Itọju oṣu meje bẹrẹ fun Martins lẹyin ifarapa

Spread the love

Olokiki ọmọ ilẹ Naijiria to n gba bọọlu ni Shanghai Shenhua, ilẹ China, Ọbafẹmi Martins, ti kọja silẹ United Kingdom lẹyin ifarapa to ni lọsẹ to kọja. Kashima Antlers ni kilọọbu Martins koju lasiko to farapa nitosi orunkun.
Ifarapa Martins yii lagbara diẹ, nitori ko le da rin, nnkan bii oṣu meje ni kilọọbu rẹ si sọ pe yoo lo ko too le pada sori papa. Eyi tumọ si pe agbabọọlu ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ko le kopa fun Naijiria ninu idije agbaye to n bọ yii gẹgẹ bii ero Kooṣi Eagles, Gernot Rohr, tẹlẹ.
Agbabọọlu ti ko ṣe e ma ni ni Martins jẹ fun Shanghai Shenhua, wọn si fi eyi han ninu ọrọ iwuri ti wọn fi ranṣẹ si i.
Bọọlu mẹrin ni Martins ti gba wọle ni saa yii ninu ifẹsẹwọnsẹ meje nilẹ China.
Ọdun 1999 ni Martin ti n ṣe bẹbẹ fawọn kilọọbu nilẹ Naijiria, Italy, England, Germany, Russia, Spain ati Amẹrika ko too balẹ si China.
Laarin ọdun 2004 si 2015 lo gba bọọlu fun Naijiria.

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.