Iya Biọla Aṣiri tu. Sẹki ti bimọ o!

Spread the love

Mo fẹẹ ṣenawo. Bẹẹ ni mo sọ fun yin, mo fẹẹ ṣe pati. Inawo ti mo fẹẹ ṣe yii, mi o ṣe iru ẹ ri, ṣugbọn mo maa ṣe e. Ọmọ mi ti bimọ, Sẹki ti bimọ, ọmọ ọkunrin lo bi. Inawo to yẹ ki n ṣe nigba iyawo ti ko ṣee ṣe, asiko ti mo fẹẹ ṣe e niyi. Mo ti gbadura si i, koda, mo ti lọ sọdọ awọn ti wọn riran si wa nijọsi pe ki n ma ṣe inawo alariwo nigba iyawo, wọn ni inawo eleyii, ko si ibi ti n ko le ṣe e de, pe ko si nnkan kan to maa ṣẹlẹ, wọn ni ọmọ ti Sẹki tiẹ bi yii, ọmọ alariwo ni, ko si kinni kan to maa ṣẹlẹ, bo ti wu ka pariwo le e lori to.

Ṣebi ẹyin naa mọ mi, pe n ko ki i ṣe ẹni to n pariwo le ara ẹ lori. Ṣugbọn idunnu naa pọ fun mi. Ohun ti Ọlọrun ran mi lọwọ ti mo fi ọwọ ara mi ṣe, to si waa yọri si daadaa bayii, ti oju ko ti mi, ko si ohun ti n ko ni i fi dupẹ. Mo ti ṣeto ohun ti mo fẹẹ fun wọn ni mọṣalaaṣi to jẹ nnkan idupẹ, inawo naa pọ diẹ nibẹ, ṣugbọn o tẹ mi lọrun, n oo na an. Mo ti ni ki wọn maa ba mi wa ọmọ onifuji to daa, n o fẹ awọn suẹgbẹ olorin, mo ti sọ bẹẹ fun wọn, mo fẹ olorin to gbadun, iye to ba fẹẹ gba kọ ni wahala mi, ko ṣa ti kọrin daadaa.

Gbogbo nnkan ti mo si n ṣe yii emi ati ọrẹ mi ni, Iya Tọmiwa, Iyaale Sẹki. Oun funra ẹ lo ti sọ fun mi pe oun fẹ ki n ṣe ikomọ Sẹki bo ba ṣe wu mi, nitori ọmọ ti inu oun dun si ni. O ni oun naa maa wa ni pati, oun maa wa nibi isọmọlorukọ, o ni ori ṣia loun maa wa, ki wọn ṣa ti maa ti oun kaakiri ibi yoowu ti wọn ba fẹẹ lọ. Oriṣii aṣọ meji ni emi ati Iya Tọmiwa maa wọ, ṣugbọn ọkan wa ti mi o ba wọn da si, iyẹn ni eyi ti oun ati Sẹki ati ọkọ wọn maa wọ. Bi mo ṣe n sọ gbogbo ẹ fun un, niṣe lo n rẹrin-in, inu ẹ dun.

Ko sẹni ti inu ẹ ko tiẹ dun lọdọ wa yẹn ni. Ọrọ naa bọ si iyanu, afi bii ẹni pe a ko ri ọmọ ri. Nigba ti wọn waa pe mi lọjọ Mọnde ti mo sare lọ yẹn, mo ba Sẹki nibi to ti n runju pọ, mo ni ki lo n ṣe e, o ni inu lo n run oun. Iya Tọmiwa naa ni oun ko mọ ohun to n ṣe e loun ṣe ni ki wọn waa pe mi wa. Mo ni ko jẹ ki a lọ si ọsibitu, o loun ko lọ, ki oun kọkọ wo o loju na, boya o maa fi oun silẹ. N ni mo ba jokoo ti i, emi ati Oluwa-pin-mi-lere, iyẹn ọmọ ẹ to kọkọ bi fun oniranu yẹn, ṣe wọn kuku ti sọ iyẹn di ọmọ temi.

Oun naa tiẹ pa mi lẹrin-in, o tun pa ọrẹ mi naa lẹrin-in, nigba to sọ fun mi pe, “Mọmi, mọmi, Anti mi n ke! Ki lo n ṣe Anti mi yii nao!” Sẹki lo n pe ni anti ẹ yẹn o, ko kuku mọ pe iya oun ni. Boya bo ba dagba to ba gbọn, aa mọ pe iya-iya oun ni mi, tabi kawọn ti wọn yoo pitan fun un tu iṣu desalẹ ikoko, ki wọn sọ fun un pe emi kọ ni iya-iya ẹ, iyawo iya-iya ẹ ni mi. Eyi to ṣa wu ki wọn sọ fun mi, mo mọ pe ko le mọ ẹlomi-in ni iya ẹ ju emi yii naa lọ, nitori emi ẹ la jọ n sun ti a jọ n ji, a jọ n lọ si ṣọọbu ni, koda, a jọ n lọ sileewe ẹ ni.

Bi Sẹki dẹ ṣe wi lo ri, nitori nigba to ṣe diẹ, inu yẹn ko run un mọ, bẹẹ ni ko si lo oogun si i, nitori mo taku pe ko le lo oogun kankan o, afi to ba de ọsibitu ti wọn sọ pe ko lo oogun. Ọlọrun ma jẹ ka ri i, bo ba lo oogun kan tiyẹn gbodi, tabi ti ki i ṣe iru oogun to yẹ ko lo nkọ, kin ni mo fẹẹ maa sọ. Ohun ti mo ro pe o ṣẹlẹ naa lo ṣẹlẹ, nitori nigba ti mo ti ri i yẹn ni mo ti mọ pe ọmọ n mu un silẹ ni. Gẹgẹ bi onka temi n ṣe, ko ti i yẹ ko bimọ, ṣugbọn n o fi tiyẹn ṣe, bo ba jẹ ọrọ naa le ju bẹẹ lọ ni, ọsibitu ni n ba tete gbe e lọ nigba ti ko sọkọ wọn nile.

Nigba ti ara ẹ ti balẹ, to si ti tun ṣere, mo ba wọn jokoo diẹ naa ni, ni mo ba mu ọmọ mi, a pada sile ni tiwa. Amọ ojoojumọ ni mo n debẹ, n ko fẹ ki nnkan kan ba mi lojiji mọ. Ọkọ wọn naa kuku tiẹ ti wa nile, ko si lọ sibi kan mọ, iyẹn naa fi mi lọkan balẹ. Alẹ ọjọ Jimọ lo pe mi, “Iya mi, ẹ maa bọ o!” Ko sọ ju bẹẹ lọ lori foonu. Foonu ti ku, mo tun pe e pada, foonu o lọ mọ. N o mọ bi mo ṣe dele wọn, boya mo sare ni boya mo rin ni, niṣe ni mo bẹ debẹ. Igba ti mo tun debẹ ni ọrẹ mi sọ pe wọn ti lọ si ọsibitu.

Bi mo ṣe sare pe ọmọ kan ko gbe mọto jade niyẹn, ko ṣa jẹ ka lọ. Taksi ni mo fẹẹ wọ tẹlẹ, ṣugbọn mo ranti pe ti mo ba gbe taksi debẹ, ti iyẹn ba ti pada, ti a ba tun nilo mọto, wahala lo maa jẹ. Emi to jẹ bi wọn ba ti gbe mi si mọto bayii, tọmọ ba ti n wa iwakuwa, n oo maa pariwo ni, n o wi kinni kan si gbogbo iwakuwa tọmọ yẹn n wa, ko ṣa ti gbe mi dọsibitu lo wa lọkan mi. Bi ọmọ ṣe n wọnu ọsibitu bayii, ọkọ ẹ ni mo kọkọ pade to sare waa so mọ mi, nigba ti mo dẹ ti rẹrin-in loju ẹ, ati ayọ to han loju ẹ, mo ti mọ pe Sẹki ti bimọ.

“Bawo lẹ ṣe ti yaa sare gbọ! Ṣe ẹ ti dele ni!” Ibeere ti Misita Akinfẹnwa n bi mi niyẹn. Ni mo ba ni Sẹki funra ẹ lo pe mi, bo si ṣe pe mi lo pa foonu, ni n o ba gbọ nnkan kan mọ. Ọkọ Sẹki ni, “Ọlọrun ma jẹ kọmọ yin yii ṣe yin leṣe. Ṣebi nigba ti wọn ni wọn fẹẹ mu un lọ si ibi to ti maa bimọ ni, lo ba ni aya oun n ja, mo si ni ko si wahala kan fun un, yoo jade nibẹ laipẹ. Emi o mọ pe o pe yin o!” Mo ni gbogbo iyẹn, iregbe ni, nibo ọmọ mi wa, o lo wa ninu ọsibitu lori bẹẹdi nibẹ. O ni ko lo iṣẹju marun-un to ti bimọ. Ṣe ẹ ri i pe temi tọpẹ.

Mo kan n wo Sẹki nigba ti mo d’ọdọ ẹ ni. Mo n ro o pe awọn ọmọ wa yii o ṣee nunu fun, ẹri wọn ṣoro o jẹ. Ibẹrẹ oṣu kẹta ni Akinfẹnwa wa sọdọ mi, ti mo bẹ Sẹki titi ko too gba lati lọ sile ẹ, pẹlu ọmọ ẹ to bi yii, o fihan pe bi o ba jẹ ọjọ to de ọdọ ẹ niyẹn ti ba a sun, aa jẹ ọjọ keji, o si n purọ femi pe ko si nnkan kan laarin oun ati Kunle. Nigba ti mo bi i pe ta lo n jẹ Kunle to ni Akinfẹnwa ni, mo ni o ti yaa sare mọ oruko ẹ, o taku pe ko ti i si kinni kan laarin awọn. Sẹki mọ pe mo n ronu, lo ba ni, “Iya mi, ki lẹ n ro?” Mo ni, “Aṣiri to tu yii naa ni o!”

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.