Iroyin aarọ ọjọ kin-in-ni, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii. 

Awọn dokita ati olukọ kọyin sijọba lori iwọle awọn akẹkọọ, wọn lo lewu gidigidi. 

Akọwe agba fẹgbẹ awọn olukọ, Mike Ekene, sọ fun Iwe-iroyin Punch pe ijọba apapọ ti ki ọrọ oṣelu bọ iwọle yii. O ni nibo lawọn tiṣa ti wọn o sanwo oṣu fun ti fẹẹ rowo ra awọn eroja ti wọn o fi daabo bo ara wọn. 

Bẹẹ ni Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo, Ọjọgbọn Innocent Ujah, ni pẹlu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe kọti ọgbọin sawọn ikilọ ajakalẹ arun yii, ohun to lewu gidi ni lati ṣi ileewe silẹ bayii.

Awọn aṣofin binu kuro niwaju minisita iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo, wọn lo jagbe mọ awọn lasiko ti wọn n beere ọrọ lọwọ ẹ

Lanaa ode yii ni awọn aṣofin pe minisita eto iṣẹ, Festus Keyamo, pe ko waa ṣalaye ibi to ba eto igbanisiṣẹ tijọba fẹẹ ṣe fawọn ọmọ Naijiria to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (774,000). Ṣugbọn ọrọ yii pada diṣu ata yan-an-yan ti minisita yii atawọn aṣofin n jagbe mọra wọn.

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, kede pe o ṣee ṣe ki wọn bẹrẹ si i ṣi awọn ileejọsin ipinlẹ naa lọjọ kẹtadinlogun oṣu yii, ipele kin-in-ni lori ṣiṣi awọn ileewe yoo si bẹrẹ logunjọ oṣu keje bakan naa. 

Fayẹmi sọrọ yii ninu ikede to ṣe fun gbogbo ipinlẹ Ekiti lalẹ ana, Tusidee.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.