Iroyin aarọ ọjọ kẹwaa, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii.

Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, kọwe si ọga agba ọlọpaa, Muhammad Adamu, pe ki wọn ṣewadii ọkunrin oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan, Jackson Ude, lori awọn ọrọ ibanilorukọjẹ to n sọ nipa oun lori ikanni ayelujara rẹ to pe ni Point Blank News.

Ọkan ninu awọn iroyin to fi sori ikanni ayelujara rẹ yii lo ti sọ pe Igbakeji Aarẹ gba biliọnu mẹrin owo Naira lọwọ adele alaga EFCC ti wọn ṣẹṣẹ da duro, Ibrahim Magu.

 

Aṣoju ijọba Lebanon, Housam Diab, binu kuro nibi ipade tawọn aṣojuṣofin pe e si lori ọrọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn n fi ṣẹru loke okun, paapaa lorilẹ-ede Lebanon ti iwa ọhun pọ si julọ. Ṣugbọn iwe-iroyin Punch ṣalaye pe awọn ri i gbọ pe ambasadọ orilẹ-ede Lebanon yii n reti ipade idakọnkọ to jẹ awọn alẹnulọrọ nikan ni yoo wa nibẹ ni, ṣugbọn nigba to de to ba ero rẹpẹtẹ atawọn oniroyin lo jẹ ko binu lọ.

 

Ṣọọṣi Redeemed Christian Church of God yọ ọkan ninu awọn igbakeji pasitọ wọn to wa niluu Akurẹ, Ọgbẹni Gideon Bakare.

Ninu fidio kan to gbori ẹrọ ayelujara kankan ni wọn ti ri pasitọ Ondo yii nihooho to n bẹ ọkan ninu awọn ara ṣọọṣi rẹ pẹlu mọlẹbi ẹ to wa ninu yara pe ki wọn ṣaanu oun.

Nnkan to ṣẹlẹ ni pe, arabinrin yii ni pasitọ fẹẹ ba oun sun, tori ẹ loun ṣe dọgbọn ṣe bii ẹni pe oun gba fun un to fi tan an wa sinu ile ọkọ rẹ, to si pe gbogbo ẹbi wọn le e lori.

Alukoro ijọ Ridiimu, Pasitọ Ọlaitan Olubiyi, lo ṣalaye ipinnu ijọ naa ninu atẹjade kan to gbe jade lanaa, Tọsidee. O ni ijọ ti yọ Pasitọ Gideon kuro loye nitori iwa to hu yii, ko si le di ipo ajihinrere kankan mu ninu sọọṣi Ridiimu mọ.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.