Ipo gomina di wahala ninu egbe oselu ADC Ọyọ

Spread the love

Nigba ti eto idibo ọdun 2019 n sun mọ etile, ti awọn ẹgbẹ oṣelu yooku si ti n gbaradi fun ipolongo idibo naa, ko jọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ti i mọ odo ti wọn yoo da ọrunla si dasiko yii, ori ija lawọn eekan ninu ẹgbẹ naa wa lori ẹni ti wọn yoo fa kalẹ lati dupo gomina orukọ ẹgbẹ wọn.

Awọn mẹtala lo n jijadu lati jẹ oludije dupo gomina lorukọ ẹgbẹ ADC ipinle Ọyọ. Ẹẹmẹta ọtọọtọ lawọn adari ẹgbẹ ọhun si ti paarọ orukọ ẹni ti wọn fẹẹ fa kalẹ gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina lorukọ wọn, bi wọn ṣe n yan ọkan ni wọn tun n yọ orukọ ẹ danu, ti wọn n fi omi-in rọpọ ẹ.

Wọn ko ri ọrọ naa yanju titi di aarọ kutu ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2018 yii, ti anfaani ti ajọ eleto idibo (INEC), fi silẹ fun awọn ẹgbẹ oṣelu gbogbo lati fi orukọ oludije fun ipo gomina wọn ṣọwọ fi pe. Eyi lo jẹ ki wọn sare fi orukọ Ọmọwe Dele Ajadi ranṣẹ si INEC gẹgẹ bii oludije fidi-hẹ-ẹ titi ti wọn yoo fi fi ẹnu ko lori ẹni kan ninu awọn to n dupo naa.

Ọmọwe Ajadi ti wọn fa kalẹ nigba naa ni igbakeji akọwe apapọ ẹgbẹ yii. nigba ti yoo si fi to ọsẹ meji, iroyin ti gba ilu kan pe Sẹnetọ Olufẹmi Lanlehin ni wọn yan.

Awọn oludije mejila yooku fariga, lọgan ni wọn ti gba kootu lọ, wọn ni ki ile-ẹjọ gba tikẹẹti ẹgbẹ ADC kuro lọwọ Lanlehin, nitori yiyan ti wọn yan ọkunrin naa ki i ṣe ajọmọ gbogbo ẹgbẹ, ọna ojooro lawọn adari ẹgbẹ gba yan an le awọn lori.

Diẹ ninu awọn oludije to pẹjọ ọhun ni Oloye Yunnus Akintunde (kọmiṣanna fun ọrọ iṣẹ-ode ni ipinlẹ Ọyọ) nigba kan ri, Amofin Sarafadeen Alli (akọwe ijọba ipinlẹ naa nigba kan ri), Ẹnijia Aderẹmi Oseni, Dokita Kọla Balogun ti oun naa ti ṣe kọmiṣanna fun eto idokoowo nigba kan ri ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹjọ yii ni wọn n fa lọwọ ni kootu ti nnkan fi tun yipada, ti iroyin si fi ye ni pe awọn alagbara inu ẹgbẹ oṣelu naa ti gba ipo ọhun kuro lọwọ Lanlẹhin, wọn ti gbe e fun Ọjọgbọn Nureni Adeniran, ẹni to ti figba kan jẹ kọmiṣanna feto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ.

Ko tun ju ọjọ meji lọ sigba naa niroyin mi-in tun gba ilu, wọn ni wọn tun ti yọ orukọ Adeniran kuro, Lanlẹhin ni wọn tun pada mu.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja ni Oloye Ralph Nwosu ti i ṣe alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu ADC fidi ẹ mulẹ pe Lanlẹhin ṣi ni oludije awọn ni ipinlẹ Ọyọ, nitori oun ni igbimọ amuṣẹya apapọ ẹgbẹ awọn fọwọ si.

Yatọ si awọn to n figa gbaga pẹlu Lanlẹhin lori ọrọ ondupo gomina yii, igbagbọ pupọ ninu awọn adari ẹgbẹ ọhun ni ipinlẹ Ọyọ, titi dori Dokita Ahmed Ayinla ti i ṣe alaga wọn lo gba pe Lanlẹhin to gbangba-a-sun-lọyẹ lati koju Bayọ Adelabu ti ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ gẹgẹ bii oludije wọn fun ipo gomina.

Ni kete ti alaga apapọ ẹgbẹ ADC ti fidi ẹ mulẹ pe Lanlẹhin lẹgbẹ awọn yoo fa kalẹ lati dupo gomina ni ipinlẹ Ọyọ lawọn mẹrẹẹrinla ti wọn jẹ ọmọọleegbimọ aṣofin ipinlẹ yii ti kan saara si awọn adari ẹgbẹ naa loke, wọn ni ika to tọ si imu gan-an ni wọn fi remu yẹn.

Lorukọ awọn aṣofin mẹrẹẹrinla to jẹ ọmọ ẹgbẹ yii, Ọnarebu Gbenga Oyekọla, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Atiba sọ pe ko si nnkan to buru ninu ọna ti wọn gba yan Lanlẹhin, nitori gbogbo awọn to n fifẹ han lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ awọn ni wọn ti jọ fẹnu ko pe ki awọn adari ẹgbẹ yan ẹnikẹni ti wọn ba ro pe ipo naa tọ si ninu awọn.

Ṣugbọn awọn to n ba Lanlẹhin dupo naa ko ti i pada lẹyin ẹ, wọn ni afi kile-ẹjọ gba tikẹẹti naa ẹ dandan.

Ni ibamu pẹlu ibeere akọroyin wa, ọkan ninu awọn to n fifẹ han lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ ADC, Oloye (Amofin) Sarafadeen Alli, sọ pe ẹjọ ti awọn pe tako yiyan ti wọn yan Lanlẹhin ṣi wa ni kootu, ati pe igba ti awọn ba too ṣepade lawọn yoo to le pinnu boya ki ẹjọ naa maa tẹwisaju tabi bẹẹ kọ.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.