Iwọsi yii ṣee n pọ ju fun Yoruba, ibi ti wọn ba wa de ree o

Spread the love

Alaigbọran ni wa. Tabi ki n sọ pe alaigbọran ti pọ ju ninu iran awa Yoruba. A fẹran abamọ pupọ. Bi ẹnikan ba roye kan, tabi to ba sọye lori ohun kan, tabi to ba ni iriri kan to fi tọ awa to ku sọna, kaka ka gbọ, yẹyẹ la oo fi i ṣe, tabi ka maa bu u, awọn mi-in aa tiẹ mura lati ṣe e leṣe ti wọn ba le sun mọ ọn. Nigba ti ọrọ naa ba waa ṣẹlẹ, to ba jẹ bi ẹni naa ti wi lo pada ja si, awọn yii kan naa ni yoo dide, wọn yoo ni awọn ko mọ ni, abamọ yoo si dun lẹnu wọn bii nnkan. Ko dun mọ mi ninu lati maa wi pe ọrọ ti mo wi ṣẹ tabi ko ṣẹ, ṣugbọn nigba to waa ṣe pe ọpọ awọn to wa nilẹ yii, aletilapa ni wọn nkọ! Ki a too dibo ọdun 2015, mo pariwo to, mo pariwo gan-an, tawọn kan si mu mi lọtaa, tawọn mi-in n ṣepe le ara wọn lori ti wọn ro pe emi ni. Ṣugbọn bi a ti dibo tan lawọn ohun ti mo ri ti mo fi sọrọ bẹrẹ si i ṣẹ, gbogbo wa si foju ri i.

Nigba naa lawọn eeyan bẹrẹ si i ke abamọ, ‘baba, a o mọ ni, baba, ọrọ ti ẹ wi lo ti n ṣẹ yii o, baba, ẹ ma binu.’ Ṣugbọn anfaani wo lo wa ninu abamọ? Oore kin ni abamọ yoo ṣe fẹni to ba ṣe e? Ṣugbọn oore kan wa nibẹ o, oore naa ni ka lo o lati fi gbaradi fọjọ iwaju, ka ba ara wa sọrọ pe ti iru nnkan yii ba tun ṣẹlẹ lọjọ mi-in, a oo gbọran sira wa lẹnu. Ṣugbọn ki lo tun ṣẹlẹ nigba ti ibo ọdun yii de? Awọn mi-in pe mi ni were danwo, awọn mi-in ni ki lo de ti mo koriira Fulani to bẹẹ, awọn mi-in si sọ pe Buhari ni mo koriira. Loju awọn dindinrin mi-in, wọn n gbeja APC, ẹgbẹ oṣelu wọn niyẹn o, wọn si ti ri emi gẹgẹ bii ọmọ PDP. N ko mọ ibi ti wọn ti pade ti wọn ni wọn gbọ orukọ mi ninu ẹgbẹ kankan, tabi ti mo ba n ṣe oṣelu, ko yẹ ki wọn ti fi emi naa si ipo nla ni. Ti pe n ko mọwe to ni tabi ti pe n ko dagba to, nigba ti wọn n mu baba ọdun marundinlaaadọrun-un (85) ninu wa lati gbe ile ijọba le wọn lọwọ.

Gbogbo ariwo ti mo pa pe n ki i ṣe oloṣelu, ohun ti mo mọ nipa Fulani, iriri ohun ti Buhari ti ṣe lẹyin ọdun mẹrin yii la fi n sọrọ, ko sẹni to ba mi gbọ ọ, aigbọran to sọ awọn ọmọ Israẹli di alarinkiri, ti gbogbo awọn iran igba naa si parẹ sinu aginju, ko kuro lara ọpọ awọn ọmọ Yoruba tiwa.  O tẹ wa lọrun ka fẹran araata, ka tẹle awọn ti wọn n ko wa lọ si oko ẹru, ju ka gbọran si ẹni tiwa lẹnu lọ. Oun lo delẹ yii o, ariwo ti tun bẹrẹ, ‘baba, ẹ ma binu, baba, nibo la fẹẹ gba, baba, ohun ti a oo ṣe ni ki ẹ sọ fun wa.’ Kin ni mo fẹẹ sọ fun yin, kin ni mo fẹẹ ṣe, ṣe ki n ni ki Buhari ma ṣejọba lẹẹkeji ni. Ṣebi ẹ ti ti oje bọ olooṣa lọwọ, ta lo to bẹẹ lati bọ ọ ninu yin. Mo sọrọ titi debii pe mo ni ọdun mẹrin ti Buhari yoo fi ṣejọba mi-in yoo le bi ẹ ba dibo fun un, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ lawọn eeyan kan ti bẹrẹ si i ṣepe, wọn ni emi ni yoo le mọ, nitori emi ni mo n ri irikurii.

Gbogbo awọn ti wọn n sọ isọkusọ yii nigba naa, gbogbo awọn ti wọn lọ si ori ẹrọ ayelujara, lori facebook, ati awọn to ku, bi ẹ ba wa wọn bayii, ẹ ko ni i gburoo wọn mọ. Wọn ko si lori ẹrọ ayelujara, bẹẹ ni wọn ko ni i da si ọrọ to wa nilẹ yii mọ. Ṣugbọn ki wọn too lọ yii, wọn ti ba nnkan jẹ, wọn ti da ọrọ ru debii pe Yoruba ko i ti i mọ ibi ti yoo gba, tabi ọna ti yoo fi ṣe e, ti a oo fi bọ lọwọ okun ti a ki bọ ara wa lọrun yii. Awọn ti ẹ n tẹle, ti wọn n purọ fun yin, ti wọn n pairwo eke, awọn ni wọn ba wa debi ti a wa yii. Bẹẹ ni wọn ti ha sọwọ awọn Fulani, awọn ni wọn kọkọ ha sibẹ ki wọn too fa ẹyin naa lọ. Bi ẹ ba ti ri ẹnikan to loun gbọn titi, tabi to ni oun gọ titi, to waa kọ idi sita, to n tọ sinu ile, ẹyin ko ti mọ pe alakooba ati abatẹnijẹ ẹda ni iru ẹni bẹẹ, ṣebi niṣe lo yẹ kẹ ẹ jinna si i. Ṣugbọn ẹyin o jẹ jinna si wọn, awọn lọlọrun yin.

Nigba ti Ẹgbọn Ṣẹgun sọrọ lọsẹ to lọ lọhun-un, ti gbogbo ilu n mi titi, ẹrin lemi n rin. Mo n rẹrin-in nitori pe yoo to ọdun mẹta ti mo ti sọ ọrọ naa sẹyin. O pẹ ti mo ti sọ fun yin pe awọn Fulani agbaye n wa ibi ti wọn yoo fi ṣe ibugbe ati ikorita fun gbogbo wọn, wọn si ti ri i pe Naijiria lo ṣee lo, nitori ainiṣọkan wọn, ati nitori pe ọmọ Fulani lolori ijọba naa, o si fẹran awọn. Ki Buhari too gbajọba ni wọn ti mọ ọn, nitori gbogbo ohun to ni lo fi n ja fun Fulani, to fi n gbeja awọn onimaalu, oun lo si kọkọ sọ pe ki ijọba Jonathan fi awọn Boko Haram silẹ, inu lo n bi wọn ti wọn fi n ṣe ohun ti wọn n ṣe. Oun lo sọ fun ijọba Ọbasanjọ pe awọn o ni i sinmi afi igba ti gbogbo Naijiria ba bẹrẹ si i lo Sharia gẹgẹ bii ofin wa.  Gbogbo awọn ọrọ to n sọ yii lawọn Fulani agbaye n kọ silẹ, nitori ẹ lo jẹ bo ṣe gbajọba ni wọn ti bẹrẹ si i ya wa si Naijiria, ti wọn n huwa ibajẹ, ti Buhari ko lẹnu lati sọ pe ohun ti wọn ṣe ko dara.

Mo sọ fun yin nigba naa pe ogun Boko Haram ti kuro ni bi awọn eeyan ti n pe e, mo ni o ti di nnkan agbaye. Ṣugbọn irọ lawọn Buhari n pa, eke ni wọn n ṣe, wọn ni awọn ibi ti awọn Fulani n gbe ni wọn ti n ba wọn ja, ki i ṣe awọn janduku tabi afẹmiṣofo lo wọ orilẹ-ede wa. Bẹẹ, ikede ẹyọ kan ṣoṣo bayii lo wulo nigba naa, bo ba jẹ Buhari ṣe e ni, a ko ni i wa bi a ti wa yii. Bo ba kede lọwọ kan pe ki awọn ṣọja maa yinbọn pa Fulani to ba gbebọn dani, tabi awọn to ba paayan niluu kan, gẹgẹ bi Ẹgbọn Ṣẹgun ti ṣe laye OPC, to paṣẹ ki wọn maa yinbọn pa wọn nibikibi ti wọn ba ti ri wọn, awọn Fulani yii yoo sa lọ bo ba jẹ ohun ti Buhari ṣe niyẹn. Awọn Fulani ti ẹ ri yẹn, ogboju ni wọn ni, wọn ko laya, ojo ni wọn, bi wọn ba yinbọn pa meji mẹta ninu wọn, awọn to ku yoo sa lọ bamu ni. Amọ Buhari ko ṣe bẹẹ, oun n fọwọ ra wọn lori ni, loju tirẹ, awọn ọmọọya oun lo de, awọn ko si gbọdọ fiya jẹ wọn, awọn gbọdọ gba ilẹ awọn ọmọ Naijiria fun wọn ni.

Lati fihan pe oun fẹran wọn daadaa, Buhari fi ọgbọn ẹwẹ sọ pe awọn fẹẹ fi reluwee so orilẹ-ede Naijiria pọ mọ Katsina, ki awọn le maa ra epo ni Nijee. Ọrọ rirun pata lo jọ loju gbogbo ẹni to gbọ ọ, nitori Nijee ko lepo ti yoo ta fun Naijiria, awọn to ṣe ofin naa fẹẹ maa fi ọgbọn ko epo wa fun wọn lorilẹ-ede naa ni. Mo sọ nigba naa pe ko daa, mo si ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ bi epo ti wọn n wa ni Nijee lodidi ọdun kan ko ṣe to eyi ti Naijiria yoo wa laarin oṣu kan. Ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ lawọn ọmọ Yoruba kan ti mu mi bu, ẹnikan tilẹ sọ pe o yẹ ki awọn DSS waa gbe mi ni, nitori mo n tu aṣiri ijọba, ọrọ ti mo si n sọ yẹn, ọrọ to le da ilu ru ni. Ṣugbọn pẹlu iru ifẹ ti Buhari n fi han awọn Fulani yii, iyẹn ni wọn ṣe bẹrẹ si i wọle si i, ti awọn afẹmiṣofo si ba Katsina wọle, nibi ti Buhari ti loun fẹẹ fi reluwee so wa pọ. Wọn ti wọle bayii, wọn ko ṣee le jade mọ.

Ọrọ ti mo sọ nigba naa ni Ẹgbọn Ṣẹgun pada sọ yii, ti Ẹgbọn Wọle naa si ranṣẹ si Buhari pe ko gbọ ootọ ọrọ lẹnu aarẹ ilẹ wa tẹlẹ yii. Ṣugbọn Yoruba lọrọ naa yoo kan gbọngbọn ju, nitori ẹya tiwa ati iṣẹda tiwa ki i ṣe onijangbọn, a ki i ṣe onijagidijagan. Iyẹn ni wọn ṣe n ya wọ ilẹ Yoruba yii, ti wọn n ji wa gbe. Mo fẹẹ sọ fun yin, ọpọ nnkan aṣiri lo wa, ọpọ awọn olowo ati ọlọla ilu ni wọn n ji gbe ti wọn ki i lee sọ sita, tabi ki wọn sọ ohun ti oju wọn ri. Bi wọn mu ọlọla kan pẹlu iyawo rẹ, tabi awọn ọmọbinrin rẹ, loju rẹ ni awọn Fulani yoo ṣe maa ṣe wọn ṣikaṣika, ti wọn yoo maa fi ipa ba wọn lo pọ, ti ko si ni i le ṣe nnkan kan si i. Iru ẹgbin, ifiniwọlẹ ati ibanininujẹ wo lo tun ju eyi lo laye. Ṣugbọn ohun ti wọn n ṣe niyẹn, wọn si ti yi ilẹ Yoruba po. Loootọ lawọn agbaagba ilẹ Yoruba ti dide, ti wọn n kiri lati ri i pe Fulani ko ko wa lẹru, ṣugbọn njẹ awọn ti wọn n tori ẹ dide yii mọ ọn fun wọn bi.

Wọn ko mọ ọn fun awọn baba yii. Ṣebi awọn ti wọn n bu tẹlẹ niyẹn, ti wọn ni wọn o ki i ṣe aṣaaju Yoruba, aṣaaju PDP ni wọn, wọn ti gbowo lọwọ PDP ni. Ṣugbọn lonii yii, bi ara ti n ni Yoruba to yii, awọn ti wọn ko wa debi ko tori ẹ pada lẹyin Fulani, koda, niṣe lọrẹ wọn n le si i, ti wọn n fi orukọ Yoruba jẹun ni tiwọn. Bẹẹ, mo fi Ọlọrun bura, ẹtẹ ati abuku ni wọn yoo ba pade nibẹ, nigba ti aburu ati inira tiwọn ba de, yoo ju eyi to n ṣẹlẹ si apapọ Yoruba bayii lọ. Oju wa yii naa ni yoo ṣe. Ṣugbọn ki gbogbo ọmọ Yoruba gbọran, ki ẹ ṣe ohun ti awọn agba ba ni ki ẹ ṣe ni gbogbo akoko yii, ẹ fọwọsowọpọ pẹlu wa, ki Yoruba ma ko sinu oko ẹru Fulani awọn ajinigbe o.

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.