Iroyin aarọ ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ijọba apapọ ti leri pe bayoowu ki awọn eeyan pariwo to, awọn o ni i ṣi ileewe lasiko ajakalẹ arun yii.

Minista eto ẹkọ, Ọgbẹni Chukwuemeka Nwajuiba, ni awọn n gbọ ariwo lọtun-un losi lori bi awọn akẹkọọ ṣe jokoo sile nitori ile-ẹkọ wọn ti wọn ti pa. Ṣugbọn bayoowu ki ariwo naa pọ to, awọn o ni i ṣilẹkun ileewe lai jẹ pe ọwọ arun Coronavirus yii lọ silẹ. Awọn o ni i ko awọn ọmọde Naijiria sinu ewu.

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) yan lati dupo gomina ipinlẹ naa lorukọ ẹgbẹ wọn. Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Gomina Obaseki binu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) nigba ti wọn ni ko le dupo gomina lorukọ ẹgbẹ awọn nitori iṣoro wa ninu iwe-ẹri to mu jade nile-ẹko giga University of Ibadan.

Ijọba apapọ ti yọ ọrọ a n ra mọto kuro ninu eto inawo Naijiria.

Ninu iwe eto ọrọ aje ti oludamọran aarẹ, Fẹmi Adeṣina, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lanaa lo ti ṣalaye pe yatọ si ọkọ panapana, ọkọ alaarẹ, ati awọn ọkọ mi-in to ṣe pataki fun iṣẹ ilu, ijọba apapọ ti fofin de a n ra ọkọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba kan. Wọn ni inawo naa ko pọn dandan.

 

(46)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.