Iroyin aarọ ọjọ kejila, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ijọba Naijiria ko mọkandinlọgbọn ninu awọn ọmọ orilẹ-ede wọn to n ṣẹru ni Lebanon wọle lanaa.

Ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe to wa niluu Abuja lajọ to n gbogun ti iwa ifiniṣẹru, NAPTIP, ati ajọ ile-igbimọ aṣojuṣofin to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere ti gba wọn lalejo. 

Ọkan ninu awọn ọmọ Naijiria ti wọn ri ko de ni Peace Busari, ọmọ Ibadan ti Wael Jerro fẹẹ ta lori Facebook, ati Temitọpẹ Arowolo ti wọn fẹsun ole ati igbiyanju lati paniyan kan. 

Arowolo ni ohun toju oun ri ni Lebanon, oun o gbadura ẹ fun Sataani gan-an lati ri i.

 

Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Wọle Oyebamiji, ti bọ lọwọ arun Coronavirus to n yọ ọ lẹnu. 

Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Ọṣun, Dokita Rafiu Isamotu, lo kede ọrọ naa lanaa, ọjọ Satide. O ni yatọ si sẹkẹtiri to bọ lọwọ arun COVID-19 yii, eeyan mọkanlelogun mi-in ni wọn gbawosan lọwọ ajakalẹ arun naa. 

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe eeyan mẹtalelogun mi-in lawọn ti tun ṣawari pe wọn larun Coronavirus nipinlẹ Ọṣun.

 

Awọn adigunjale jiiyan mẹta gbe nipinlẹ Ekiti. 

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, ti fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin pe loootọ ni awọn adigunjale ji eeyan meji gbe nisọ pako kan to wa ni Isinbọde Ekiti lẹyin ti wọn gba gbogbo nnkan ini oniṣowo ati oṣiṣẹ ibẹ, ki wọn too lọọ ji oṣiṣẹ ijọba kan gbe ninu ọkọ akero Hilux. 

Awakọ Hilux yii wa nileewosan nibi to ti n gbatọju lọwọ, tori awọn agbebọn yii yinbọn fun un.

Abutu ni ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe yii ti raaye bọ mọ wọn lọwọ, awọn meji to ku naa yoo si bọ ninu ide wọn laifarapa.

(52)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.