Iroyin aarọ ọjọ kẹjọ, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Awọn agbofinro lọọ tu ile adele alaga EFCC, Ọgbẹni Ibrahim Magu. 

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni adele alaga EFCC naa ṣi wa lahaamọ awọn ọlọpaa, agbofinro kan lo si ṣofofo ọrọ naa fun iwe iroyin Punch pe awọn ti lọọ tu ile ti Magu n gbe tẹlẹ ni opopona Abdujalil,  Karu Site, awọn si ko awọn iwe kan kuro nibẹ tawọn oo ṣewadii le lori.

 

Ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti gbe pasitọ ijọ CAC kan, Oluwafẹmi Oyebọla, lori ẹsun pe o n fipa ba ọmọ rẹ lo pọ, o si tun ṣẹyun fun un lẹẹmẹta. 

Ọmọ yii naa lo lọọ fẹjọ rẹ sun lagọ ọlọpaa Owode Egbado. 

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lo fọrọ naa to awọn oniroyin leti nibi atẹjade to fi ranṣẹ lanaa.

 

Adari igbimọ amuṣẹṣe aarẹ lori itankalẹ aarun Coronavirus, Ọgbẹni Boss Mustapha, ni pẹlu bi awọn to karun yii ṣe n pọ si i ninu awọn oṣiṣẹ ijọba, o ṣee ṣe kawọn tun dabaa ofin konilegbele mi-in lẹyin ọsẹ meji. 

Mustapha sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja, lọjọ Mọnde.

(54)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.