Iwadii bẹrẹ lori ọga ileewe ati tiṣa ti wọn so akẹkọọ mọgi l’Ayetoro

Spread the love

Ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, to si n fọwọ ofin mu awọn afurasi ni ọga ileewe kan, Ọgbẹni Afọlayan Joseph, atawọn tiṣa rẹ meji wa bayii nipinlẹ Ogun. Ohun to gbe wọn debẹ ni ti awọn akẹkọọ meji ti wọn de mọgi, ti wọn si n na wọn ni koboko nitori pe wọn pẹ ẹ dele iwe lọsẹ to kọja.

Ọjọru, Wẹsidee, to kọja yii niṣẹlẹ naa waye nileewe Metorite Standard School, Ayetoro, nipinlẹ Ogun, eyi ti Ọgbẹni Afọlayan n dari. ALAROYE gbọ pe awọn akẹkọọ meji naa, ọkunrin ati obinrin kan, pẹẹ de ileewe laaarọ ọjọ naa ni. Igba ti ọga ileewe si fẹẹ ba wọn wi, niṣe loun atawọn tiṣa meji so apa awọn ọmọ naa mọgi bii igba ti wọn kan wọn mọ agbelebu.

Ọlọpaa kan, Livinus lo ri awọn akẹkọọ yii nita gbangba ti wọn so wọn si, ti ọga ileewe atawọn tiṣa rẹ si n lu wọn ni koboko mọbẹ, to si jẹ pe iṣẹlẹ naa ti n da sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ silẹ nitori awọn ero to n woran.

Gẹgẹ bi alaye agbofinro yii, o loun wọ inu ileewe naa lati beere ohun tawọn ọmọde naa ṣe to fi jẹ dandan ni ki wọn so wọn mọgi pẹlu okun bẹẹ. Awọn to n fiya jẹ wọn naa si sọ pe wọn pẹẹ de ileewe ni, awọn ko si ni i tu wọn silẹ, ibi ti wọn yoo wa niyẹn ti wọn yoo maa jẹrora.

Gbogbo igbiyanju ọlọpaa yii lati gba awọn akẹkọọ naa silẹ ko bọ si i rara, o si tun fẹẹ fọwọ ofin mu awọn eeyan naa, wọn ko tun gba, nitori gẹgẹ bo ṣe wi, niṣe ni Afọlayan atawọn tiṣa meji naa mu oun paapaa lu lori ọrọ yii, ti wọn tun lu ọlọpaa keji tawọn jọ n lọ sibi iṣẹ lọjọ naa.

Eyi lo mu ọlọpaa Livinus pe DPO teṣan Itele, l’Ayetoro, iyẹn lo si fi awọn ọlọpaa ṣọwọ sileewe Metorite, ti wọn fi ṣẹṣẹ ko gbogbo wọn lọ si teṣan yii.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyemi, sọ pe iwa ti awọn eeyan naa hu ti kuro ni ibawi lasan, o ti tapa sofin ilẹ wa.

O ni ijọniloju gbaa ni, iyẹn lawọn ṣe ti ko awọn eeyan naa lọ sibi to yẹ wọn, nitori ijọba ko ni i faaye gba ka tun maa so eeyan mọgi nibi ti aye laju de loni-in, afi kawọn arufin naa jiya labẹ ofin.

Pix: Awọn akẹkọọ ti wọn so mọgi

(125)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.