Iroyin aarọ ọjọ kẹta, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ajọ to n mojuto imunadoko ounjẹ ati oogun ni Naijiria, National Agency for Food and Drugs Administration Control (NAFDAC), da oju agbo ti wọn ti fẹẹ gbe agbo, to n ṣewosan Coronavirus jade.
Akọṣẹmọṣe oniṣegun ibilẹ, Paul Oni, lo ṣagbekalẹ agbo COVID-19 to pe ni “Oxibiotics” yii, gbọgan igbafẹ Centenary Hall to wa l’Ake lo si ti gbero ati ko o jade bii ọmọ tuntun.
Ṣugbọn tijatija lajọ NAFDAC fi debẹ ti wọn da agbo naa ru, wọn si tun lọọ ti ileeṣẹ ti ọkunrin naa ti n po oogun yii pa. Wọn ni ko ti i gbawe aṣẹ le e lori.

Ipinlẹ Ekiti fi Ajewọle ṣẹsin lori ẹsun ifipabanilopọ.
Kaakiri gbagede ti gbogbo oju ti le ri i ni ijọba Ekiti lẹ orukọ ati fọto ẹni ọdun mẹtalelogun nni, Ajewọle Filani, mọ lori ẹsun ifipabanilopọ to jẹbi rẹ. Ile-ẹjọ ti da a lẹwọn gbere lori ẹsun yii, ijọba Ekiti naa si ti gbe fọto rẹ jade kaye le ri i.
Kọmiṣanna eto idajọ ipinlẹ naa, Ọgbẹni Ọlawale Fapohunda, ni gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo ṣe lati ri i pe ipinlẹ Ekiti ko dile awọn afipabanilopọ.

Ile-igbimọ aṣofin Naijiria da eto igbanisiṣẹ tijọba apapọ gbe kalẹ duro.
Agbẹnusọ ile-igbimọ aṣofin agba, Ajibọla Bashiru, ati agbẹnusọ ile-igbimọ aṣojuṣofin, Benjamin Kalu, lo kede aṣẹ awọn aṣofin lati da igbanisiṣẹ naa duro lọjọ Wẹsidee ọsẹ yii. Wọn ni eto naa ki i ṣe ti ileeṣẹ aarẹ nikan, o lọwọ awọn aṣofin ninu. Gbogbo ohun to ba si yẹ kawọn wadii nipa rẹ lawọn ni lati mọ ko too di pe wọn le bẹrẹ ẹ.
Eyi waye lẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ laarin minisita iṣẹ ṣiṣe ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo, atawọn aṣofin lọjọ Iṣẹgun.
Ṣugbọn minisita yii ti ni awọn aṣofin ko lẹtọọ ati da eto yii duro labẹ ofin Naijiria. Wọn le beere ọrọ ni, wọn o le paṣẹ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.