Iroyin aarọ ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ijọba ipinlẹ Ekiti fofin de ayẹyẹ ọlọpọ ero nipinlẹ Ekiti.

Alaga igbimọ amuṣẹṣe ipinlẹ naa lori ajakalẹ arun COVID-19, Ọjọgbọn Bọlaji Aluko, lo sọrọ yii ninu ikede to ṣe niluu Ado-Ekiti lanaa. 

O ni lọwọ bayii ninu akọọlẹ ijọba, apapọ ẹni to ti karun Coronavirus nipinlẹ naa jẹ mejidinlọgọrin. Eeyan mọkandinlọgbọn ni wọn ṣi wa lori idubulẹ aisan, awọn mẹtadinlogoji lawọn ti wo san ninu wọn. Eeyan meji lo si ti ku latara arun naa. 

Aluko ni asiko oriṣiiriṣii ayẹyẹ ipinlẹ Ekiti to fẹẹ wọle yii le mu ki arun ọhun tubọ tan kalẹ si i. Eyi lo ṣe n rọ awọn lọbalọba pe ki wọn gbegile gbogbo ayẹyẹ yoowu to ba wa niwaju wọn gẹgẹ bi ofin ijọba ipinlẹ naa ṣe la a kalẹ.

 

Aarẹ ẹgbẹ awọn awọn olukọ ileewe yunifasiti, Ọjọgbọn Abiọdun Ogunyẹmi, ni awọn fọwọ si i bi ijọba apapọ ṣe fẹẹ sun idanwo aṣekagba WAEC siwaju lati daabo bo ẹmi awọn ọmọleewe. O ni ki wọn fi ti orilẹ-ede Kenya to ti awọn ileewe wọn pa titi di ọdun 2021 nitori ajakalẹ arun yii ṣe awokọṣe. Bi o ba si pọn dandan ki wọn ṣi i, afi ki awọn obi tọwọ bọwe pe ohun yoowu to ba ṣe ọmọ awọn, awọn lawọn fi wọn sẹnu ewu. 

Abiọdun sọrọ yii nibi ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu akọweroyin Punch.

 

Ọlọpaa mẹta ku sinu ira nibi ti wọn ti n le janduku lọ nipinlẹ Ọyọ. 

Lopopona Balogun to wa niluu Ọyọ gan-an ni awọn oṣiṣẹ ijọba wọnyi ti padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n le awọn ọmọ amugbo adugbo naa lọ. 

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Olugbenga Fadeyi, fidii ọrọ yii mulẹ fawọn oniroyin.

O ni awọn agbofinro ti mu afurasi mẹrin lori ọrọ ọhun. Iwadii si n lọ lọwọ lori iku awọn ọlọpaa naa.

(47)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.