ITAN ṢOKI NIPA IGBESI AYE OLOYE OLUṢẸGUN ỌBASANJỌ

Spread the love

Ọkan pataki ninu awọn aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ. Oun ni olori aarẹ akọkọ ti yoo dari ijọba Naijiria lẹẹmeji, bo ti dari Naijiria lasiko ologun, bẹẹ naa lo ṣe aarẹ fun un lasiko ijọba tiwa-n-tiwa. Oriṣiiriṣii aṣeyọri ni Ọbasanjọ ti ṣe to sọ orukọ rẹ di manigbagbe fun gbogbo ọmọ Naijiria. Oun ni olori ologun akọkọ ti yoo gbejọba fawọn oloṣelu alagbada, ọkan pataki si ni ninu awọn ti wọn jagun abẹle Naijiria lọdun 1967 si 1970. Ọkan ninu awọn ọmọ Yoruba ti orukọ wọn ti la kọja ilẹ Yoruba, Afrika ati agbaye lapapọ ni.

IBẸRẸ IGBESI AYE Ẹ

A bi Oloye Oluṣẹgun Mathew Okikiọla Ọbaluayesanjọ sinu idile Amos Adigun Ọbaluayesanjọ (Ọbasanjọ) Bankọle ati Aṣabi Ọbaluayesanjọ niluu Abẹokuta lọjọ karun-un, oṣu kẹta ọdun 1937.

Ileewe Saint David Ebenezer School to wa n’Ibogun lo ti kẹkọọ alakọọbẹrẹ lọdun 1948, lẹyin to ṣetan nibẹ lo lọ si Baptist Boys High School l’Abẹokuta, nibi to ti kawee girama laarin ọdun 1952 si 1957.

O wọ ileeṣẹ ologun Naijiria (Nigerian Army) lọdun 1958. Lẹyin to wọle tan lo lọ si awọn ile-ẹkọ ologun loriṣiiriṣii lati kọ imọ nipa bi wọn ṣe n jagun. Awọn ile-ẹkọ to lọ naa ni:

  1. Mons Cadet School, Aldeshot, England.
  2. Royal College of Millitary Engineers, Chatham, England.
  • School of Survey, Newbury, England.
  1. College of Millitary Engineering, Poona.
  2. Royal College of Defence Studies, London

 

AWỌN OGUN TO KOPA NINU Ẹ:

Rogbodiyan orilẹ-ede Congo: Ọkan ninu awọn ogun to buru julọ lagbaaye ni rogbodiyan to ṣẹlẹ lorilẹ-ede Congo laarin ọdun 1960 si 1965. Ninu iwadii awọn onimọ ijinlẹ, eeyan to le ni ọgọrun ẹgbẹrun lo padanu ẹmi wọn latara ogun yii. Ninu awọn ologun Naijiria to ja lorukọ ajọ orilẹ-ede agbaye (United Nations) lasiko rogbodiyan yii ni Ọbasanjọ wa.

Ogun Abẹle Naijiria: Ogun abẹle Naijiria to waye laarin ọdun 1967 si 1965. Ọpọ eeyan lo mọ ogun yii si ogun Ojukwu, awọn mi-in si n pe e ni ogun Biafra. Ogun abẹle yii da lori awọn ẹya Igbo ti wọn fẹẹ ya kuro lara Naijiria lati da orilẹ-ede wọn silẹ, orilẹ-ede naa ni wọn pe ni Biafra.

Ọbasanjọ wa lara awọn adari ogun lasiko ogun abẹle yii, koda, oun gan-an lo gba ituuba awọn ọmọ orilẹ-ede Biafra lọjọ kejila, oṣu kin-in-ni ọdun 1970.

ỌBASANJỌ NINU IJỌBA OLOGUN:

Ọgagun Agba, Oluṣẹgun Ọbasanjọ

O fẹrẹ ma si bi a ṣe fẹẹ sọrọ ijọba ologun ti a ko ni i darukọ Ọbasanjọ si i. Ninu ijọba ologun naa lorukọ rẹ ti tubọ tan si i, nibẹ naa lo ti di ọmọ Yoruba akọkọ to di olori orilẹ-ede Naijiria.

Ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ naa kọ lo bẹrẹ, oun naa bẹrẹ labẹ awọn aṣiwaju kan ni. Lasiko ijọba rẹ, Ọgagun Yakub Gowon fi i ṣe kọmiṣanna fun iṣẹ ati ile gbigbe awọn ọmọ Naijiria.

Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keje, ọdun 1975, Ọgagun Murtala Mohammed fibọn gbajọba lọwọ Ọgagun Yakub Gowon, o sọ Ọbasanjọ di olori awọn oṣiṣẹ ijọba patapata.

Nigba ti ọkan ninu awọn ọga ologun, Lt. Col. Buka Suka Dimka, gbiyanju lati fibọn gbajọba lọwọ Murtala lọdun 1976, Ọbasanjọ wa lara awọn olori ologun ti wọn ni lati pa lẹyin ti wọn pa Murtala Muhammed ki wọn too le gbajọba. Ṣugbọn wọn o ri i pa. Oun nikan si kọ lori ko yọ ninu iku ojiji yii, lara awọn mi-in tori ko yọ lasiko naa ni Ọgagun Theopilus Yakubu Danjuma. Eyi lo mu ki ikọ Dimka padanu ipo olori ijọba ti wọn n wa.

Ọbasanjọ ati Danjuma gba akoso ijọba Muritala pada, ajọ awọn ologun (Federal Millitary Council) si yan Ọgagun Ọbasanjọ gẹgẹ bii olori ijọba tuntun.

O ṣeleri lati tẹle ilana ijọba Muritala Muhammade to pinnu lati da ijọba pada fawọn araalu, iyẹn dẹmokiresi, lọdun 1979. Eyi to mu ṣẹ lọjọ kin-in-ni oṣu kẹwaa, ọdun 1979. Shehu Shagari ni aarẹ to gbejọba silẹ fun. Bẹẹ lo kọwe fiṣẹ ologun silẹ lọjọ naa.

Ṣugbọn Ọbasanjọ fiṣẹ silẹ ni o, Naijiria ko fi i silẹ. Igboya lati sọ ohunkohun to ba n dun un lọkan bayoowu ko le to si tun sun un lọ sẹnu iku.

Ọbasanjọ bẹnu atẹ lu awọn iṣejọba Ọgagun Sani Abacha to tẹ awọn ẹtọ ọmọniyan kọọkan loju mọlẹ, eyi si mu ki wọn fẹsun kan an pe o fẹẹ ditẹ gbajọba lọwọ Abacha ni. Ni wọn ba pe Ọbasanjọ lẹjọ ni kootu awọn ologun, wọn si dajọ iku fun un nibẹ.

Ṣugbọn ọjọ iku ti wọn da fun Ọbasanjọ o ti i pe ti Abacha fi pa ipo da. Oriṣiiriṣii awuyewuye lo wa lori iku to pa olori ijọba naa tori bi ileeṣẹ ijọba ti n sọ pe ẹjẹ riru lo pa a, bẹẹ ni awọn oniwadii ati awọn aṣoju orilẹ-ede kan ni bẹẹ kọ lọrọ ri, majele ni wọn fi sounjẹ tabi omi rẹ fun un lasiko ti oun atawọn aṣẹwo n ṣe faaji nile-ijọba. Eyi to mu ki ọrọ naa tiẹ waa dojuru ni pe lọjọ to ku naa ni wọn sin in lai ṣayẹwo oku ẹ gẹgẹ bii aṣa Musulumi, ẹni kan ko le sọ pato nnkan to pa a gan-an afi ohun ti ijọba ba sọ faraaye.

ỌBASANJỌ NINU IJỌBA DẸMOKIRESI

Lọdun 1999 ti Ọgagun Abubakar Abdusalam fẹẹ gbejọba silẹ funjọba alagbada, Ọbasanjọ dide lati dupo aarẹ Naijiria lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), oun si lo gbegba oroke ninu idibo ọdun naa.

Ọbasanjọ sin Naijiria gẹgẹ aarẹ rẹ lati ọdun 1999 yii titi di ọdun 2007 to fipo naa silẹ fun aarẹ ana, Umaru Musa Yar’adua.

Ni bayii, ile ikawe ati oko rẹ, iyẹn Olusegun Obasanjo Presidential Library ati Obasanjo Farms, lo  ku to n moju to. Bẹẹ ni ko si yee sọrọ nipa ijọba bi wọn ba ṣina tabi wọn ṣe ohun kan to daa faraalu. Ọkan ninu awọn agba to ku ti a ni ni Naijiria ni, ọmọ Yoruba atata si loun i ṣe.

(73)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.