Iroyin aarọ ọgbọnjọ, oṣu kẹfa ọdun 2020

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami (▶️) to wa nisalẹ yii

Ijọba apapọ ti fọwọ si irinajo lati ipinlẹ kan sipinlẹ mi-in. Alaga igbimọ agbaṣẹṣe lori ajakalẹ arun COVID-19,Boss Mustapha, lo kede ọrọ naa lanaa pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu irinajo lati ipinlẹ kan sipinlẹ mi-in ṣugbọn wọn ko gbọdọ jade laarin awọn wakati tijọba fofin de. Ofin tuntun yii yoo bẹrẹ iṣẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu keje ọdun yii.

Lasiko yii kan naa nijọba apapọ ni ki awọn ọmọleewe ti wọn fẹẹ ṣedanwo aṣekagba wọn wọle ki wọn le pari eto ẹkọ wọn.

Ọkan pataki ninu awọn oniṣowo nilẹ Yoruba, Oloye Bọde Akindele, ku lẹni ọdun mejidinlaadọrun. Lanaa ni a ri i gbọ pe ọkunrin to nileeṣẹ Modandola naa ku sile rẹ to wa ni Marina nipinlẹ Eko. Ọkan pataki ninu awọn oloye Ibadan ni Akindele, oye Parakoyi ilẹ Ibadan ni wọn fi i jẹ nigba aye ẹ.

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu, ti paṣẹ fun kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, pe ko da awọn ọlọpaa to n ṣọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi, pada fun un ni kiakia. 

Aipẹ yii ni kọmiṣanna ọlọpaa naa yọ awọn ẹṣọ alaabo to n ṣọ igbakeji gomina yii kuro lẹyin rẹ ni lọgan to ya kuro ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.