Iroyin aarọ ọjọ kẹtala, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ọkan pataki kinu awọn agba agbẹjọro to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan ni Naijiria, Ọgbẹni Fẹmi Falana, ti tako iroyin kan to jade nipa rẹ pe o gba miliọnu mejidinlọgbọn Naira #28m lọwọ adele alaga ajọ EFCC to n mojuto iwa ajebanu ni Naijiria, Ọgbẹni Ibrahim Magu, ti wọn ṣẹṣẹ juwe ile fun lori ẹsun ṣiṣe owo ilu mọkumọku.

Fẹmi Falana sọ ọrọ yii nínú lẹta kan ti agbẹjọro rẹ, Amofin Olumide Fusika, fi ranṣẹ si ileeṣẹ iroyin naa.

Fusika ti ké sí Ileeṣẹ iwe iroyin yii pe ki wọn ṣe àtúnṣe sí iroyin naa, ki wọn sì tọrọ aforijin lọwọ onibara oun, lori iroyin ibanilorukoje ti wọn kọ yii laarin wakati mejidinlaadọta tabi ki wọn mura lati fidi ootọ wọn mulẹ nile-ẹjọ.

 

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, tako iroyin to n lọ kaakiri pe wọn ti gbegi dina oun lati dije ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu All progressive Congress ti yóò wáyé logunjọ, oṣu keje ọdun yii.

Ohun to fa idi ọrọ yii ko ju iroyin to jade pe ẹgbẹ oṣelu APC ti yọ ọkan ninu awọn mọkanla ti wọn ṣe ayẹwo fun lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn lọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade ti alukoro rẹ, Ọgbẹni Oyewamide Ojo, gbe jade lanaa, Sannde yii,  l’Akeredolu ti tako ahesọ ọhun. O ni awọn alatako gomina ipinlẹ Ondo lo n gbe iroyin eleje naa kiri lati fi bu omi tutu sí àwọn alatilẹyin rẹ lọkan.

Oyewamide fi kun ọrọ rẹ pé kì í se pé Gomina Akeredolu yóò dije nikan o, oun ni ipinlẹ Ondo yoo tun yan gẹgẹ bii gomina wọn ninu idibo ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa ọdun yii.

 

Ọwọ ọlọ́pàá tẹ ọkunrin ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn kan, Chukwubeka Obiaku, to jẹ ọmọ ìjọba ibilẹ Ikeduru nipinle Imo lori ẹsun jibiti ati ijinigbe.

Ohun ta a gbọ ni pe Chukwubeka lu arabinrin orilẹ-ede Amẹrika kan ni jibiti miliọnu mejidinlogun ataabọ Naira.

Iyẹn nikan si kọ ni ẹṣẹ to ṣẹ, niṣe ni Chukwubeka fi ọgbọn àrékérekè tan arabinrin naa wa sile-itura kan nipinlẹ Eko, nibẹ lo si ti i mọ lati oṣu keji ọdun 2019 to n gba owo ninu akannti rẹ, to si tun n forukọ rẹ lu jibiti kiri.

Gẹgẹ bí iroyin ṣe sọ, ori ẹrọ ayelujara Facebook ni Chukwubeka ati arábìnrin yii ti pade ara wọn. Ko too wa a wa si Naijiria.

(45)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.