Iroyin aarọ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Oku Ajumọbi ti wọn o ti i sin, wọn ni ija oṣelu lo fa a o. 

Gẹgẹ bii ofin Musulumi, ọjọ ti oku ba ku gan-an tabi o pẹ tan ọjọ keji lo yẹ ki wọn ti sin in, ṣugbọn oni lo pe ọjọ kẹta ti oku gomina ana Ọyọ, Abiọla Ajimọbi, ti wa nilẹ ti wọn o ti i sin in. Iwe Iroyin Punch to ṣewadii ọrọ naa gbọ lẹnu ọkan ninu awọn mọlẹbi pe bi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ko ṣe ti i fọwọ si ibi ti wọn maa sin in si lo n da oku naa duro. Ṣugbọn akọroyin Gomina Ọyọ, Ọgbẹni Taiwo Adisa, ni bi wọn ṣe n sọ ọrọ naa kọ lo ri rara. Ẹbi Ajumọbi fẹẹ sin in sori ilẹ ti kootu ko ti i pe ni tiẹ ni. Ko si si ohun to kan gomina lori pe ki wọn ma sinku wọn.

Ajọ to n mojuto ọrọ ajakalẹ arun ni Naijiria, National Center for Diseases Control, kede pe eeyan to lẹẹdẹgbẹrin (779) lawọn tun ri pe wọn ti karun Coronavirus ni Naijiria, eyi to mu ko jẹ eeyan to le ẹgbẹrun mẹrinlelogun (24,077) ni wọn ti ko arun yii lapapọ. Eeyan to le lẹẹdẹgbẹta (558) lo si ti ku latara ẹ.

Ijọba ipinlẹ Ondo ni irọ pata ni pe ijọba awọn gbaṣẹ lọwọ awọn dokita to daṣẹ silẹ ni University of Medical Science and Teaching Hospital o. Kọmiṣanna fun eto iroyin ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Donald Ojogo, ni eto ile gbigbe ti wọn ṣe ni yunifasiti naa lawọn kan fẹẹ da duro, gbogbo rogbodiyan to n lọ laarin ijọba atawọn dokita to daṣẹ silẹ yoo lawọn yoo yanju titi ọjọ ọla.

(90)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.