Iroyin aarọ ọjọ keje, oṣu keje ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii.

Awọn ọmọleewe girama yoo bẹrẹ idanwo aṣekagba wọn lọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ titi wọ ọjọ karun-un oṣu kẹsan-an ọdun yii. 

Minisita eto ẹkọ nipinlẹ, Ọgbẹni Emeka Nwajuiba, lo kede ọrọ yii lasiko ti igbimọ amuṣẹṣe aarẹ lori ajakalẹ arun Coronavirus n ba awọn eeyan sọrọ. 

Awọn akẹkọọ ti wọn fẹẹ ṣedanwo aṣekagba nikan nijọba faaye gba lati wọle. 

 

Ijọba ipinlẹ Ondo tako ahesọ ti wọn n gbe kiri ipinlẹ ẹ pe awọn ọmọ Igbo ni wọn ko gbogbo iṣẹ ọna fun. 

Gomina Rotimi Akeredolu lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to jade latọdọ akọroyin rẹ, Ojo Oyewamide. 

O ni irọ pata gbaa ni pe ijọba oun ti gbe gbogbo iṣẹ ọna ipinlẹ naa fawọn ọmọ Igbo, o ni awọn ti wọn kuro ninu ẹgbẹ oṣelu awọn, All Progressive Congress, ni wọn n gbe ahesọ yii kiri. 

 

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party kọwe sijọba apapọ, wọn ni ki adele alaga EFCC, Ibrahim Magu, fipo ẹ silẹ 

Akọwe agba fẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Kọla Ologbodiyan, lo gbe ọrọ naa jade lanaa niluu Abuja. O ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ti mọ bayii pe Amofin agba fun ijọba apapọ ati Minisita eto idajọ, Ọgbẹni Abubakar Malami, ti fẹsun ikowojẹ kan Magu, wọn si lo n ta awọn dukia ti ajọ to n ri si iwa ajẹbanu naa gbẹsẹle nitakuta fawọn eeyan ẹ. 

O waa ni bi ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ba fẹẹ fi bi ọrọ igbogunti iwa ibajẹ ṣe mumu lọkan wọn to, afi ki adele alaga EFCC naa fipo ẹ silẹ titi ti awọn oniwadii yoo fi wẹ ẹ mọ kuro ninu ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.

(50)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.