Iya Biola Alaaji fẹẹ ṣe saraa nitori iyawo ẹ

Spread the love

Ṣe mo sọ, ko si ka ma mọ ohun to ṣẹlẹ. Aṣiri kan ko si laye yii to bo o, ọrọ to ba ti ṣẹlẹ to ṣoju ẹni meji, o ti di ti gbogbo aye niyẹn. Ṣe ẹ mọ pe mo sọ pe Sẹki maa mọ ohun to ṣẹlẹ si iyawo Alaaji, Anti Sikira, ti wọn lu ti oju ẹ ri bii ti Baba Keresi. Sẹki ni oun ko wadii kankan lọ sibi kan, ilẹ ko si ti i ṣu to fi gbọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ. Aburo Anti Sikira gan-an lo waa sọ fun un. Aṣọ ti mo n sọrọ ẹ nijọ yẹn, aṣọ ti mo ni Anti Sikira wọ wa sode Sẹki pẹlu ọkọ ẹ, ti Alaaji naa ko si agbada nla, ti wọn jọ jokoo ti wọn n jiisi, ọrọ aṣọ yẹn lo di wahala ti wọn fi luyawo wa o.

Wọn lawọn ọmọ to n ba kọsitọma to maa n raṣọ lọwọ ẹ taja lo lu u, wọn ni wọn lu u bajẹ ma ni o. Emi o kuku tiẹ mọgba to wale, wọn ni wọn ja aṣọ ẹ sihooho ni o, pe niṣe ni gbogbo ọmu ẹ n ṣere nita, pe ọtọ lawọn ti wọn fun un laṣọ to wọ wa sile. Aya mi tiẹ ti ja, mo ni ṣe ki i ṣe pe o jale. Sẹki ni ole kuku kọ. Mo ni o tiẹ daa, ti ki i baa ti i ṣe tole, eyi to ku, a oo maa fi mọra. Iyawo wa ni, ko sohun ta a le ṣe. Sẹki ni o ti jẹ kọsitọma ẹ yẹn lowo awọn aṣọ kan, iyẹn dẹ ti sọ pe to ba ti wa ki wọn ma ta aṣọ oun fun un mọ, afi to ba san awọn owo tilẹ.

Oun naa si ti gbọn, ki i gba ṣọọbu ọrẹ ẹ yẹn kọja. Igba ti Sẹki waa bimọ to fẹẹ ṣe fọrifọri fawa, lo fi lọ si ṣọọbu kọsitọma ẹ yẹn pada, o si ti ṣọ ọ pe iyẹn o si ni ṣọọbu, lo ba sọ fawọn ọmọ ẹ pe ọga wọn lo ni ki oun waa ko aṣọ ọpa mẹẹdogun, oun ṣẹṣẹ fun un lowo lọsẹ to kọja ni, o waa ba oun nile ọkọ oun. N lawọn yẹn ba n rẹrin-in si i, paapaa nigba to fun wọn lowo diẹ, bi wọn ṣe jẹ ko ko aṣọ lọ niyẹn, ko too di pe ọga wọn de to yari fun wọn pe oun o mọ ile ọkọ Sikira, ko si fun oun lowo, ki lo de ti wọn o fi pe oun lori aago. Lo ba le awọn ọmọ mejeeji jade pe afi ti wọn ba gba owo oun ni ki wọn too pada wa si ṣọọbu.

Loootọ lawọn yọn o si mọ ile wa, ko sẹni to le juwe fun wọn, bi wọn ṣe ṣe bii ọsẹ kan nile ti wọn o lọ si ṣọọbu niyẹn, ni wọn ba fi lọọ wa owo ya, ti wọn ko owo aṣọ fun ọga wọn, ko too di pe wọn bẹrẹ si i lọ si ṣọọbu pada. Ọlọrun lo waa mọ ohun ti Anti Sikira wa lọ si ọja Ojuwoye, itosi ṣọọbu awọn ọrẹ ẹ yii lo n lọ o, ṣugbọn ko gba iwaju ibẹ, ọna ẹyin patapata lo gba to fi ja sibẹ. Bo ṣe di pe wọn lẹni kan ri i to lọọ sọ fawọn ọmọ yẹn niyẹn, ko si si ọga wọn nitosi, ni wọn ba lọọ ja ba a.

Wọn beere owo yẹn lọwọ ẹ lo tun n ṣagidi, lo ba fọkan leti ninu wọn, o lo n roun fin. Bawọn yẹn ṣe gbe ti ọrẹ ọga ti sẹgbẹẹ kan niyẹn o, ni wọn ba ko lilu fun un taara, ohun to sọ ọ di oloju ku-n-gbu-ku-n-gbu niyẹn. O tiẹ waa to irọ buruku ti Iya Dele ni o n pa fun Alaaji, wọn lo sọ pe ọkada lo la oun mọlẹ. O daa bẹẹ. Ni baba yin ba tun bẹrẹ ere buruku to maa n sa kiri, koda, nibi ti ọrọ de yii, wọn lo fẹẹ ṣe saraa, wọn lo lọrọ iyawo oun ti ọkada kọlu ki i ṣe oju lasan, pe o lọwọ aye ninu. Wọn lo ni iku ti i ba paayan, to ba ṣi ni ni fila, ka dupẹ lo tọ.

Emi o kuku wobẹ, eyi ti mo tiẹ gbe dani pọ ju gbogbo iyẹn lọ. Ṣugbọn bi Alaaji ba le dẹnu owo kọ mi, nigba naa ni yoo gbọ winrinwinrin lẹnu mi. Mo tiẹ jẹrii ẹ, ko jẹ waa ba mi. Oun naa kuku ri i pe emi naa ṣẹṣẹ ṣenawo kan ni, inawo ti mi o ro tẹlẹ ni. Iya mi ni mo ri ti wọn ka jọ sẹgbẹẹ kan, inu wọn o dun rara. Mo tẹ wọn ninu titi, wọn o dahun, n o si fẹẹ sọ fun Sẹki, iyẹn yoo tun ko ọkan soke pẹlu ọmọ lọwọ, mo tiẹ ti ro o pe ko yẹ ka maa ko wahala tiwa lọọ ba a nile ọkọ ẹ, ko dojukọ ọkọ ẹ ni, kawa naa dojukọ ile wa.

Iyẹn ni mo ṣe tun pada lọọ ba iya mi, ti mo ni ki wọn ṣalaye fun mi, mo fẹẹ maa sunkun si wọn lọrun ni. Igba ti wọn ri i pe omi ti fẹẹ maa le loju mi ni wọn ba ni awọn lalaa kan ni. Mo ni iru ala wo, wọn ni awọn lalaa ri awọn ẹgbẹ awọn, wọn n na awọn, wọn lawọn o fawọn lounjẹ. Mo ni ṣe ẹlẹgbẹ ni wọn ni, abi bawo, pe emi o gbọ pe ki wọn sọrọ ẹlẹgbẹ ri o. Ootọ si ni, n o ro pe a sọrọ debi iru ẹ ri. Ẹgbẹ bawo! Ṣe Emere n daamu agbalagba ni. Wọn ni awọn fẹẹ ṣe saraa, mo ni ko buru, ṣugbọn ki wọn jẹ ki n pe awọn alaafaa ki wọn kọkọ ṣadura fun wọn.

Iya mi taku, wọn ni ekuru ati akara lawọn aa ṣe, tawọn aa pe awọn ẹlẹgbẹ ki wọn waa bawọn jo. Mo ni ko buru, ki wọn ma ṣeyẹn l’Ekoo ṣaa o, ki wọn lọọ ṣe e l’Abẹkuta, nitori bi wọn ba ṣeyẹn nile, awọn ara Eko yoo sọ ile wa di ile ẹlẹbọ ni. Ba a ṣe gbera Abẹkuta niyẹn, koda n o sọ fun Sẹki, n o si wi f’Alaaji naa, Iya mi tiẹ ni ki n ma wi fun un, wọn ni lọjọ to ti gbe Sikira wọle ni o ti dọdọ awọn mọ, tẹlẹ, o ṣi maa n wa ti yoo jokoo tawọn aa sọrọ sọrọ. Alaaji mọ ṣaa o, o da bii pe awọn ara Abẹkuta ni wọn sọ pe a wale, nitori nigba ta a de, o ki mi kuunawo, mo si lo ṣe e.

Se iyẹn ni yoo waa sọ fun mi pe iyawo oun fẹẹ ṣe saraa! Ka ma ri i. Koda bi wọn dana ẹ ti wọn sọ fun mi, n o ni i duro nile, ẹni to ba to bẹẹ ko waa beere lọwọ mi ninu wọn. Iya Dele lo pada waa sọ fun mi pe wọn ma ti ni wọn yoo ṣe e lọjọ Jimọ to n bọ yii, mo si ni Ọlọrun yoo ba wọn ṣe e, emi n ji lọ si ṣọọbu mi ni, mo n ji lọọ ṣe mitinni pẹlu awọn ileeṣẹ ti wọn ṣẹṣẹ ni awọn fẹ ki n wa ṣọọbu nla, bo si jẹ odidi ile, tabi sitọọ to tobi ti awọn le maa ja irẹsi si, pe emi lawọn fẹẹ fi ṣe aṣoju ti yoo maa ba awọn ta irẹsi awọn ni gbogbo Eko.

Ki i kuku ṣe pe mo wẹ awure, tabi mo ṣe kinni kan yatọ, keeyan kan maa mura si iṣẹ ọwọ ẹ naa ni, ko si maa ṣe daadaa. Awọn kan ti mo ti n ba ṣe lati ọjọ yii lọdọ ijọba ni wọn sọrọ mi fawọn araabi naa, awọn gomina kan pẹlu awọn oyinbo Tailandi ti wọn n ṣe irẹsi lọdọ wọn nilẹ Hausa ni, wọn ni awọn fẹẹ waa lu ọja Eko pa pẹlu irẹsi wọn. Wọn lawọn yoo fun mi lowo ki n fi gba ṣọọbu, mo ni ki wọn fi iyẹn silẹ, ki wọn jẹ ki n lo ile mi. Ilẹ mi kan to wa nitosi Ṣariti, lọna Maili Tuu, ni mo fẹẹ kọ sitọọ nla si, nibẹ la maa lo, odidi pulọọti kan ataabọ ni.

Nnkan ti mo ṣe fẹ ki Biọla maa bọ nile niyẹn, ki Ọlọrun ṣa ma jẹ ko sọ pe oun o ni i wa.

 

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.