Iwọde isinku awọn Alufaa Benue waye lana

Spread the love

Lana ni isinku awọn alufaa ijọ Katoliki meji, Joseph Gor ati Felix Tyolaha pẹlu awọn ọmọ ijọ mẹtadinlogun Ijọ Ignatius to wa ni Ayar, eyi tawọn Fulani darandaran pa ni Ifonna fonsu lagbegbe Mbalon,nijọba ibilẹ Ila Oorun Gwer nipinlẹ Benue loṣu to kọja. Lẹyin isin ikẹyin ni wọn yoo sin awọn oloogbe naa si ile igbadura mimọ ti Susugh Maria to wa ni Ayati, Ikpayongo.

 

Awon aṣoju Poopu pẹlu aadọta Bisọọbu ati ọpọlọpọ awọn alufaa jakejadedo Naijiria ati awọn orilẹ ede yooku ni yoo ṣe isin ikẹyin fawọn oloogbe naa.

 

Bi isin ikẹyin naa ṣe n lọ nipinlẹ Benue ni yoo tun waye kaakiri ijọ Katoliki to wa lorilẹ ede yii. Pupọ ninu awọn Biṣọọbu ni ẹlẹkunjẹkun ni wọn ti tẹ atẹjade pẹlu akọle pe “O to gẹẹ, ifẹmiṣofo yii gbọdọ dawọ duro”, pe ki awọn eeyan tu jade ninu aṣọ ẹgbẹ wọn lati kopa ninu iwọde wọọrọ naa.

 

Ni oluulu ilẹ wa to wa ni Abuja, isin ikẹyin yoo waye ni ipagọ awọn ọmọ lẹyin Kristi (National Christian Centre), nibi ti wọn yoo ti wọde lọ si ileeṣẹ ijọba apapọ (3-Arm Zone Central) ti o wa ni Garki.

 

Ni ti Ẹkun Eko, lẹyin isin ikẹyin ni ile ijọsin St. Leo to wa ni Ikẹja, iwọde yoo bẹrẹ lati ibẹ lọ si ileeṣẹ ijọba to wa ni Alausa. Ni ẸKun ti Ibadan, iwọde naa yoo bẹrẹ ni ileewe ẹkọṣẹ awọn alufaa to wa ni Bodija, wọn yoo si wọde lọ sileeṣẹ ijọba to wa ni Agodi.

 

Gbogbo awọn Biṣọọbu ijọ Katoliki lorilẹ ede yii lo fọwọ si iwọde wọrọwọ naa pe o to asiko ti ijọba gbọdọ kọwọ awọn afẹmi ṣofo bọṣọ. Iwọde awọn ọmọ ijo naa da lori ifẹhonu han fun ipadanu tawọn Fulani darandaran n pa awọn ọmọ orilẹ ede yii ti ijọba apapọ ko si ṣe bi ẹni pe ọrọ naa kan won rara. Ṣe lo dabi ẹni pe ẹmi awọn araalu ko ja mọ nkankan ninu ọkan wọn.

 

Isinku awon oloogbe naa ko ṣadede bọ si oni, ọjọ kejilelogun oṣu Karunun. Awọn Biṣọọbu Ijọ Aguda naa mọ ọn mọ fi si ayajọ ọjọ oni ni.

 

Bi a ko ba gbagbe, oni gan an lo pe ọdun kan ti awon aṣofin ipinlẹ Benue fi ootẹ lu u pe ẹnikẹni ko gbọdọ da ẹran tabi maalu kiri ni gbangba mọ. Lati igba naa lawọn Fulani darandaran afẹmi ṣofo naa ti wa tubọ mura si pipa awọn araalu naa.

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.