Iroyin aarọ ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami ▶️ to wa nisalẹ yii.

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, tako iwe idibo abẹle lati yan aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC nibi idibo gomina ipinlẹ Ondo.  Wọn ni iwe ifitonileti ti wọn kọ ranṣẹ sawọn, adele akọwe agba fun ẹgbẹ naa nikan lo fọwọ si i, ofin eto idibo si fi dandan le e pe iru iwe bẹẹ, akọwe agba ati alaga ẹgbẹ gbọdọ fọwọ si i.

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Ghana ṣeleri pe awọn afurasi meji ti ọwọ awọn tẹ lori ile ijọba Naijiria ti wọn wo lulẹ ni Accra yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ rara. 

Ṣaaju ni awọn aṣojuṣofin Naijiria ti ka ọrọ ile ti wọn wo lulẹ yii si iwa afojudi ati arifin si orilẹ-ede Naijiria, abẹnugan wọn, Fẹmi Gbajabiamila, si ni ko yẹ ki Naijiria naa ma fesi to le fun wọn. Ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ lawọn o ni i sọ ọrọ ile ti wọn wo yii di ija igboro nigba ti aarẹ Ghana funra ẹ ti pe aarẹ Naijiria lati tọrọ aforijin fun ohun to ṣẹlẹ lorilẹ-ede oun.

Lara awọn ofin tuntun ti ijọba apapọ fẹẹ gbe kalẹ lori ati wọle awọn ileewe le mu ọpọlọpọ wọn ma lagbara ati ṣilẹkun wọn. 

Gẹgẹ bi iwe iroyin The Punch ṣe ri i ninu iwe ofin tuntun to jade nibi ijiroro awọn aṣofin lori iwọle yii, ileewe to ba fẹẹ ṣi yoo ni lati kọ aaye kan ti wọn le da fi ẹni ti wọn ba ri pe o n ṣaarẹ si. Ileewe wọn gbọdọ ni ileewosan to munadoko, bẹẹ ni wọn le ni lati kọ awọn yara igbẹkọ tuntun ki aaye le wa laarin awọn akẹkọọ sira wọn.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.