Iroyin aarọ ọjọ kọkanla, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Samuel Ọlọrunwa, kọwe fẹgbẹ oṣelu rẹ silẹ lanaa. Ọlọrunwa wa lara awọn oloṣelu ẹgbẹ APC to wa lẹyin igbakeji gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Agboọla Ajayi. 

Ọkunrin alaga ana yii ko sọ ohun kan fawọn oniroyin Punch nigba ti wọn bi i leere pe inu ẹgbẹ wo lo n lọ, ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ọkunrin naa ko ni i pẹ kede iwọle rẹ sinu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, awọn gbọ pe gbogbo eto ni wọn ti ṣe fun un lati wọnu ẹgbẹ naa.

 

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni ki Aarẹ Muhammadu Buhari yọ awọn minisita eto ẹkọ ẹ kuro loye, tori o jọ pe wọn o mọ nnkan ti wọn n ṣe. 

Akọwe agba fẹgbẹ naa, Bashorun Sehinde, lo gbe ọrọ ẹgbẹ naa jade lori ileewe ti minisita agba feto ẹkọ, Adamu Adamu, ni ki wọn ṣi wa ni titi pa. O ni bawo ni minisita feto ẹkọ ipinlẹ, Chukuwuemeka Nwajuiba, yoo ṣe ni kawọn akẹkọọ wọle, ti Adamu yoo tun pada jade pe ki wọn ma wọle mọ. 

 

Ẹka ijọba to n mojuto iwọle ati ijade ni Naijiria, Nigeria Immigration Service, da dokita mẹrindinlọgọta to n lọ sorilẹ-ede United Kingdom pada sile lori ẹsun pe wọn o niwee igbeluu orilẹ-ede ti wọn n lọ. 

Adari ajọ naa, Muhammad Babandele, ni dokita mejilelogiji ni baalu n bọ waa ko ni papakọ ofurufu Muritala Muhammed lanaa, ṣugbọn dokita mejidinlọgọta lo yọju pe awọn n lọ soke-okun, meji pere lo si ni iwe igbeluu to le fi wọ orilẹ-ede United Kingdom ninu wọn. 

Eyi lo mu kawọn da wọn pada sile pẹlu agbara tawọn ni labẹ ofin Naijiria lori iwọle ati ijade.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.