Iroyin aarọ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

 

Ọkan pataki ninu awọn oṣere tiata, Bọsẹ Adewọyin tawọn mi-in mọ si Madam Tinubu, ṣaisi laarọ ana, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa ọdun yii. Irọlẹ ana naa ni wọn sin in. Adewọyin di gbajumọ nibi ipa to ko ninu ere Ẹfunroye Tinubu ti Oloogbe Akinwunmi Iṣọla kọ, ti Ọgbẹni Gbenga Adewusi si dari lọdun 1989. Oun naa lo kopa “MAMA ONIMAMA” ninu ere Ọmọ Ghetto ti Funkẹ Akindele ṣe.

 

Ile-igbimọ aṣojuṣofin kọ ẹbẹ orilẹ-ede Ghana lori ile ijọba Naijiria ti wọn wo lorilẹ-ede wọn. Abẹnugan awọn aṣojuṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, ni ile lasan kọ ni wọn wo ni Ghana, orilẹ-ede wa gan-an ni wọn doju ija kọ, o si yẹ ki Naijiria naa fesi to le fun wọn lori ohun ti wọn ṣe yii ni.

 

Ijọba apapọ kọwe eto iwọle awọn akẹkọọ kaakiri Naijiria ranṣẹ sawọn aṣofin ijọba apapọ lati jiroro lori ẹ. Minisita fun eto ẹkọ, Ọgbẹni Chukwuemeka Nwajuiba, ni awọn fi iwe eto iwọle ranṣẹ sawọn sẹnetọ yii ki wọn le ṣe lameetọ ẹ lati le ṣafikun tabi ayọkuro ohun ti ko ba yẹ nibẹ ti isinmi ọlọjọ gbọọrọ yii ko fi ni i ṣakoba fun eto ẹkọ Naijiria.

Lati ọṣu kẹta ni ijọba apapọ ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ileewe pa nitori ajakalẹ arun Cronavirus.

 

Eefin jẹneretọ pa hiadirẹsa meji nipinlẹ Eko. Ohun ta a ri gbọ ni pe eefin ẹrọ amunawa ti Temitọpẹ Ọlagunju tan sitosi inu ile wọn lagbegbe Ọgba nitori ojo lo pa oun ati aṣerunlọṣọọ mi-in, Baraka, ti wọn jọ wa ninu ile. Ẹni kẹta wọn to jẹ ọmọ ẹkọṣẹ ni wọn ba laaye to ṣi n pofolo. Lẹsẹkẹṣe naa ni wọn ti gbe e lọ sileewosan, ibẹ lo wa titi di bi a ṣe n sọrọ yii.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.