Iroyin aarọ ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

O ṣee ṣe kijọba ipinlẹ Eko tun ṣofin konilegbele nitori ajakalẹ arun Coronavirus. 

Kọmiṣanna fun eto ilera ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, ni loootọ nijọba ipinlẹ naa ti gbiyanju lati faaye gba awọn araalu lati ṣiṣẹ ọrọ aje wọn lasiko ti wọn kogun ja ajakalẹ arun Coronavirus, ṣugbọn pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, awọn o ni i ro o pe ẹẹmeji kawọn too ṣofin konilegbele tuntun ti ọrọ ba gba bẹẹ. 

 

“Ko si ilu kan to le fọkanbalẹ mọ ni Naijiria” Ọbasanjọ

Aarẹ tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ni ọrọ Naijiria ti kuro lọwọ pe boya ẹya kan, ipinlẹ kan, tabi awọn ẹlẹsin kan ni wọn n fojuko iṣoro eto aabo, o ti di ohun to kan tẹbk tara kaakiri orilẹ-ede yii. O ni eto aabo ijọba apapọ, bi wọn ti n ṣe e yii, ko le ṣeto aabo fun ẹya kan, ka too waa sọ pe fun gbogbo orilẹ-ede

 

Ile-ẹjọ Iwọ-Oorun Afrika, ECOWAS Court of Justice, paṣẹ fun ijọba Naijiria lati sanwo fawọn ṣọja to le ni ojilenigba (244) ti wọn yọ niṣẹ lọdun 2016. Ohun to fa a ti ọrọ iyọniṣẹ naa ṣe dẹjọ ni pe ko sẹni ti wọn pe lẹjọ lati sọ tẹnu ẹ ki wọn too gbaṣẹ lọwọ wọn. 

Ọjọbọ, Tọsidee, gan-an ni wọn ṣedajọ yii ṣugbọn ana niroyin yii too tẹ awọn oniroyin lọwọ. 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.