Iroyin aarọ ọjọ karun-un, osu keje ọdun 2020

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Engr. Ṣeyi Makinde, kọwe ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, lori iku gomina ana naa.

O ni gomina ana ọhun gbe ile aye rẹ lati sin ọmọniyan, ọpọlọpọ nnkan lo si ṣe lati da si idagbasoke eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọyọ ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

Ṣaaju ki eyi too ṣẹlẹ ni ede aiyede to lagbara ti wa laarin Gomina Ọyọ ati mọlẹbi Ajimọbi, ti iyawo Ajimọbi, Abilekọ Florence, fẹsun kan Gomina Ọyọ pe titi ti ọkọ oun fi ku, oun ko ri i ki wọn pe oun tabi kọwe ranṣẹ sawọn.

Ijọba apapọ atawọn ẹka eto ẹkọ ijọba ipinlẹ fẹẹ pade lori iwọle awọn akẹkọọ.

Latinu oṣu kẹta lawọn akẹkọọ ti wa nigbele nitori ajakalẹ arun Coronavirus. Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja yii ni alaga ajọ amuṣẹṣe lori Coronavirus yii kọkọ kede pe awọn ọmọleewe to wa nipele ati jade yoo le wọle ṣedanwo wọn.

Ṣugbọn kọmiṣanna eto ẹkọ ipinlẹ Edo, Ọgbẹni Jimoh Ijegbai, sọ fun iwe iroyin Punch pe awọn o ti i gbaradi fun iwọle naa rara, awọn ṣẹṣẹ fẹẹ ṣepade pẹlu ijọba apapọ ni.

Iye eeyan ti arun Coronavirus mu ni Naijiria bayii ti le lẹgbẹrun mejidinlọgbọn (28,168) o. Pẹlu ikede ti ajọ to n mojuto ọrọ ajakalẹ arun, Nigeria Center for Disease Control, fi sita, eeyan to le lẹgbẹfa (634) niwadii fidi ẹ mulẹ pe wọn ni arun yii ni Naijiria lọjọ Satide nikan.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.