Ipo Igbakeji gomina ti n da wahala silẹ l’ẹgbẹ APC

Spread the love

Tako ifẹ awọn adari APC nipinlẹ Kwara, oludije funpo gomina ẹgbẹ naa, Abdulrahman Abdulrasaq, ti n gbero lati yan oludasilẹ ileewe nla kan niluu Abuja, Ọgbẹni Kayọde Alabi, gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ ninu eto idibo ọdun 2019.

Igbesẹ ti ko dun mọ awọn agba ẹgbẹ naa ninu la gbọ pe o ti n da wọn ru labẹlẹ.

Bakan naa lo tun da bii pe bi Abdulrahman ṣe yan Alabi yii ti fẹẹ fopin si erongba awọn alaga ẹgbẹ PDP tẹlẹ, Akọgun Iyiọla Oyedepo ati Ọmọọba Sunday Fagbemi, lati dipo naa mu. Ṣe lati bii ọsẹ diẹ sẹyin lawọn eeyan ti n lero pe o ṣee ṣe ki wọn fa ọkan ninu awọn eeyan naa kalẹ.

Yatọ si Oyedepo, awọn agba oloṣelu mi-in ti wọn ni minisita naa nifẹẹ si lati dipo naa mu ni Sẹnẹtọ Makanjuọla Ajadi ati oludije funpo gomina nigba kan, Sẹnẹtọ Simeon Ajibọla.

Gbogbo wọn lo jẹ oloṣelu lati ẹkun idibo Kwara South nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe gbogbo orukọ ti wọn la kalẹ fun oludije naa lati yan laarin wọn lo tako patapata. Eyi lo si ti n da rukerudo silẹ laarin ẹgbẹ.

Ṣaaju nipade oriṣiiriṣii ti waye lọna ati ri i pe Abdulrahman yan igbakeji rẹ laarin awọn orukọ ti ẹgbẹ ti la kalẹ, ṣugbọn o da bii ẹni pe oludije naa ti mọ ẹni to fẹ lọkan ara rẹ.

Ṣugbọn Oyedepo ti ni ifẹ ẹgbẹ lo maa pada leke. O ni ẹni ti wọn ba fa kalẹ nigbẹyin naa ni yoo ṣe igbakeji Abdulrahman.

 

 

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.