹ mi, o fẹẹ bẹ mi pa. Ẹẹkeji, ifẹ ti ru bo Alaaji loju bayii, bi o ba sọ fun un ko ni i gba, o le sọ pe a koriira ẹ la ṣe sọ bẹẹ, iyẹn lo jẹ ki n dakẹ funra mi, bo ba ya, ọrọ yoo sọ ara rẹ jade.

Ọjọ ti wọn ti de ọsibitu ti Alaaji ti pada wale lo ti sọ pe oyun lo bajẹ lara iyawo oun. Iyẹn lo si jẹ ki emi jade si iwadii temi, ọdọ Sẹki ni mo kọkọ lọ. Mo ṣalaye fun un pe baba ẹ ni oyun iyawo oun ti bajẹ o. Sẹki f’Ọlọrun ṣẹri, o ni ọmọbinrin yẹn ko loyun ti mo ba fẹẹ gbagbọ ki n gbagbọ nigba yẹn.

Lo ba mu ọrẹ ẹ kan wa nirọlẹ loootọ. Ọrẹ tiẹ gan-an kọ, ọrẹ ọrẹ rẹ ni. Awọn mẹta ṣa jọ wa, nigba ti wọn si bẹrẹ si i sọrọ, mo lanu silẹ ni. Ọrẹ wọn yẹn sọ pe ile kan naa loun ati aburo Anti Sikira jọ n gbe, awọn dẹ jọ n ṣe ọrẹ daadaa, Anti Sikira naa ko dẹ n wọn lọdọ awọn, ko le ṣe ko ma debẹ laarin ọjọ meji ko too di pe o lọ sile ọkọ yẹn, lati igba to si ti n fẹ Alaaji lo ti purọ oyun, ki aṣiri ma tu lo ṣe sọ pe oun loyun, o ni oun ati aburo ẹ jọ lọọ ba a lọsibitu to wa, nitori awọn mọ dokita yẹn, o maa n ṣẹyun fun gbogbo awọn ni.

O ni ki emi beere boya ọsibitu tiẹ lo lọ abi ti Alaaji, boya Alaaji lo si kowo fun dokita, o ni bo tiẹ jẹ Alaaji lo kowo fun dokita, Anti Sikira maa gba a pada, odu ni wọn fi ṣe. Mo beere lọwọ Alaaji loootọ, o ni Sikira loun ko owo fun to ko o fun dokita, nitori oun o si nibẹ nigba ti wọn n tẹẹsi ẹ lẹyin toyun ti bajẹ, ati pe Sikira naa lo mọ dokita ti awọn lọ sọdọ ẹ. Mo kan n poṣe mọ ọn ni ori ni, gbaju-ẹ ni wọn n ṣe fun baba yii, baba o dẹ mọ, ọkọ iyawo tuntun, niṣe lo tun ba iyawo ẹ daro pe oyun ẹ ti bajẹ.

Mo ti mọ pe n ko le gba owo mi lọwọ Alaaji, ni mo ba pe Anti Sikira. Mo ni ọjọ wo lo maa da owo mi pada fun mi, o ni oun n ṣa a jọ, awọn to jẹ oun ni gbese lẹyin oku ko ti i san an ni. Mo ni iyẹn kọ ni mo n sọ, owo to ko lọ si ọsibitu lọdọ dokita ọrẹ ẹ, to n purọ pe oyun bajẹ lara oun. Niṣe lo ṣe “Haa!”, o lanu ni. Mo ni ko wo o, ko si eyi to kan mi, oun ati ọkọ ẹ ni, bo ba wu u ko maa purọ gba owo lọwọ ẹ, mo ni mo mọ dokita to lọọ ba, mo si mọ pe ko loyun lati igba to ti n fẹ Alaaji to n purọ fun un, ṣugbọn ko kan mi, owo temi ni ko ba mi gbe.

Lo ba kunlẹ lo n bẹ mi, “Iya mi, Iya mi, bo mi laṣiiri, ma pa mi sita, mo maa da owo yẹn pada leni-in leni-in, ṣa fi bo mi laṣiiri!” Bi Anti Sikira ṣe wọle to lọọ ka ́ẹgb́ẹrun lọna aadọta Naira fun mi niyẹn, mo ti gbowo temi lọwọ ẹ o, ibi toun ati ọkọ ẹ ba ba ara wọn de, tabi ohun ti Iya Dele ba foju ẹ ri, wọn yoo jọ maa ran an.

 

 

 

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.