Iroyin aarọ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii. 

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko tẹ Eke Kanu, ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61) to fun ọmọ rẹ, ẹni ọdun mọkandinlogun, loyun n’Ikorodu. 

Ẹyin to fọmọ naa loyun lo tun mu un lọ sọdọ awọn chemist to n ta oogun pe ki wọn ba oun ṣẹ ẹ fun un. 

Kalu wa ni Panti bayii, nibi to ti n ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ gan-an lapa ọdọ tiẹ. 

Alukoro ọlọpaa, Bala Elkana, ni bi iwadii awọn ba ti pari lawọn yoo gbe e lọ siwaju adajọ lati jẹjọ ẹ nibẹ.

Ijọba ipinlẹ Eko ti awọn ile igbafẹ pa nipinlẹ Eko. 

Adari to n mojuto itẹle ofin ijọba fun eto aabo, Ọgbẹni Lanre Mojola, lo fọrọ yii to awọn oniroyin leti lẹyin to dari awọn oṣiṣẹ abẹ rẹ lọ si awọn ile faaji kaakiri Lagos Island, Surulere, Abule-Ẹgba atawọn agbegbe rẹ. 

O ni ijọba ipinlẹ Eko ko ni i fojuure wo ẹnikẹni to ba tapa sofin ti wọn la kalẹ lati dena ajakalẹ arun Coronavirus.

Awọn ọmọ Naijiria to le lọọdunrun (314) ni wọn ko wọ Naijiria lati orilẹ-ede United Kingdom. 

Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria lẹyin odi, Abikẹ Dabiri-Erewa, lo ju ọrọ yii sori ikanni rẹ lori ẹrọ ayelujara Twitter. 

Awọn ọmọ Naijiria yii la gbọ pe wọn ha silẹ okeere lasiko ajakalẹ arun Coronavirus.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.