Itan bi Ladoke Akintọla ṣe di Aarẹ-Ọna-Kakanfo ilẹ Yoruba

Spread the love

Ọrọ awọn oloṣelu, too too too ni. Paapaa ni ilẹ Yoruba yii, ọrọ awọn oloṣelu too too ni. Ni 1964, ọpọlọpọ eeyan ko ranti oye Aarẹ Ọna Kakanfo mọ rara. Ẹlomiiran ko tilẹ gbọ ọ ri, wọn o si mọ ohun ti wọn n pe bẹẹ. Bẹẹ agbalagba ni wọn, awọn mi-in ninu wọn si ti le ni ọmọ adọrin (70) ọdun daadaa. Ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, nitori ẹni to jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo yii gbẹyin ko too di 1964 yii, Mọmọdu Ọbadoke Latoosa, ẹni ti gbogbo aye pada mọ si Aarẹ Latoosa ni. Ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun 1871, lo di aarẹ naa, oun si ni Aarẹ Ọna Kakanfo to jẹ gbẹyin, nitori lasiko rẹ ni Ogun Ekiti Parapọ ti wọn tun n pe ni Ogun Kiriji waye, ogun naa ko si pari titi ti awọn oyinbo fi de. Awọn oyinbo funra wọn ni wọn pari ogun naa, ti wọn si ṣofin pe ko gbọdọ tun si ija tabi ogun ẹlẹyamẹya laarin awọn Yoruba, tabi ni ibi gbogbo ni Naijiria mọ.

Nidii eyi, nigba to ṣe pe o din diẹ ni ọgọrun-un ọdun ti wọn ti jẹ Aare Ọna Kakanfo yii gbẹyin, ọpọ eeyan ni ko ranti mọ, afi awọn ti wọn ba n ka iwe itan ilẹ Yoruba nikan. Ṣugbọn ni 1964, awọn oloṣelu hu kinni naa yọ pada, Alaafin Gbadegẹṣin Ladigbolu si fi Samuel Ladoke Akintọla ṣe Aarẹ ilẹ Yoruba ninu oṣu kẹjọ, ọdun naa, ọrọ naa si mu idunnu pupọ ati ironu pupọ dani fawọn eeyan. Bawọn kan ti n dunnu pe kinni naa daa, bẹẹ lawọn mi-in n ronu pe eeti jẹ, kin nitumọ oye yii, ki lo si de to jẹ Ladoke Akintọla ni wọn gbe e fun. Ọrọ naa mu awuyewuye ati ọpọlọpọ ariyanjiyan dani, kaluku ṣaa fẹẹ mọ idi abajọ ni. Ṣugbọn boya ẹni kan fẹ, boya ẹni kan kọ, Akintọla ti di Aarẹ-Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, ko si si ohun ti ẹnikẹni le ṣe si i. Ko tiẹ kuro lori ipo naa titi ti ọlọjọ fi de ba a ninu oṣu kin-in-ni, ọdun 1966, o lo oye naa titi digba naa ni.

Ko too di igba ti oun jẹ yii, bi eeyan yoo ba tu itan naa sẹyin diẹ, oun kọ lakọkọ. Ọba kan ti jẹ ni aafin Ọyọ ri to jẹ ọba alagbara, ara ọtọ ninu awọn Alaafin si ni. Ajagbo lorukọ rẹ, eyi ni wọn ṣe n pe e ni Alaafin Ajagbo. Nigba ti wọn bi i, ibeji ni wọn bi i, Ajampati lorukọ ẹkeji rẹ. Awọn mejeeji jọ ara wọn debii pe wọn aa maa ṣi wọn mu sira wọn, ti awọn eeyan yoo si maa ke kabiyesi fun ekeji rẹ, lai mọ pe ki i ṣe Alaafin ni wọn ki. Ko too di ọba, jagunjagun gbaa ni, o si laya, bẹẹ lo gboju, ko si ibi ti ogun ti le ti ẹ ko ni i ba a. O ni ọrẹ kan, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Kokoro-gangan lati ilu Iwoye, wọn ti n ba ara wọn bọ pẹ gan-an. Boya ọgbọn atọrunwa ni o, tabi irin-ajo rẹ to ti rin kaakiri, nigba ti Ajagbo di Alaafin, o mu nnkan tuntun wọnu ijọba ilu Ọyọ. Bii ọdun 640 lo ti jọba, ko si tun si Alaafin to pẹ bii tirẹ lori oye, nitori ogoje (140) ọdun lo lo nipo Alaafin.

Ọkunrin yii lo da igbimọ apaṣẹ, tabi igbimọ awọn to n ṣelu, silẹ ninu ijọba Ọyọ, asiko to si da a silẹ yii, ko ti i si iru nnkan bẹẹ niluu oyinbo paapaa, gẹgẹ bi itan awọn naa ti ṣe sọ. Ninu awọn eto tuntun to mu wọ inu iṣejọba ni akoso awọn ọmọ ogun rẹ. Ki oun too de, awọn ọmọ ogun yii maa n pọ kaakiri, ti wọn yoo si wa labẹ Balogun agbegbe kọọkan. Loootọ Balogun to wa niluu Ọyọ lo yẹ ko jẹ olori awọn Balogun gbogbo, ṣugbọn awọn Balogun mi-in laya, wọn si loogun debii pe wọn le wo oju Balogun Ọyọ nigba mi-in pe Balogun lawọn naa, Balogun kan ko si ju Balogun mi-in lọ. Eyi ni Alaafin Ajagbo ṣe da ipo Aarẹ-Ọna Kakanfo silẹ, o si fi i lelẹ pe ki i ṣe ọmọ Ọyọ nikan loye naa tọ si, olori ologun, tabi jagunjagun to dangijia julọ, ni yoo maa jẹ oye naa, ibi yoowu ko ti wa. Aarẹ Ọna Kakanfo yii ni yoo si jẹ olori ologun gbogbo fun ilẹ Yoruba pata.

Ẹni to ba mọ oju Ogun ni i pa obi n’Ire, Alaafin Ajagbo ko rẹni ti yoo gbe ipo naa fun ju ọrẹ rẹ lọ, iyẹn Kokoro-gangan to n gbe ilu Iwoye, pe oun gan-an ni ipo Aarẹ Ọna Kakanfo yii tọ si. Lakọọkọ, jagunjagun nla ni, o si mọ ọn pe ọrẹ oun ni, ati pe ko le da oun, nitori ko tun si alagbara bii tirẹ, agbara to si wa lọwọ aarẹ yii le debii pe bo ba kọju ija si Alaafin nilẹ Yoruba nigba naa, nnkan yoo ṣe. Alaafin ni olori ijọba loootọ, ọwọ rẹ si ni agbara wa, ṣugbọn Kakanfo ni olori awọn ọmọ ogun, oun ni gbogbo ọmọ ogun si n gbọrọ si lẹnu, koda, bi Alaafin duro sibẹ, ko si ọmọ ogun ti yoo gbọrọ si i lẹnu, aṣẹ ti aarẹ ba pa ni wọn yoo tẹle, ohun to ba sọ pe ki wọn ṣe ni wọn yoo ṣe. Agbara nla ti Aarẹ ni lọwọ yii ni Ajagbo ṣe sọ pe ko gbọdọ gbe aarin ilu pẹlu Alaafin, ko ma di pe alagbara meji yoo maa tako ara wọn. Oun ni olori gbogbo Balogun, ko si sẹni to le da aṣẹ rẹ kọja.

Eto ijọba ti Alaafin Ajagbo gbe dide yii mu nnkan dara, paapaa nigba to jẹ asiko ti awọn ọmọ ogun Ibariba n yọ Ọyọ Ile lẹnu ni. Kia ni Aarẹ yii ṣa awọn Balogun to ku jọ, to si kọ wọn lohun ti wọn yoo ṣe. Kia ni wọn rẹyin awọn ogun Ibariba yii, wọn si le wọn jinna debii pe ẹẹkọọkan lo ku ti wọn n yọju. Eleyii fi ẹsẹ Kokoro-gangan mulẹ gẹgẹ bii Aare Ọna Kakanfo, nigba to si jẹ gbogbo igba to fi wa nipo naa, ko si ogun ti ko bori, dandan ni fun aarẹ yoowu to ba wa lori oye lati maa ṣẹgun. Aarẹ to ba lọ sogun ti ko ṣẹgun ọhun, dandan ni ko ṣe bii ọkunrin. Ṣugbọn ki i saaba waye pe aarẹ kan lọ sogun ko ṣẹgun, nitori bi ọpọlọ ko ba fi le dun lọbẹ, tapa-titan rẹ ni yoo rẹ si i. Aarẹ Ajagbo ati Kokoro-gangan yii ni wọn pin awọn ọmọ ogun ilẹ Yoruba si ọna nla mẹrindinlogun, ati ọna wẹwẹ mẹrinlelaaadọta. Awọn wọnyi ni gbogbo ọmọ ogun ilẹ Yoruba wa labẹ wọn.

Lẹyin ti Kokoro-gangan lati Iwoye fipo naa silẹ ni Ọyatọpẹ tun jẹ, Iwoye yii loun naa ti wa. Lẹyin tiwọn ni Ọyabi lati Ajaṣẹ, Adeta lati Jabata, ati Oku lati Jabata bakan naa. Afọnja Laya-loko lo jẹ lati ilu Ilọrin, ko si si ẹni ti ko mọ ibi ti itan Afọnja ti bẹrẹ, ati ibi to pari si, nitori oun ni idi ti Ilọrin fi bọ kuro lọwọ awọn Yoruba, to di ibi ti Fulani ti n ṣe ọba wọn. Aye Afọnja gẹgẹ bii Aarẹ Ọna Kakanfo ni wahala ba ilẹ Yoruba, ti ijọba Ọyọ si daru, ti ijọba naa ko si ni isinmi titi ti wọn fi fa a ya. Lẹyin tirẹ, ati lẹyin ọpọlọpọ wahala ati idaduro, Toyejẹ lati Ogbomọṣọ ni wọn gbe ipo naa fun, ko too waa kan Ẹdun lati Gbọngan, lẹyin ti yoo ti ku tan. Amepo lati Abemọ lo jẹ lẹyin Ẹdun, ẹyin tirẹ lo si kan Kurumi Ijaye, Kurumi ọkunrin dan-in dan-in. Ojo Aburumaku lo jẹ lati Ogbomọṣọ, ọmọ Toyejẹ to kọ jẹ Aarẹ lati ilu naa ni, oun naa si wa nibẹ pẹ titi.

Aarẹ to jẹ gbẹyin ni saa yii ni Aarẹ Latoosa, lati ilu Ibadan loun ti wa. Ni akoko ti Latoosa jẹ yii, Ibadan ni ile agbara fun Yoruba, nitori awọn ọmọ ogun Ibadan yii ni Alaafin funra rẹ gbojule lati ṣe ohunkohun. Nidii eyi, ko ṣoro rara fun Latoosa lati di aarẹ, nigba to jẹ oun ni olori gbogbo jagunjagun wọn, ti Ibadan si jẹ olori ilu ajagun ilẹ Yoruba. Tipatipa lo tilẹ fi di Aarẹ Ọna Kakanfo yii, nitori ki i ṣe pe aarẹ to wa nibẹ, iyẹn Ojo Aburumaku, ti ku. Aburumaku wa laye, ṣugbọn Latoosa ranṣẹ si i pe ko ko gbogbo nnkan oye ati ọpa aṣẹ Aarẹ Ọna Kakanfo ranṣẹ soun n’Ibadan, ti ko ba fẹ ki ilẹ ga ju oun lọ. Ojo Aburumaku ko lagbara Ibadan, o mọ pe bi Latoosa ba binu, ko si ibi ti oun yoo gba, ko sẹni ti yoo gba oun lọwọ rẹ, alagbara kan ṣaa ju alagbara mi-in lọ. Iyẹn ni Ojo Aburumaku fi gba fun Ọlọrun, o si ko gbogbo eelo naa ranṣẹ pata. Nigba to di ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, 1871, wọn fi Latoosa jẹ Aarẹ-Ọna-Kakanfo ni gbangba ode.

Ni ọjọ kẹfa to joye lo fi Ajayi Ogbori-ẹfọn jẹ Balogun rẹ, to si fi Laluwọye jẹ Ọtun Balogun. Ṣugbọn wọn o ti i jokoo rara nigba ti ogun Ekiti Parapọ bẹrẹ, nigba ti Ogedengbe ṣaaju awọn Ijẹṣa, ti wọn darapọ mọ awọn Ekiti ati Ẹfọn, ti wọn mura lati yọ ara wọn kuro ninu igbekun awọn ara Ibadan, nitori labẹ wọn ni wọn wa lati ọjọ pipẹ, ti wọn si kọju ogun si wọn. Lati Ibadan titi wọ agbegbe awọn Ijẹṣa ati Ifẹ, titi wọ awọn Ilu Ekiti, abẹ Ibadan ni wọn wa, Ibadan lo n paṣẹ fun wọn, ko si si ohun ti awọn eeyan naa le da ṣe lai jẹ pe Ibadan fun wọn laṣẹ. Ajaga yii lawọn eeyan naa fẹẹ kọ, ni wọn ba bẹrẹ ogun gidi. Ogedengbe lo da kinni naa silẹ, nitori oun lo fẹẹ fi Odigbadigba jẹ Ọwa Ileṣa, ṣugbọn awọn Ibadan fi ẹlomiiran jẹ, wọn si bẹ Odigbadigba lori ni Ibadan, wọn ni oku ki i jẹ Ọwa, ko fi ẹni ti awọn fi sipo naa silẹ ko maa ṣejọba rẹ lọ.

Eleyii lo bi Ogedengbe ninu, toun naa fi lọọ ko ogun ja Ileṣa, to si le Ọwa ti awọn Ijẹṣa fi sori oye naa danu. Arifin pata lawọn Ibadan ka eleyii si, pe Ogedengbe yoo da aṣẹ ti awọn Ibadan pa kọja bẹẹ yẹn, yoo le ẹni ti awọn fi sori oye danu, wọn si mura lati mọ ohun to n ki i laya gan-an. Balogun Ajayi Ogbori-ẹfọn ko awọn ọmọ ogun rẹ jade n’Ibadan ninu oṣu kejila, 1872, wọn n wa Ogedengbe lọ. O ku dẹdẹ ki wọn wọ Ileṣa ni Ogedengbe sa mọ wọn lọwọ, o si kọja si inu igbo Ekiti lọhun-un. Bẹẹ lawọn ọmọ ogun Ibadan gba Ileṣa pada, wọn tun gba awọn ilu mi-in, wọn ko si dẹyin lẹyin Ogendengbe, wọn n wa a kaakiri. Ogedengbe tan wọn wọ inu igbo Ekiti, o duro de wọn ninu igbo Alawun, nitosi Ikẹrẹ, nibẹ lo si ti dana fawọn ọmọ ogun Ibadan ya, o foju wọn ri mabo. Ṣugbọn ibi ti ogun Ekiti ti bẹrẹ naa ree, ogun ti wọn fi ọpọlọpọ ọdun ja.

Lati igba ti wọn ti bẹrẹ ogun yii ni 1872, to jẹ bi wọn ti n ja ọkan ni omi-in tun n ruwe, titi ti ẹnu awọn Ekiti ati Ijẹṣa fi ko pe awọn ko ni i ṣe ẹru fun Ibadan mọ, ko si eyi to ṣẹyin Aarẹ Latoosa. Oun gan-an ni apaṣẹ ogun yii, oun lo si n dari wọn bi wọn yoo ti ṣe jagun naa. Adelu ni Alaafin igba naa, abẹ rẹ ni Latoosa ti bẹrẹ si i ṣe aarẹ. Amọ ko pẹ lẹyin naa ti Adelu fi waja, ti Adeyẹmi akọkọ si dọba ni 1875, Adeyẹmi lo si wa lori oye ni gbogbo igba ti Latoosa n lo agbara rẹ. Latoosa lawọn oyinbo bẹrẹ si i ba sọrọ nigba ti ogun naa fẹju tan, oun lawọn aṣoju oyinbo gbogbo n ri, ti awọn naa si n kọwe sawọn oyinbo yii lori ogun Ekiti parapọ to n lọ naa, o si ku gẹgẹrẹ ki wọn yanju ọrọ naa, iyẹn ni bii oṣu mẹfa si akoko ti ohun gbogbo yoo yanju ni Latoosa ku lojiji, o ku nigba ti ẹnikankan ko ro pe yoo ṣe bẹẹ lọ. Iyanu ni iku rẹ paapaa jẹ fun ọpọ eeyan.

Lẹyin ti Latoosa ti ku bayii, ọrọ ogun ko ṣẹlẹ mọ, nitori bii oṣu mẹfa to ku ni wọn pari ija naa, ti wọn si tọwọ bọwe adehun, ko si tun si ẹni to gbọdọ jagun kankan mọ pẹlu ara wọn. Nidii eyi, ko si ipo aarẹ kankan mọ, nigba to jẹ oye ologun ni, ti ko si si ogun mọ, ko sẹnikan ti wọn tun le ni ko waa ṣe aarẹ. Ni asiko naa, awọn oyinbo ti de, wọn ti n ṣejọba kaakiri, wọn si ti n fi ẹsẹ ijọba wọn mulẹ, bẹẹ ni wọn n fi agbara awọn ṣọja tiwọn mu awọn jagunjagun ati awọn araalu tabi ọba to ba fẹẹ ṣe agidi, ko si si ẹni to fẹẹ ko sọwọ oyinbo ninu wọn. Awọn jagunjagun ti awọn oyinbo n lo, awọn jagunjagun ilẹ Yoruba naa wa ninu wọn, ṣugbọn awọn oyinbo ni olori ogun tiwọn funra wọn, ko si oyinbo ti yoo fi eeyan dudu kan ṣe Aare Ọna Kakanfo, tabi olori ogun rẹ, nitori puruntu ni wọn ka gbogbo wọn si.

Nigba naa ni oye Aarẹ Ọna Kakanfo yii parẹ, nitori awọn ṣọja oyinbo lo ku to n dari ogun, awọn oyinbo funra wọn ni wọn si n ṣejọba, ko si si ohun ti wọn yoo fi oye yii ṣe. Koda, awọn ko ni Balogun tabi Ajagunna, gbogbo awọn oye yii ni wọn ti sọ di oye ọmọwe, sajẹnti tabi mejọ leeyan yoo maa gbọ, awọn jagunjagun ilẹ Yoruba naa si gbe jẹẹ. Ni ọdọ Alaafin ati lọdọ awọn ọba to ku paapaa, ko sẹni ti i yan Balogun nitori ko le lọọ jagun, Balogun ti yoo kan ri si aabo ilu pẹlu awọn ọmọ ọdẹ ni, ko si Balogun ti i lọ sogun. Kẹrẹkẹrẹ bẹẹ ni oye Aarẹ Ọna Kakanfo yii n lọ, ti awọn eeyan si n gbagbe rẹ, nitori ko si ogun, ko si si ijọba lọwọ Alaafin funra rẹ mọ, ijọba ti bọ sọwọ awọn oyinbo ti wọn n ṣejọba, gbogbo agbara Alaafin tabi ọba yoowu ko si ju ilẹ rẹ nikan lọ. Niluu rẹ paapaa, ajẹlẹ oyinbo lagbara ju u lọ, nigba to jẹ awọn ni wọn n ṣejọba.

Ohun ti ọpọ eeyan ko ṣe gbọ nipa oye naa mọ ree, nitori bo tilẹ jẹ pe lẹyin igba naa, awọn Alaafin mẹrin mi-in lo ti jẹ: Alaafin Adeyẹmi Alowolodu to waja, Agogooja to jẹ lẹyin tirẹ, Ṣiyanbọla Onikẹpe Ọladigbolu ati Adeniran Adeyẹmi Keji. Ninu awọn ọba mẹrẹẹrin yii, ko si eyi to tun dabaa Aarẹ Ọna Kakanfo mọ, nigba ti ko si oju ogun to fẹẹ ran an lọ. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Yoruba wa to lorukọ daadaa bii Herbert Macaulay, Kitoye Ajasa, Eric Moore, Ṣapara Williams pẹlu awọn mi-in ti wọn mọwe, ti wọn n ba awọn oyinbo ṣiṣẹ, ti wọn si jẹ ojulowo Yoruba, ko sẹnikan to fi ipo aarẹ lọ wọn, nitori ko si ohun ti wọn o fi i ṣe. Eyi ko jẹ ki awọn ọmọ Yoruba mọ ipo naa ati bo ṣe ṣe pataki to laye atijọ, ẹlomi-in o si gbọ orukọ naa ri, afi ninu iwe awọn onpitan, ati ninu owe awọn Yoruba bii aarẹ n pe ọ o n d’Ifa, bi Ifa rẹ fọre bi aarẹ ko ba fọre nkọ.

Afi lojiji ti awọn oloṣelu de, ti wahala si bẹrẹ, ti wọn deede sọ pe wọn yoo fi Samuel Ladoke Akintọla jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, lẹyin ọdun mẹtalelaaadọrun-un (93) ti Latoosa ti jẹ oye naa gbẹyin.

Ki lo waa de ti Akintọla loun yoo di aarẹ ilẹ Yoruba? Ẹ ka a ninu Alaroye lọsẹ to n bọ.

(182)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.