Iroyin aarọ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki ajọ to n ri si iwa ajẹbanu, EFCC, da awọn ile aarẹ ile-igbimọ aṣofin agba ana, Oloye Bukọla Saraki, pada. 

Loṣu kejila ọdun to lọ nile-ẹjọ yii kọkọ dajọ pe oun fun EFCC laṣẹ lati gbẹsẹ le awọn ile naa fungba diẹ tori wọn ni owo ijọba Kwara ni Saraki fi kọ wọn nigba to wa nipo gomina laarin ọdun 2003 si 2011.

Ninu idajọ ti Adajọ Rilwan Aikawa ṣe lanaa lo ti paṣẹ fun wọn pe ki wọn da awọn ile naa pada fun Saraki tori oun ko ri idi kan pataki toun fi le ni ki EFCC gba awọn ile naa patapata.

 

Ile-igbimọ aṣofin bẹnu atẹ lu bi Minisita iṣẹ ati eto igbanisiṣẹ ijọba apapọ, Chriss Ngige, ṣe kọ lati yọju sile-igbimọ naa lati ba wọn sọrọ lori awọn ọmọ Naijiria ti wọn n fi ṣẹru loke okun. 

Alaga ajọ ile-igbimọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere, Tolulọpẹ Akande-Sadipẹ,  ni ẹlẹẹkarun-un tawọn yoo pe minista naa ree to n ran-an-yan sawọn.

 

Ijọba apapọ ni ki awọn dokita to fẹẹ lọọ ṣiṣẹ lorilẹ-ede United Kingdom ro o daadaa o, tori ijọba ọhun ki i san owo ijamba ojiji fun wọn. 

Minisita eto ilera, Dokita Osagie Ehanire, lo sọrọ yii lasiko ti igbimọ aarẹ lori COVID-19 n jiṣẹ fawọn ọmọ Naijiria. 

Ehanire ni oun ti beere lọwọ awọn dokita to wa lọhun-un, wọn si ti jẹ ko ye oun pe ko sẹni to n san owo ijamba ojiji yii fun wọn ni UK. Ijọba Naijiria wa lara awọn orilẹ-ede diẹ to n san eyi. 

Iwadii iwe iroyin Punch fidi ẹ mulẹ pe owo tijọba apapọ n san fun ijamba ojiji loṣooṣu yii jẹ ẹgbẹrun marun-un Naira. Iye ti wọn n san niyi titi di oṣu kẹfa to pari yii.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.