Iroyin aarọ ọjọ keji, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ijọba apapọ ti fowo kun owo epo o.
Lanaa ode yii ni ẹka ijọba to n diye le epo rọbi, Petroleum Products Pricing Regulatory Agency, kede fawọn elepo pe wọn ti lanfaani lati ta epo bẹntiroolu laarin ogoje Naira ati ọgọrin kọbọ (N140.80) si Naira mẹtalelogoje ati ọgọrin kọbọ (143.80).
Nnkan bii ogun Naira nijọba gbe le owo epo yii tori Naira mọkanlelọgọfa ati ọgọrin kọbọ (N121.0) si Naira mẹtalelọgọfa ati ọgọrin kọbọ (N123.80) ni wọn ni kawọn elepo ta a tẹlẹ.

Ṣọọbu mẹrin gbana ninu ọja Ajao Estate to wa lọna Airport Road, nipinlẹ Eko. Ọja miliọnu iyebiye lo deeru mọ inu awọn ṣọọbu yii gẹgẹ bi adari ẹka ijọba Eko to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, Lagos State Emergency Management Agency (LASEMA), Olufẹmi Ọkẹ-Ọsanyintolu, ṣe sọ fun akọroyin Punch. O ni ọkan ninu awọn ṣọọbu to wa nitosi ọja yii ni ina mọnamọna ti ta, to si ṣe bẹẹ ran de awọn ṣọọbu to ku ninu ọja yii. Ẹni kan ko ba iṣẹlẹ naa lọ, ṣugbọn aimọye ọja lo ṣofo danu

Ijọba ipinlẹ Ọyọ kede awọn eto ti wọn ti ṣe kalẹ lati daabo bo awọn akẹkọọ ti wọn fẹẹ wọle nipinlẹ wọn.
Kọmiṣanna eto ẹkọ, imọ ijinlẹ ati ẹrọ igbalode ipinlẹ Ọyọ, Ọlasunkami Ọlalẹyẹ, ni gbogbo ọsẹ to lọ yii lawọn fi n kọ awọn olori ileewe kaakiri bi wọn oo ṣe daabo bo awọn akẹkọọ wọn. Lara eto tawọn ṣe ni ibugbe pajawiri ti wọn le sare gbe akẹkọọ tabi olukọ lọ, aaye tawọn ọmọleewe ti le fọwọ wọn ati oogun apakokoro ti wọn gbọdọ maa fi pawọ nileewe.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.