Iriri ti mo ni lo mu mi tayọ laarin awọn to fẹẹ dupo gomina nipinlẹ Kwara -Bọlaji Abdullahi

Spread the love

Minisita fun idagbasoke ere idaraya tẹlẹ, Mallam Bọlaji Abdullahi, ti ni oun loun ni iriri, ti oun si kunju oṣuwọn ju laarin awọn oludije to ti fifẹ han lati dupo gomina ipinlẹ Kwara lọdun 2019.

Abdullahi to sọrọ naa niluu Ilọrin, sọ pe gbogbo igbesẹ to yẹ loun ti n gbe ni ibamu pẹlu aṣẹ ẹgbẹ PDP lati dupo gomina ipinlẹ Kwara. O loun yoo kede ni gbangba laipẹ yii.

O gboriyin fun adari ẹgbẹ PDP to tun jẹ olori ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnẹtọ Bukọla Saraki, pẹlu ohun to sọ pe oludije ti awọn araalu ba yan, ti wọn si nifẹẹ si, loun yoo ṣatilẹyin fun.

Nigba to n sọrọ lori ipolongo awọn ẹgbẹ oṣelu to ku, o ni o jẹ ohun to ṣe ni laaanu pe gbogbo ohun ti wọn n tẹnumọ ni titako Saraki, ohun to yẹ ki wọn maa ṣe ni sisọ awọn ọna ti wọn fi maa mu ipinlẹ Kwara ga si i.

O ni ẹgbẹ PDP kunju oṣuwọn lati jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2019.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.