Irin ifura wa lẹsẹ awọn PDP

Spread the love

Ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ni awọn yọ olori awọn adajọ, Adajọ Agba Walter Onnogehn, kuro nipo rẹ lọsẹ to kọja yii, ọrọ naa si di ariwo rẹpẹtẹ jakejado Naijiria. Ariwo naa le debii pe ko sẹni kan ti yoo sọ pe oun ko gbọ, nitori bi inu awọn kan ti n dun ni inu awọn mi-in bajẹ pata, ọrọ to mi gbogbo ilu titi ni. Amọ kinni kan wa nibẹ. Ariwo ti awọn ẹgbẹ APC n pa ni pe ọrọ naa n ka awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lara nitori wọn ti mọ pe ọkunrin yii ni awọn fẹẹ lo lati fi da gbogbo ibo ti awọn ba di ru, ti yoo sọ pe awọn ko wọle nigba to jẹ pe awọn lawọn wọle. Wọn ni PDP lọkunrin adajọ agba naa, o si fẹẹ fi ipo rẹ ran ẹgbẹ yii lọwọ ni. Ariwo ọrọ naa n lọ lọwọ lawọn PDP funra wọn ba kede, wọn ni nitori yiyọ ti wọn yọ Adajọ Agba yii, awọn ti fopin si kampeeni awọn fungba diẹ, awọn ko ni i jade fun ipolongo nibi kọọkan, nitori ọrọ naa n ka wọn lara. Ohun to n ka wọn lara ninu ọrọ yii ko yeeyan o. Loootọ ọrọ naa dun gbogbo ọmọ Naijiria, ki i ṣe awọn nikan lo dun, nitori ki i ṣe PDP nikan lọrọ ọhun kan, gbogbo Naijiria lapapọ ni. Amọ ki waa ni tiwọn ti wọn ni awọn ko ni i ṣe kampeeni mọ, abi loootọ lọrọ ti awọn APC n sọ n nipa wọn ni. Bi ọrọ ti APC n sọ ki i baa ṣe loootọ, ki lawọn naa ronu bẹẹ yẹn si. Ṣe ki araalu le ni ọrọ naa dun wọn ju ni abi ki adajọ-agba yii funra rẹ le mọ pe ẹyin ẹ lawọn wa. Eyi o wu ko jẹ jare, irin awọn PDP yii mu ifura lọwọ, awọn funra wọn ni wọn si n sọ ara wọn lẹnu. A ko fẹ ẹni ti yoo riigi ibo to n bọ yii o, gbogbo ẹni to ba fẹẹ ṣe bẹẹ, Ọlọrun Ọba ko ni i fun wọn ṣe.

 

(103)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.