Iwe-ẹri Dapọ Abiọdun, ile-ẹjọ giga loun yoo dajọ nidibo ku ọla

Spread the love

Ile-ẹjọ giga to n jokoo lagbegbe Apo, l’Abuja, ti ni bi idibo gomina ọjọ kẹsan-an yii ba ku ọla loun yoo dajọ aini iwe-ẹri yunifasiti  ti ẹnikan pe ta ko Ọmọọba Dapọ Abiọdun, eyi ti wọn fi ni ko lẹtọọ lati dupo gomina ipinlẹ Ogun.

Ọmọ ẹgbẹ APC kan, Ọgbẹni Abdulrafiu Baruwa, lo pe ẹjọ tako Dapọ Abiọdun lọjọ kẹtala, oṣu kejila, ọdun 2018, nibi to ti sọ pe ondije dupo gomina yii kuna lati fi iwe-ẹri yunifasiti to ti kawe jade silẹ fun ajọ INEC.

 Wọn ni iwe-ẹri oniwee mẹwaa pere ni Dapọ Abiọdun ri mu kalẹ, bẹẹ, o ti figba kan sọ pe oun ni iwe-ẹri fasiti ri, nigba to n dije dupo sẹnetọ.

Agbẹnusọ olupẹjọ, Amofin Oluwọle Aladedoye, sọ pe nitori Dapọ Abiọdun ko sinru ilu, ko si ni iwe-ẹri agunbanirọ ni ko ṣe fi iwe-ẹri yunifasiti rẹ silẹ.

Lọọya yii ṣalaye pe ondije dupo gomina yii mọ pe ai ni iwe-ẹri agunbanirọ ko le jẹ ki ohun toun n wa tẹ oun lọwọ, o si le jẹ ki wọn fagile erongba oun lati di gomina ni ko ṣe fi iwe-ẹri ileewe giga to lọ silẹ fun INEC ati ẹgbẹ APC to ti n dije. Eyi si lodi si abala kẹtalelọgbọn, ẹka kẹrin ati ikarun-un ofin eto idibo ilẹ wa.

Koda, Dapọ Abiọdun nikan kọ ni Baruwa to pe ẹjọ yii gbe lọ si kootu, bakan naa lo fẹsun kan APC ati INEC pe wọn ko tẹle ofin. Ṣugbọn lọọya to n ṣoju Dapọ Abiọdun ninu ẹjọ yii, Amofin agba Kẹhinde Ogunwumiju, tako kootu to  n gbọ ẹjọ naa, o ni wọn ko lagbara lati gbọ ẹjọ yii nile -ẹjọ giga naa.

Adajọ Olukayọde Adeniyi to gbọ ẹjọ naa sọ pe ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ, oṣu yii, ti idibo gomina yoo ku ọla ni idajọ yoo waye, o ni to ba si le ṣee ṣe ko too digba naa, oun yoo da a.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.