Iroyin aarọ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

 

Lẹyin ọjọ mẹwaa ti wọn ti fi i sahaamọ, ileeṣẹ ọlọpaa tu adele alaga EFCC ti wọn da duro, Ibrahim Magu, silẹ. 

Lati ọjọ kẹfa oṣu yii lawọn ẹṣọ alaabo ti gbe Magu lati waa jẹjọ awọn ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.

Lati igba ti wọn ti gbe e yii naa lawọn agbẹjọro rẹ ti n ṣọna bi yoo ṣe gbominira, ṣugbọn bi ọlọpaa ṣe n ti wọn si igbimọ Adajọ Ayọ Salami to n ṣewadii ẹ naa ni igbimọ naa n sọ pe awọn o ni ki wọn de Magu mọlẹ fawọn. 

Irọlẹ ana lọrọ naa too niyanju, ti igbimọ oniwadii yii ni ki awọn ọlọpaa da ọkunrin olori EFCC naa silẹ.

 

Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn eeyan nla nla ṣedaro Tolulọpẹ Arotile, obinrin ṣọja akọkọ ti yoo wa ọkọ ofurufu lọ soju ogun. 

Ninu atẹjade to jade nileeṣẹ awọn ajagun oju ofurufu lanaa ni wọn ti ṣalaye pe ọkan ninu awọn ọrẹ Tolulọpẹ nigba to wa nileewe awọn ologun lo fi mọto pa a. Bẹẹ wọn fẹẹ kira wọn ni, ki i ṣe pe iyẹn mọ-ọn-mọ gba a.

 

Awọn dokita fopin si iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta ti wọn ṣe l’Ekoo. 

Ninu atẹjade ti alaga igbimọ awọn oniṣẹ eto ilera ipinlẹ naa, Oluwajimi Ṣodipọ, fi sita lo ti ni ki awọn dokita atawọn oniṣẹ eto ilera ipinlẹ Eko to ku bẹrẹ iṣẹ loni-in.

Ipinnu yii waye lẹyin ipade awọn dokita naa pẹlu Gomina Babajide Sanwoolu, Ọba Rilwan Akiolu tilu Eko ati awọn alẹnulọrọ mi-in ninu eto ilera. 

Alaga yii rọ awọn oṣiṣẹ ijọba to wa lẹka wọn pe ki wọn ri i daju pe awọn mojuto ohun to fa iyanṣẹlodi naa kiakia, ki wọn le dena ajalu buruku lẹka eto ilera ipinlẹ Eko.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.