Iroyin aarọ ọjọ kẹrin, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

 

Lanaa ode yii ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, da ọjọ kẹta oṣu kẹjọ gẹgẹ bii ọjọ iwọle fawọn ọmọleewe to wa nipele ati bọ si ẹka eto ẹkọ mi-in bii Primary 6, JSS 3 ati SSS 3. Ni ti awọn ile-ẹkọ giga, wọn ni ki wọn maa ba eto ẹkọ ori ayelujara wọn lọ.
Fun awọn ileejọsin ati ile faaji gbogbo, ijọba ipinlẹ Eko ni awọn o tiẹ ti i le sọ ọjọ tawọn yẹn oo bẹrẹ iṣẹ tiwọn

Ijọba ipinlẹ Ogun fofin de awọn ileewe ati ileejọsin, wọn ni awọn o ti i dajọ iwọle fun wọn o.
Akọroyin Gomina Dapọ Abiọdun, Kunle Somorin, lo fi ọrọ yii sita ninu atẹjade ti wọn fun awọn oniroyin lanaa niluu Abẹokuta.
O ni lori awọn ọmọ ileewe ti wọn fẹẹ bọ si ẹka eto ẹkọ mi-in, awọn yoo pepade pẹlu awọn alẹnulọrọ nidii eto ẹkọ lati mọ bi awọn yoo ṣe gba wọn laaye lati wọle ṣedanwo wọn.
Ṣugbọn ni lọwọ bayii, awọn o ti i gba ileewe kankan tabi ileejọsin yoowu laaye ati bẹrẹ si i kero jọ.

Ọọni ileefẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II, ṣepade iranti Ọọni Adesọji Tadenikawo Aderẹmi to ku lọdun 1980.
Ana yii lo pe ogoji ọdun ti ọba naa waja lẹyin bii aadọta ọdun to fi lo ipo Ọọni Ileefẹ, to si tun n ba wọn da soṣelu Naijiria ko le gbominira lọwọ ijọba oyinbo amunisin.
Ọọni Ogunwusi ni iṣẹ n lọ lọwọ lati tubọ sọ orukọ ọba naa di manigbagbe ninu iwe itan. O leri nibi ipade yii pe ọmọ toun ba bi gan-an, orukọ Ọba Aderẹmi loun oo sọ ọ.

(54)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.