Iya Biọla Asiko ti to lati wayawo fun Dele, iṣẹ gbogbo wa ni

Spread the love

N o mọ boya ọmọ yii ko lori iyawo ni. Dele ni o, Dele ọmọ mi, ọmọ Iyaale mi. Gbogbo igba to ba ti mu ọmọbirin kan wa ti gbogbo wa ti n rọkẹkẹ igbeyawo, pati ni kinni naa yoo tun ja, ti wọn yoo tun sọ pe ko si igbeyawo kankan mọ. Ikan to fẹ nigba kan ti wọn jọ gbe fungba diẹ, Ọlọrun ni o ni ka lokuu eeyan lọrun, ọmọ naa iba ku mọ Dele lọwọ ni. Lati igba to si ti ba ọga ibiiṣẹ wọn sa lọ, afi bii ẹni pe o ṣe nnkan si Dele, to jẹ to ba mu eleyii pe oun loun fẹẹ fẹ, pabo ni. Emi o mọ pe iya ẹ naa n kiyesi i, afigba to waa ba mi ni ṣọọbu nijọ Alamiisi.

Bo ma ṣe n sọrọ yẹn fun mi lo maa n sunkun, o ni ara n fu oun, ko ma jẹ wọn ti fi nnkan kan Dele. Mo ni ko si ohun to jọ ọ, owo ti ko to nnkan lọwọ ọmọ naa ni ko jẹ ko ri ọmọ gidi, bi owo ba wa lọwọ ẹ, awọn obinrin yoo maa le e kaakiri ni. Mo ni ko jẹ ka foju silẹ, ko sohun to buru nibẹ bi awa naa ba ri ọmọ daadaa to ti ile rere wa ta a ba ni ko fẹ ọmọ wa, bi wọn ba ti ri ara wọn ti wọn si fẹran ara wọn, o ṣa ti pari naa niyẹn. Igba yẹn ni Iyaale mi too turaka diẹ, gbogbo bo si ti ṣere niwọnba naa to, ko mẹnuba ọrọ Anti Sikira.

Ohun to dun mọ mi ninu ju ninu ọrọ naa niyẹn, nitori mo ri i pe fun igba akọkọ, Iyaale mi ko ronu ọrọ ọkọ ati orogun, ọrọ ọmọ ẹ lo n ronu nipa ẹ. Mo ro pe oun naa ti ri i pe oun n dagba, ko si si ohun ti oun le ṣe si iwa Alaaji yii, ko si bi oun ṣe le ṣe e ti ko ni i fẹ iyawo, koda bi Anti Sikira lọ. Emi ti fi i dapaara nigba kan, mo ni Ọlọrun o ni i jẹ o fẹ ọmọ ọmọ ẹ nijọ kan, o ni nigba toju oun ko fọ. Ṣe ẹni to ba ti n fẹ ọmọde ti ko ju ọmọ ọmọ ẹ lọ, ki i ṣe ọmọ ọmọ ẹ naa lo n fẹ yẹn. Alailojuti kan ni baba yii, ṣugbọn ẹnu mi kọ ni yoo ti gbọ.

Nigba ti mo fi n sọ pe ki iyaale mi jẹ ka foju sita wa ọmọbinrin to daa fun Dele yẹn, ọmọ kan lo wa lọdọ mi ti ọkan mi lọ sọdọ ẹ. Biọla lorukọ ẹ, ṣugbọn Risikat gangan lorukọ suna ẹ, emi nikan ni mo dẹ maa n pe e bẹẹ. O ti to gọlọtọ gọlọtọ o, ileewe awọn tiṣa lo lọ, igba ti o riṣẹ tiṣa lo waa gbaṣẹ lọdọ mi nigba ti mo n wa akọwe ọja. Latigba to si ti wa lọdọ mi ni bii ọdun mẹta sẹyin, n o ba palapala kan lọwọ ẹ ri, ọmọ daadaa ni. Ohun ti mo fẹran ninu ọrọ ẹ ni pe bi mo ṣe n sọ yii, ibale ṣi wa lara ẹ. Ṣe ẹ mọ pe iru ọmọ bẹẹ ṣọwọn lasiko yii.

Ohun to jẹ ki n mọ ni pe mo ri ọmọ kan to n waa wa laipẹ yii, lemọlemọ ọmọ naa si pọ, ṣugbọn mo mọ ọn laduugbo tẹlẹ, awọn ọmọ ajagungbalẹ ni, ajagungbalẹ ni baba ẹ. Baba ẹ ki i ṣe ọmọ Eko o, ọmọ Abẹkuta bii tiwa naa ni, ṣugbọn o ti sọ ara ẹ di ọmọ onilẹ l’Oṣodi, a a ni baba awọn lo nilẹ lati Oṣodi titi wọ Mafoluku. Ẹrin lemi maa n fi i rin, nitori mo mọ ọn daadaa, nigba ti mo ba si pade ẹ to ba n ki mi, ma a ni, “Ọmọ Oṣodi to t’Ẹgba ile wa.” A a da mi lohun pe, “Iya mi niyẹn, ẹyin nikan lẹ mọtan bẹẹ.”

O ju mi lọ o, diẹ lawọn Alaaji fi ju u lọ, ṣugbọn Iya mi lo maa n pe mi, nitori itan ẹ ti mo mọ naa ni. Mo mọgba ti wọn bimọ yẹn, oju wa naa lo ṣe dagba nibẹ l’Oṣodi, ṣugbọn awọn Sẹki ki i ṣe ẹgbẹ ẹ, wọn ju u lọ daadaa. Mo mọgba ti wọn lo n lọ sileewe, afi bo ṣe pa ileewe ti ti ko lọ mọ, eyi ti a si gbọ nigba kan ni pe fọọ-wan-nain lo n ṣe, afi bo ṣe tun ya ti wọn ni o ti di ọmọ yahuu-yahuu. Ki n ṣa sọ pe mi o gbọ daadaa nipa ẹ ri, oun naa si mọ mi, o mọ pe mo mọ baba oun, iyẹn lo ṣe laya lati maa wa ṣọọbu mi waa wo Biọla.

Igba ti mo ri i pe gbọnmọgbọnmọ ẹ n pọ ni mo pe Biọla nijọ kan pe ki lo n wa lẹgbẹẹ ẹ, mo ni ṣe ko mọ iru ẹni to jẹ ni, abi ọkọ to n ṣe yahuu lo fẹẹ fẹ. Mo ni mo ri i lalẹ ọjọ kan ti wọn n gbe ara wọn kiri, ṣe o ti n ṣeṣekuṣe ni, bo ba fẹẹ lọkọ ṣe ko gbọdọ wọle ọkọ ko too maa lẹ mọ ọkunrin kiri ni. Iyẹn jẹ kọmọ yẹn waa ba mi, o ni oun ko le fẹ ẹ, o kan n yọ oun lẹnu ni, oun si ti ni ko ma wa oun wa mọ, ṣugbọn ko ni i gbọ. Igba naa lo sọ fun mi pe bi mo ṣe n wo oun yii o, ọkunrin ko ba oun sun ri, oun ko mọ bi wọn ṣe n ṣe e tabi bo ṣe n ri.

Mo sun mọ ọn, mo ni ṣe loootọ lo n sọ, o si mu kuraani kekere kan jade ninu baagi ẹ, o na an soke, o ni walai. Lati ọjọ yẹn ni mo ti n wo o ni awotunwo, ko si si ohun to le ṣe ti n ko ni i fori ji i. O tun waa loootọ, ko si ọjọ kan ti yoo wa ni ṣọọbu ti owo yoo sọnu ri, iyẹn lo ṣe jẹ oun lọga awọn to ku, bi n ko ba si fẹẹ lọ sibi kan, oun ni mo maa n ran lọ. Bo ba le fẹ Dele, tabi ti Dele ba le fẹ ẹ, inu mi yoo ti dun ju, nitori mo mọ pe aya rere ni yoo jẹ fun un. Ṣugbọn alakọwe lawọn n wa kiri, ọmọ yunifasiti, bi wọn si ṣe n sọyawo gidi nu niyẹn.

Mo mọ bi n o ṣe ṣeto naa ti yoo fi ṣee ṣe, ki Ọlọrun fun mi ṣe. Ọmọ daadaa ni Dele naa, ki i ko ọrọ mi danu, bo ba le gbọ ọrọ eleyii si mi lẹnu, yoo ṣe gbogbo idile wa lanfaani. Ọmọ to jẹ ki i ṣi ori ẹ silẹ, o si lọ si asalaatu ju ki lo da a silẹ lọ. Bẹẹ lo lẹwa, ko bora o, ṣugbọn niṣe lo pupa bii ọmọ Ibo, aṣọ to si maa n da bori ni mo ro pe awọn okunrin fi maa n sa fun un, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ti mu un balẹ ṣaa ni. Bi mo ti ranti ọrọ ẹ ni mo ti pe Dele, mo ni ko waa ri mi ni ṣọọbu, ọrọ wa ti mo fẹẹ ba a sọ. Ko sohun ti mo fẹẹ ba a sọ, mo kan fẹ ko ri Biọla funra ẹ ni.

Haa, mo fẹẹ maa lọ, wọn ni ọrẹ mi n pe mi nile wọn, Iyaale Sẹki, wọn lo loun o mọ bi Sẹki ṣe n ṣe. Ko ma jẹ ọmọ mi ti fẹẹ bimọ, ko si sọkọ ẹ nile, wọn lo sare lọ si Abuja. Hee, Ọlọrun ma ba mi sọ Sẹki nirọrun o, ki n gbohun iya, ki n gbọ tọmọ o. Ha, ẹ jẹ n tete maa lọ, n o tiẹ mọbi ti mo gbe baagi mi si. Ha, abi bawo lemi naa ṣe n ṣe bay

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.